SpyPen (Gègé Alamí)

News as it breaks.

‎Olùkọ́ Pàdánù Ẹ̀mí Rẹ̀ Lákòkò Ìbálọ̀pọ̀ Pẹ̀lú Akẹ́kọ̀ọ́ Nípìnlẹ́ Kogi

Images 3

Enimere Àkànbí
‎Ọ̀mọ̀wé Ọlábọ̀dé Abímbọ́lá Ìbìkúnlé, tó jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn àgbà olùkọ́ ní ilé ẹ̀kọ́ gíga Fáṣítì ìpínlẹ̀ Kogi, tó ń bẹ ní ìlú Anyingba, ní ìjọba ìbílẹ̀ Dekina, bá ikú pàdé nígbà tó ń jẹ ìgbádùn ìbálọ̀pọ̀ pẹ̀lú akẹ́kọ̀ọ́, ẹni ọdún méjìlélógún tó wà ní ìpele kejì.
‎
‎SaharaReporters, jábọ̀ pé Ọjọ́kẹẹ̀dógún, oṣù Keje, ọdún 2025, ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà wáyé, tí iléeṣẹ́ Ọlọ́ọ̀pá agbègbè Anyigba, nígbà tí ìròyìn kàn wọ́n lára, ti lọ gbé akẹ́kọ̀ọ́bìnrin náà láti fi ìbéèrè wa lẹ́nu wò.
‎
‎Ọ̀mọ̀wé Ìbìkúnlé, tí wọ́n sọ pé ó jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn Ọlùkọ́, tó jẹ́ kanjúko, ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ jẹ́ẹ̀rí pé ó kúndùn láti má a fi ìbálọ̀pọ̀ ṣe pàsípààrọ̀ máàkì fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó jẹ́ obìnrin.
‎
‎Àkọsílẹ̀ fihàn pé Ọ̀mọ̀wé Ìbìkúnlé, tó ní aya àti àwọn ọmọ méjì, gba yàrá ní ilé ìtura kan fún òun àti Akẹ́kọ̀ọ́bìnrin náà tó wà ní ìpele kejì ẹ̀ka tí wọ́n ti ń kọ́ nípa ìgbé ayé ọmọnìyàn (Social Studies Education).
‎
‎Àwọn kan tún jẹ́ kó di mímọ̀ pé Àgbà Olùkọ́ náà po onírúurú àwọn nǹkan afáralókun pọ̀, kí ó le è fakọyọ ju Akẹ́kọ̀ọ́bìnrin ọ̀un lọ, ní àkókò ìbálọ̀pọ̀ ọ̀hún.

‎Ìròyìn Míràn: Ọwọ́ Iléeṣẹ́ Ọlọ́ọ̀pá Ìpínlẹ̀ Kano Ba Akẹ́kọ̀ọ́ Mọ́kànlá Fún Ẹ̀sùn Ìṣekúpa Àwọn Akẹgbẹ́ Wọn

‎Kàkàbẹ́ẹ̀, ọ̀rọ̀ bá ibòmíràn yọ fún Ọ̀mọ̀wé Ìbìkúnlé, pẹ̀lú bí wọ́n ṣe jẹ́ kó di mímọ̀ pé, níṣe ni o dákú lọ rangandan ní àkókò ìbálọ̀pọ̀ náà, tó sì gba ibẹ̀ di èrò ọ̀run.
‎
‎Ọjọ́kejìdínlógún, oṣù keje, ọdún 2025, ni iléeṣẹ́ Ọlọ́ọ̀pá ìpínlẹ̀ Kogi, fìdí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí múlẹ̀ fún iléeṣẹ́ ìròyìn SaharaReporters.
‎
‎Agbẹnusọ iléeṣẹ́ Ọlọ́ọ̀pá ìpínlẹ̀ Kogi, SP William Ovye Aya, ṣàlàyé fún iléeṣẹ́ ìròyìn náà pé, Ọ̀gbẹ́ni Moses Friday, tó jẹ́ alákòóso ilé ìtura ọ̀hún tí wọ́n fi orúkọ bò ní àṣírí, ló fi ìṣẹ̀lẹ̀ náà tó àwọn létí.
‎
‎SP Aya, ṣàlàyé pé Ọ̀gbẹ́ni Friday, jẹ́ kó di mímọ̀ pé Akẹ́kọ̀ọ́bìnrin ọ̀hún tí wọ́n pe orúkọ rẹ̀ ní Gloria Samuel, ló sáré wá bá àwọn pé, Ọ̀mọ̀wé Ìbìkúnlé, tó gbé òun wá sí ilé ìtura náà ṣubú lulẹ̀ lẹ́yìn tí àwọn ni ìbálọ̀pọ̀ tán-àn.
‎
‎Lójú ẹṣé ni Ọ̀gbẹ́ni Friday gba iléeṣẹ́ Ọlọ́ọ̀pá lọ, tí Ọ̀gá ẹ̀ka iléeṣẹ́ Ọlọ́ọ̀pá náà sì yára tẹ́lẹ̀ lọ, tí wọ́n sì gbé olùkọ́ náà lọ sí iléwòsàn, níbi tí Ọnímọ̀ṣègùn òyìnbó tí wọ́n bá ní ẹnu iṣẹ́ ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé, Ọ̀mọ̀wé Ìbìkúnlé, ti gbé ẹ̀mí-mì.
‎
‎Níbàyí, wọ́n ti fi Akẹ́kọ̀ọ́bìnrin, Gloria Samuel, tí Ọ̀mọ̀wé Ìbìkúnlé, tó jẹ́ àgbà olùkọ́, kú lé lórí, rán-únsẹ́ sí ẹ̀ka tí wọ́n ti ń wọ́n ti ń ṣe ìwádìí nípa ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀daràn, ní iléeṣẹ́ Ọlọ́ọ̀pá ìpínlẹ̀ Kogi.
‎
‎Bákan náà ni wọ́n ti gbé òkú Ọ̀mọ̀wé Ọlábọ̀dé Abímbọ́lá Ìbìkúnlé, tó jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn àgbà olùkọ́ ní ilé ẹ̀kọ́ gíga Fáṣítì ìpínlẹ̀ Kogi, lọ fún àyẹ̀wò (Autopsy) láti mọ ikú tó pa á.
‎
‎
‎

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *