SpyPen (Gègé Alamí)

News as it breaks.

ỌWỌ́ ỌLỌ́PÀÁ BA ẸNI TÓ PA ỌMỌDÉBÌNRIN ỌDÚN MẸ́FÀ NÍBÀDÀN

HFs9rgBXMAEqMb2

Enimere Àkànbí
Ọwọ́ Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá lórílẹ̀èdè Nàìjíríà, ẹ̀ka ti ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, ti ba ọkùnrin kan, ẹni ọdún mẹ́tàlélógún, tí wọ́n fura sí pé ó lọ́wọ́ nínú ìṣekúpa ọmọdébìnrin tọ́jọ́ orí rẹ̀ kò ju mẹ́fà lọ, nílùú Ìbàdàn.

Gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe jẹ́ kó di mímọ̀ nínú àtẹ̀jáde láti ọwọ́ agbẹnusọ iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Ọ̀gbẹ́ni Ọláyínká Àyànládé, ọjọ́ kọkànlá, oṣù kẹrin, ọdún ẹgbàá-lé-mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n(2026) ni ìṣẹ̀lẹ̀ apanilẹ́kún ọ̀hún wáyé ní abúlé Àdìgún, ní agbègbè Ọlọ́rundá-Ògúnṣọlá, nílùú Ìbàdàn.

Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá náà ṣàlàyé pé àwọn ọwọ́ ba onítọ̀ún tí wọ́n pe orúkọ rẹ̀ ní Sodiq Káyọ̀dé Akóredé, lẹ́yìn tí ọ̀rìnkínnínwín ìwádìí tí àwọn fi ọgbọ́n àtinúdá ṣe, fi hàn pé ó lọ́wọ́ nínú bí wọ́n ṣe pa ọmọdébìnrin ọ̀hún tí wọ́n pe orúkọ rẹ̀ ní Mutiyatu Sunday, lọ́nà tí kò bófin mu.

Ó fi kún-un pé àbọ̀ ìwádìí náà ló mú kí Ọ̀gá àgbà ọlọ́pàá nípìnlẹ́ Ọ̀yọ́, Ọ̀gbẹ́ni Abímbọ́lá Ayọ̀déjì Olúgbénga, rán àwọn ikọ̀ ọlọ́pàá lọ lójú ẹsẹ̀ síbi tí ìṣẹ̀lẹ̀ ti wáyé.

Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ jẹ́ kó di mímọ̀ pé àwọn ikọ̀ ọlọ́pàá náà gbéra lójú ẹsẹ̀ láti jẹ́ iṣẹ́ náà, láì fi ti àwọn tó fẹ́ ṣe ìdájọ́ lọ́wọ́ ara wọn ṣe, wọ́n fi ìlànà akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ mú ọkùnrin ọ̀hún àti àwọn nǹkan ẹ̀rí tó ní ṣe pẹ̀lú ìṣẹ̀lẹ̀ yìí.

IMG 20260406 WA0006 1 226x300

Gẹ́gẹ́ bí iléeṣẹ́ ọlọ́pàá náà ṣe sọ, ìwádìí àkọ́ṣe fi hàn pé onítọ̀ún tí wọ́n fura sí, ṣe iṣẹ́ láabi ọ̀hún àti pé wọ́n bá àwọn nǹkan tó ṣe ẹ̀rí pé ó lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ làabi náà lákàtà rẹ̀.

Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ túbọ̀ jẹ́ kó di mímọ̀ pé ẹni tí wọ́n fura sí, ti ṣe àpatẹnujẹ́wọ́, wọ́n sì ti gbe lọ sí ilé ìwòsàn fún ìtọ́jú àwọn ìfarapa tó ní lákòókò tí àwọn tó fi ìdájọ́ sí ọwọ́ are wọn.

Ìrètí sì wà pé wọn yóò fi ráńṣẹ́ sí ẹ̀ka tí wọ́n ti ń ṣe ìwádìí nípa ìwà ọ̀daràn, láti ṣe ohun tó yẹ lórí rẹ̀.

Bákan náà ni iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ gba èrò àwùjọ níyànjú láti dẹ́kun ìwà fífi ìdájọ́ sí ọwọ́ ara wọn, pẹ̀lú àfikún pé ìgbésẹ̀ àwọn tí inú ń bí leè ṣàkóbá fún ìwádìí àwọn agbófinró.

Sẹ́gun Adélakùn

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *