SpyPen (Gègé Alamí)

News as it breaks.

Àjọ Tó Ń Ṣètò Hajj Nípìnlẹ́ Ọ̀yọ́ Ṣètò Àyẹ̀wò Ìlera Fún Àwọn Tó Fẹ́ Di Alhaji, Alhaja Lọ́dún 2026

IMG 20260129 WA0032

Enimere Àkànbí
Àjọ tó ń rí sí ètò ìgbàyégbádùn àwọn tó fẹ́ rìnrìn àjò Hajj ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, ti bẹ̀rẹ̀ àyẹ̀wò ìlera àti ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò nípa ìmọ̀ ẹ̀sìn Islam, fún àwọn tó ń gbèrò láti di Alhaji àti Alhaja, ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, láti mọ bí ẹ̀sìn ṣe yé wọn sí.

Lára àyẹ̀wò náà ti àwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ onímọ̀ ìṣègùn òyìnbó láti Àjọ tó ń ṣe àmójútó àwọn ilé ìwòsàn ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, ṣe fún wọn, ni àyẹ̀wò ẹ̀jẹ̀ ríru, ikọ́ ife, àyẹ̀wò ẹdọ̀, ọkàn, kíndìnrín, àyẹ̀wò àìsàn jẹ̀dòjẹ̀dọ̀ àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

Nígbà tó ń bá àwọn onítọ̀hún sọ̀rọ̀ ní ìpàgọ́ Àjọ náà tó ń bẹ ní agbègbè Olódó, Ìbàdàn, Alága Àjọ tó ń rí sí ètò ìgbàyégbádùn àwọn tó fẹ́ rìnrìn àjò Hajj ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Sheikh Wahab Atẹ́rẹ́ Hashim Ọlámìdé (JP) gbà wọ́n níyànjú láti di òpó ẹ̀sìn Islam mú ṣinṣin, kí wọ́n sì má a ṣe iṣẹ́ ìsìn wọn ní ìbámu pẹ̀lú àgbékalẹ̀ Allah.

Ó ṣàlàyé ìdí tí wọ́n fi ní láti wá ìmọ̀ kún ìmọ̀ nípa ọ̀nà tí wọ́n leè gbà má a ṣe ẹ̀sìn bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ, pẹ̀lú àfikún pé àbájáde ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò nípa ìmọ̀ ẹ̀sìn Islam, tí wọ́n ṣe fún wọn lọ́jọ́ ajé, fi hàn pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn ni kò ní ìmọ̀ tó nípa ẹ̀sìn Islam.

Sheikh Atẹ́rẹ́, wá mú u dá àwọn tó fẹ́ rìnrìn àjò Hajj, lójú pé, Àjọ náà yóò fi ìmọ̀ kíkún nípa bí wọ́n ṣe lè ṣe iṣẹ́ ìríjú wọn ní ilẹ̀ mímọ́, kọ́ wọn ní ìbámu pẹ̀lú àgbékalẹ̀ ìwé mímọ́(Qu’ran) látara sí ṣe ìdánilẹ́kọ̀ọ́ àtìgbàdégbà àti àwọn ètò ìlanilọ́yẹ̀ láti ẹnu àwọn ògbọ́ntarìgì onímọ̀ kíkún nípa ẹ̀sìn Islam, fún wọn.

Ó sì gba wọ́n níyànjú láti yẹra fún àwọn ìṣe tàbí ìgbésẹ̀ tó leè ṣe àkóbá fún ìlera wọn.

Nínú ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò tí àwọn oníròyìn ṣe fún díẹ̀ lára àwọn tó ń gbèrò láti lọ fún Hajj, Ọ̀gbẹ́ni Abass Fìjàbí, Ọ̀gbẹ́ni Raheem Balógun, Arábìnrin Modinat Àlàbí àti Arábìnrin Monsurat Muritala, fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ọ̀hún wáyé ní àkókò tó yẹ, tí wọ́n sì ṣe lọ́nà tó bójúmu.

Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa ìrì rẹ̀, Arábìnrin Monsurat Muritala, ṣàlàyé pé àwọn òṣìṣẹ́ Àjọ ọ̀hún bèrè àwọn nǹkan pẹ́pẹ̀pẹ́ nípa wọn àti ìmọ̀ wọn nípa ẹ̀sìn.

Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa ẹwà àti èrè Hajj, Ọ̀mọ̀wé Ibrahim Adélaní, gba àwọn tó fẹ́ lọ sí ìrìn àjò náà níyànjú láti lọ pẹ̀lú ọkàn tó tọ́ àti pé kí wọ́n ní ẹ̀mí ìforítì ṣe atọ́nà wọn.

Ìrètí wà pé wọn yóò fẹ ètò àyẹ̀wò ìlera ọ̀hún lójú dé àwọn ẹ̀ka yòókù.

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *