Enimere Àkànbí
Ọ̀kan lára àwọn ògúnná-gbòǹgbò nínú Ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress, APC, ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Onímẹ̀ẹ̀rọ Pópóọlá Olúkáyọ̀dé Joshua, tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ mọ̀ sí POJ, ti ṣèlérí láti yí ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ padà sí rere, bí wọ́n bá le fi ìbò gbé e wọlé, nínú ètò ìdìbò gbogbogbò ọdún Ẹgbàá-lé-mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n.
Akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ amojú-ẹ̀rọ náà, tó díje dupò GÓMÌNÀ ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ lábẹ́ ẹgbẹ́ òṣèlú New Nigeria Peoples Party, NNPP, ní ọdún Ẹgbàá-lé-mẹ́tàlélógún, fi ìgboyà sọ̀rọ̀ náà níbi ètò kan tó wáyé ní ìpínlẹ̀ Èkó, pẹ̀lú àfikún pé ipá àti ìrírí òun wúlò gidigidi fún ìṣàkóso ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́.
Onímẹ̀ẹ̀rọ Pópóọlá, tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ mọ̀ sí POJ, ṣàlàyé pé Gómìnà Ṣèyí Mákindé, lábẹ́ ìṣàkóso rẹ̀, ti sọ ìjọba ìbílẹ̀ di ẹdun arinlẹ̀, ṣe àfikún ìṣẹ́ àti òsì láti ara bí kò ṣe mọ nǹkan tó yẹ láti ṣe.
Ó fi kún àlàyé rẹ̀ pé Ẹgbẹ́ òṣèlú tó ń bẹ ní ìṣàkóso ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, kọ̀ láti mú ìpèsè ètò ẹ̀kọ́ tó yè koro, tó ṣèlérí ní ọdún Ẹgbàá-lé-mọ́kàndínlógún, ṣẹ, pẹ̀lú ìtọ́ka síi owó tó lé ní irinwó bílíọ́ọ̀nù náírà tí wọ́n ti ná lórí ètò ẹ̀kọ́, láti ọdún méje sẹ́yìn, síbẹ̀ ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ṣì ní àkọsílẹ̀ àwọn ọmọ tó ti pa ilé ẹ̀kọ́ tì jù lọ ní ẹkùn yìí, láti ara bí àkọsílẹ̀ ṣe fi hàn pé ìdá ogún àwọn ọmọ tí ọjọ́ orí wọn wà ní ààrin ọdún mẹ́ta sí mẹ́tàdínlógún, tí àpapọ̀ wọn jẹ́ ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọ̀rìnlélẹ́gbẹ̀ta-dín-díẹ̀, ni wọ́n kò lọ sí ilé ẹ̀kọ́ mọ́.
POJ sọ pé “Finland àti àwọn oríléèdè aláwọ̀ funfun tó ń kó ipa tó ṣeyebíye jù lọ lórí ètò ẹ̀kọ́, ni ọrọ̀ ajé wọn ń gbòòrò síi.
Ó kọminú lórí bí iná ìpèsè àwọn nǹkan amáyérọrùn ètò ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀, girama àti ti àwọn ilé ẹ̀kọ́ gíga tó jẹ́ ti ìjọba ṣe ń jó àjórẹ̀yìn, èyí tó ṣe àpèjúwe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi nǹkan tí kò bójú mu.
POJ ṣàlàyé pé “èèyàn yóò lérò pé owó tó lé ní irinwó bílíọ́ọ̀nù náírà tí ìjọba Ẹgbẹ́ òṣèlú PDP gbékalẹ̀, ti ná lórí ètò ẹ̀kọ́, láti ọdún méje sẹ́yìn, yóò mú àyípadà rere wá, ṣùgbọ́n rárá, ní ṣe ni nǹkan ń peléke síi, àwọn olùkọ́ àti akẹ́kọ̀ọ́ ń ṣe ètò ẹ̀kọ́ lábé àwọn yàrá ìkẹ̀kọ̀ọ́ tí kò ní òrùlé tàbí nínú ilé ìkẹ̀kọ̀ọ́ tó ti dàbìtì àlàpà.
Onímẹ̀ẹ̀rọ Pópóọlá, tó ń gbèrò láti díje du ipò Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ní ọdún Ẹgbàá-lé-mẹ́tàdìnlọ́gbọ̀n, ṣèlérí láti mú àwọn nǹkan tó ti bàjẹ́ ṣe lẹ́ka ètò ẹ̀kọ́, ó tún sọ pé ìṣàkóso òun yóò túbọ̀ mú àlàáfíà jọba, kí ohun gbogbo sì má a lọ ní mẹ̀lọmẹ̀lọ àti kí ìlọsíwájú láì yọ apá ibì kankan sílẹ̀ má a bá ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ lápapọ̀.
Ẹ̀wẹ̀, aṣáájú Ẹgbẹ́ òṣèlú APC, wá gba àwọn ọmọ Nàìjíríà níyànjú láti ṣe àtìlẹyìn fún ìṣàkóso Ààrẹ Bọlá Tinúbú, fún àléékún ìdàgbàsókè ìjọba àwarawa, bákan náà ló ní kí àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú APC ṣe ara wọn ní òṣùṣù ọwọ̀, kí wọ́n sì pa ẹnu pọ̀ yan òun gẹ́gẹ́ bíi ẹni tí yóò díje du ipò Gómìnà lábẹ́ àsìá Ẹgbẹ́ òṣèlú ọ̀hún, tó sì mú u dá wọn lójú pé ìṣèjọ̀ba kárí ilé, kárí ẹni gbogbo ni òun yóò, ṣe tí àwọn ará ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ bá leè fi ìbò wọn gbé òun wọlé ní ọdún Ẹgbàá-lé-mẹ́tàdìnlọ́gbọ̀n.












Leave a Reply