Enimere Àkànbí
Ìròyìn tó kàn wá ku ni pé, ẹnìkan tí wọ́n fúnra sí gẹ́gẹ́ bíi adarandáràn, ṣe ìkọlù ní agbègbè kan ní ìjọba ìbílẹ̀ Ìdó, ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, tó sì ṣekú pa ìyá àgbàlagbà kan, lẹ́yìn tó nawọ́ ìbálòpọ̀ si.
Nínú fọ́nrán amóhùnmáwòrán kan tí gbajúgbajà òǹmọ̀tàn nnì, Ààrẹ Lájí Abass, gbé sójú òpó ayélujára, ní alẹ́ ọjọ́rú, ọjọ́ kejìdínlógún, oṣù kejì, ọdún 2026, ni ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ti lu síta.
Nínú fọ́nrán náà ni ọ̀kan nínú àwọn ọmọ olóògbé, ti ṣàlàyé bí ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀hún ṣe wáyé ní agbègbè Orí-Àpáta, ní ìjọba ìbílẹ̀ Ìdó.
Gẹ́gẹ́ bó ṣàlàyé, ìyá àgbà náà ló lọ sí oko etélé láti já nǹkan ọbẹ̀, tó sì ṣe alábàpádèé onítọ̀hún tó gbójú aágan sí i, lẹ́yìn náà ló ṣekú pa á.
Ọmọ olóògbé ọ̀hún, túbọ̀ jẹ́ kó di mímọ̀ pé lákòókò ìkọlù náà, ni ọ̀kan nínú àwọn ọmọ ikọ̀ aláàbò Àmọ̀tẹ́kùn, ká onítọ̀hún mọ́ ibi tó ti ń hu ìwà burúkú ọ̀hún.
Síbẹ̀, ó múra ìjà sí òun náà, tó sì fi àdá tó ń bẹ ní ọwọ́ rẹ̀, ṣe ikọ̀ Àmọ̀tẹ́kùn, léṣe.
Bákan náà ni Ààrẹ Lájí Abass, jẹ́ kó di mímọ̀ pé nígbà tí wọ́n gbé òkú ìyá àgbà ọ̀hún lọ sí ilé ìgbókùú sí, ní ilé ìwòsàn ìjọba ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ mọ̀ sí Adéọ̀yọ́, àwọn òṣìṣẹ́ ẹ̀ka náà bèrè fún ẹgbẹ̀rún márùndín-lọ́gọ́rin náírà, kò tó di pé àwọn yóò gba òkú lọ́wọ́ wọn.
Ó sì fi àkókò náà rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Ṣèyí Mákindé àti Olúbàdàn ilẹ̀ Ìbàdàn, Ọba Ràṣídì Ládọjà, pé kí wọ́n dákun dá sí ọ̀rọ̀ ọ̀hún.
Ní àkókò tí a fi kó ìròyìn yìí jọ, àwọn Àjọ elétò ààbò tàbí ìjọba ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, kò tíì fèsì lórí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí.









Leave a Reply