Enimere Àkànbí
Adarí ilé aṣòfin ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Ọnarébù Adébọ̀ Ògúndoyin, ti kí ìjọba àti àwọn olùgbé ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ kú oríire àjọ̀dún ààdọ́ta ọdún tí wọ́n ti ṣe ìdásílẹ̀ ìpínlẹ̀ náà, ó sì ṣe àpèjúwe àpèjúwe àṣeyọrí ọ̀hún gẹ́gẹ́ bíi ohun tó ṣe ẹ̀rí gbé ìforítì, ìṣọ̀kan àti ẹ̀mí ìlọsíwájú tí elédùmarè fi jínkí àwọn ọmọ bíbí ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́.
Nínú ọ̀rọ̀ ráhúnpẹ́ tí Ọnarébù Ògúndoyin, sọ níbi ìṣíṣọlójú àjọ̀dún ọ̀hún tó wáyé nínú ọgbà ilé ẹ̀kọ́ gíga Fáṣítì ilẹ̀ Ìbàdàn, tó sì ṣàlàyé nípa bí ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ láti ọdún 1976 tí wọ́n ti ṣe ìdásílẹ̀ rẹ̀ ṣe ń tẹ̀síwájú láti má a lapa rere, fi ara rẹ̀ hàn gẹ́gẹ́ bíi ibùdó àṣà àti ìrẹ́sẹ̀walẹ̀ òṣèlú, bákan náà ló ń kópa tó jọjú nínú ìdàgbàsókè oríléèdè Nàìjíríà
Adarí ilé aṣòfin ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ sì gbóríyìn fún onírúurú ìṣàkóso tó ti tukọ̀ ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, fún akitiyan wọn láti jẹ́ kí gbogbo àgbáyé gbà pé ajíṣe bí Ọ̀yọ́ lá ń rí, Ọ̀yọ́ kò ní ṣe bíi baba ẹni kankan, ni ìpínlẹ̀ jẹ́.
Ọnarébù Ògúndoyin, sì kan sáárá sí Gómìnà Ṣèyí Mákindé, fún bó ṣe ṣe ìrẹ́sẹ̀walẹ̀ ìlànà ìṣèjọ̀ba tí ó mú ìpèsè àti àtúnṣe àwọn nǹkan amáyédẹrùn, àtúntò ètò ẹ̀kọ́, ìrólágbára àwọn ọ̀dọ́, ìdókòwò nínú iṣẹ́ àgbẹ̀ àti ìgbọ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀ òwò ṣíṣe ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, lọ́kùnkúndùn.
Bákan náà ni ó sọ nípa iṣẹ́ takuntakun tí àwọn olórí ìṣàkóso ológun ṣe, pẹ̀lú àfikún pé àwọn ló ṣe ìfilọ́lẹ̀ ìpìlẹ̀ tí ó mú ìdàgbàsókè àti ìlọsíwájú bá ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́.
Ọnarébù Ògúndoyin, kò gbàgbé ipa tí àwọn orí adé, ọrùn ìlẹ̀kẹ̀, àwọn àgbékalẹ̀ ìjọba, ẹ̀ka aládàáni, Ẹgbẹ́ àwùjọ, àwọn iléeṣẹ́ ìròyìn, àwọn oníṣẹ́-ọwọ́ àti àwùjọ lápapọ̀, kò nínú ìdàgbàsókè àti àṣeyọrí gbogbo tí ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ti ṣe láti ìgbà tí wọ́n ti ṣe ìdásílẹ̀ rẹ̀.
Nígbà tó ń kí àwọn ọmọ ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, nílé, lóko àti lẹ́yìn odi oríléèdè Nàìjíríà kú oríire, Adarí ilé aṣòfin ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ fi ìgbàgbọ́ kíkún hàn pé, nígbà tí ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ yóò bá fi pé ọgọ́rùn-ún ọdún, yóò ti ṣe àṣeyọrí síi nínú ọrọ̀ ajé, ẹ̀ka òṣèlú rẹ̀ yóò tún ti dúró re ju báyìí lọ àti wípé àwọn nǹkan amáyédẹrùn náà yóò ti gbọ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀ síi.
Ọnarébù Ògúndoyin, sì bẹ elédùmarè láti jẹ́ kí omi àlàáfíà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ túbọ̀ má a tòrò, kí ìlọsíwájú aláìlẹ́gbẹ́ sì má a bá ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, bákan náà ló gba àwọn olùgbé ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ níyànjú láti má a pa òfin mọ́ àti pé kí wọ́n má a kó ipa ti wọn nínú ìdàgbàsókè oríléèdè Nàìjíríà lápapọ̀.









Leave a Reply