SpyPen (Gègé Alamí)

News as it breaks.

Ìfi Àmì Ẹ̀yẹ Fún Ni Ti Di Ọ̀nà Ìkówójọ – OYASI Korò Ojú Síi

IMG 20260121 WA0024
Enimere Àkànbí
Alága ẹgbẹ́ Ọmọ Yorùbá Àtàtà Socio-cultural Initiative (OYASI) àti Olùdásílẹ̀ Àjọ̀dún Ẹ̀ṣọ́ Orí Lágbáyé (World Headdress Celebration) Ọ̀gbẹ́ni Ọláwálé Àjàó, ti kọminú nípa bí àwọn Ẹgbẹ́, Àjọ àti èrò àwùjọ ṣe ti ń sọ àgbékalẹ̀ àmì ẹ̀yẹ di ọ̀nà ìkówójọ, tó sì ti ń di bárakú fún ọ̀pọ̀lọpọ̀.
Ọ̀gbẹ́ni Àjàó, sọ̀rọ̀ tako ó lákòókò tó léwájú Ẹgbẹ́ OYASI lọ́ rèé gbé àmì ẹ̀yẹ fún Ìyá oní gèlè àrà nnì, Olóyè Níkẹ̀ẹ́ Davies-Okundaye, gẹ́gẹ́ bíi Ọbabìnrin ní ilẹ̀ Adúláwọ̀.
Ní ọ́fìsì Olóyè Davies-Okundaye, tó jẹ́ olùdásílẹ̀ ibùdó ìṣàfihàn àwọn iṣẹ́ ọnà, àṣà àti nǹkan mèremère (Nike Art Gallery), tó ń bẹ ní agbègbè Lekki, ní ìpínlẹ̀ Èkó, ni wọ́n ti lọ gbé àmì ẹ̀yẹ ọ̀hún fún-un nítorí pé kò ní àǹfààní láti gbà á níbi Àjọ̀dún Ẹ̀ṣọ́ Orí Lágbáyé tó wáyé ní ìlú Ìbàdàn, tí ṣe olú ìlú ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, fún-un.
Nínú ètò ọlọ́dudún ọ̀hún, tó jẹ́ ẹlẹ́ẹ̀kejì irú rẹ̀ ni wọ́n ti fi àmì ẹ̀yẹ dá àwọn ọkùnrin onífìlà àrà àti obìnrin onígèlè àrà lọ́lá.
Àmì ẹ̀yẹ yìí jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ohun pàtàkì nínú ayẹyẹ Ẹ̀ṣọ́ Orí Lágbáyé, ẹlẹ́ẹ̀kejì irú rẹ̀, tí wọ́n ṣe ní ọjọ́ Àìkú, Ọjọ́ kejìdínlọ́gbọ̀n, Oṣù Kejìlá, ọdún 2025, ní ìlú Ìbàdàn.
Nígbà tí Ọ̀gbẹ́ni Àjàó, ń fún Arábìnrin Davies-Okundaye, ní àmì ẹ̀yẹ rẹ̀, ó tẹnu mọ́ pé àmì ẹ̀yẹ náà kìí ṣe fún èrè owó tàbí láti fi lọ́ àwọn tó ń gbàá lọ́wọ́ gbà.
Gẹ́gẹ́ bí ó ṣe sọ, wọ́n ṣe àgbékalẹ̀ ètò ayẹyẹ Ẹ̀ṣọ́ Orí Lágbáyé láti fi ìmọrírì hàn sí àwọn tó dé fìlà tàbí wé gèlè tó yááyì pẹ̀lú àfikún pé Ẹ̀ṣọ́ Orí tí ẹnì kọ̀ọ̀kan wọ̀ ni wọ́n fi ṣe òdiwọ̀n àmì ẹ̀yẹ náà.
Ọ̀gbẹ́ni Àjàó sọ pé ohun tí Ẹgbẹ́ náà ń ṣe iṣẹ́ tọ̀ ní bí wọn yóò ṣe rí àwọn onígbọ̀wọ́ débi wí pé ní ọjọ́ iwájú wọ́n yóò le è má a fún àwọn tí wọ́n bá ń fún ní àmì ẹ̀yẹ ní ẹ̀bùn owó tàbí àwọn nǹkan mìíràn tó jọjú.
Gẹ́gẹ́ bó ṣe sọ “Àmì ẹ̀yẹ kìí ṣe ohun tó yẹ fún àwọn tó ń ṣe àgbékalẹ̀ rẹ̀, láti má a retí owó láti ọ̀dọ̀ àwọn tí wọ́n gbé àmì ẹ̀yẹ fún, ṣùgbọ́n ó ṣeni láànú pé nítorí owó àti èrè ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn tàbí Ẹgbẹ́ ṣe ń gbé àmì ẹ̀yẹ kalẹ̀ báyìí”
Ó ní ẹni tí wọ́n bá fẹ̀ gbé àmì ẹ̀yẹ fún gbọ́dọ̀ jẹ́ ẹni tó tọ́ sí jù lọ, láìní retí owó tàbí ẹ̀bùn padà lọ́dọ̀ rẹ́”
Nígbà tó ń fèsì, Arábìnrin Davies-Okundaye, fi ìmọrírì hàn sí Ẹgbẹ́ OYASI, fún bí wọ́n ṣe kàá yẹ fún àmì ẹ̀yẹ ọ̀hún àti bí wọ́n ṣe ń gbé àṣà Yorùbá lárugẹ.
Arábìnrin Davies-Okundaye, nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣe ìrántí bí Akọ́wé-kọwúrà nnì, Ọ̀jọ̀gbọ́n Wọlé Ṣóyínká, ṣe pe gèlè ní “Gèlè Galla” àti bí òun náà ṣe ń ṣe akitiyan láti ró àwọn obìnrin lágbára, láti ara kíkọ́ wọn ní gèlè síso, ní ọjà Téjúoṣó àti Jàànkara, ní ìpínlẹ̀ Èkó.
Ó ní “nígbà tí mo gbọ́ pé àwọn èèyàn ti ń gbowó lórí gèlè wíwé, mo lọ kọ́ àwọn èèyàn nípa bí wọ́n ṣe ń wé gèlè nínú ọjà Jankara ati Tẹjúoṣó.
“A kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú gèlè lásán, nígbà tó yá là ń wé e bí ìgbà tí èèyàn bá ń wé láwààní, àwọn èèyàn sì tẹ́wọ́ gbàá”
Wọ́n ṣe àgbékalẹ̀ Àjọ̀dún Ẹ̀ṣọ́ Orí Lágbáyé fún ìṣelọ́jọ̀ àti ìgbèlárugẹ àṣà àti ìṣe Yorùbá, nípasẹ̀ fìlà àti gèlè.
IMG 20260121 WA0025 300x169
Ṣáájú níbi ayẹyẹ ní ìlú Ìbàdàn, ni igbákejì Olóòtú ìròyìn, ní iléeṣẹ́ ìwé ìròyìn Nigerian Tribune, Ọ̀gbẹ́ni Yínká Ọládòyìnbó, tó gba àmì ẹ̀yẹ fún olóògbé Ọbáfẹ́mi Awólọ́wọ̀, tó jẹ́ ẹni àkọ́kọ́ tó ṣe ìṣàkóso ẹkùn ìwọ̀-oòrùn oríléèdè Nàìjíríà, lo àkókò náà fi gba àwọn òbí àti alágbàtọ́ níyànjú láti fi ìṣe, èdè àti àṣà Yorùbá kọ́ àwọn ọmọ wọn, kí ó má ba à parun.
Àgbàọ̀jẹ̀ òǹkọ̀wé nnì, Alàgbà Débọ̀ Aáwẹ́, àwọn Ògbóǹkangí Agbóhùnsáfẹ́fẹ́, Olóye Adesoye Ọmọ́tọ̀ṣọ́ àti ẹni tó fi ẹ̀yìn tì ní iléeṣẹ́ ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Ọ̀nàọlápọ̀ Gbọ́lágún, tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ mọ̀ mọ fìlà abetí-ajá tí ó ma ń dé ní gbogbo ìgbà, tí àwọn náà wà lára àwọn tí Ẹgbẹ́ OYASI gbé àmì ẹ̀yẹ fún, náà kín ọ̀rọ̀ Ọ̀gbẹ́ni Ọládòyìnbó lẹ́yìn.
Lára àwọn tó lókọlókì tó yẹ́ ayẹyẹ ìfámì ẹ̀yẹ ọ̀hún sí ni Aṣẹ́yìn ti ìlú Ìṣẹ́yìn, Ọba Ọláwálé Sefiu Oyèbọ́lá àti Olówu ti ìlú Òwu, Ọba Saka Adélọlá, tí Ààrẹ Oníkòyí, Olóyè Ayọ̀délé Ọ̀jẹ̀ladé àti Sákòsì ti ìlú Òwu, Olóyè Ọláníyan Ṣọ́fẹlá.
Àwọn gbajúmọ̀ tó tún wà níbi ayẹyẹ ọ̀hún ni, igbá-kejì Adarí ẹ̀ka ìròyìn àti ọ̀rọ̀ tó ń lọ, ní iléeṣẹ́ ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ àpapọ̀ oríléèdè Nàìjíríà, FRCN, ẹkùn Ìbàdàn, Ọ̀gbẹ́ni Adéwùmí Fáníran àti Gíwá iléeṣẹ́ ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ Amúlùdún, Arábìnrin Tolúlọpẹ́ Ọnàfọwọ́kàn, tí Alákòóso ẹ̀ka ìròyìn, Ọ̀gbẹ́ni Olúṣẹ̀yẹ Arówólò, ṣojú fún.
Arábìnrin Davies-Okundaye, tó jẹ́ gbajúgbajà oníṣẹ́ ọnà àti agbáṣà ga, ni kò ní àǹfààní láti wà níbi ayẹyẹ ọ̀hún nígbà tó wáyé ní ìlú Ìbàdàn, ìdí nìyí tí àwọn tó ṣe àgbékalẹ̀ rẹ̀ fi ṣe àbẹ̀wò síi ní ìlú Èkó, láti gbé àmì ẹ̀yẹ rẹ̀ fún-un, gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe ṣe fún àwọn míràn tí kò ní àǹfààní láti fi ara hàn.
Lára àwọn tí wọ́n fún lámì ẹ̀yẹ ọ̀hún ni, igbá-kejì gómìnà nígbà kan rí ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Alhaji Taofeek Arápájà, Alákòóso Àjọ tó ń rí sí ìrìn-àjò afẹ́ ní ìpínlẹ̀ Èkìtì, Amọ́fin Wálé Ojó-Láńre.
Bákan náà ni wọ́n fi àmì ẹ̀yẹ náà fi ìmọrírì hàn sí méjì nínú àwọn aṣáájú Yorùbá, tí wọ́n ti jáde láyé, Olóògbé Ọbáfẹ́mi Awólọ́wọ̀, àti Alhaji Abdul-Azeez Aríṣekọ́lá Àlàó, tó jẹ́ Ààrẹ Mùsùlùmí ilẹ̀ Yorùbá, ìpínlẹ̀ Edo àti Delta, nígbà tó wà láyé.
Àwọn mìíràn tó tún kópa níbi ayẹyẹ náà ni ọ̀kan nínú àwọn tó ṣojú oríléèdè Nàìjíríà lásìkò ọdún àṣà àgbáyé ọdún 1977, Ọmọọba Túndé Ọdúnladé, tó tún jẹ́ olùdásílẹ̀ Ìṣe ọnà àti àwọn nǹkan tó ní ṣe pẹ̀lú àṣà, ti Túndé Ọdúnladé, (Túndé Ọdúnladé Art and Culture Connexions); Alága Ẹgbẹ àwọn Akọ̀ròyìn lórílẹ̀èdè Nàìjíríà(NUJ) ẹ̀ka ti ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Ọ̀gbẹ́ni Akeem Abas àti ìgbìmọ̀ ìjọba rẹ̀; tí obìnrin oníṣòwò nnì ní ìlú Ìbàdàn, tó jẹ́ olùdásílẹ̀ iléeṣẹ́ Deborah Olúfúnkẹ́ (Deborah Olufunkẹ Nigeria Ltd) Arábìnrin Deborah Olúfúnkẹ́ Awóyẹlé, sì jẹ́ alága ayẹyẹ náà.
Akọ̀ròyìn:
Abdullah Ọlápàdé, Blessing Jọlásun, Mutiah Adéyẹmọ

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *