Enimere Àkànbí
Ẹni tó ti fìgbà kan rí jẹ́ Alákòóso ìgbòkègbodò ọkọ̀ lórílẹ̀èdè Nàìjíríà, Ọ̀gbẹ́ni Rótìmí Amaechi, sọ pé ìrírí àti ìmọ̀ tí òun ti ní nípa ìṣèjọ̀ba àti mímú ìdàgbàsókè bá àwọn nǹkan amáyédẹrùn, fi òun sípò ẹni tó leè wá ojútùú sí ìṣòro oríléèdè Nàìjíríà.
Ọ̀gbẹ́ni Amaechi, tó jẹ́ Gómìnà nígbà kan rí nípìnlẹ́ Rivers, fi ọwọ́ ìdánilójú yìí sọ̀yà fún àwọn ọmọ Nàìjíríà, lákòókò tí ìgbáradì fún ètò ìdìbò gbofbofbò ọdún ẹgbàá-lé-mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n 2027.
Ó sọ̀rọ̀ yìí lákòókò tó ń kópa lórí ọ̀kan lára ètò iléeṣẹ́ Amóhùnmáwòrán Channel, tó sì jẹ́ kó di mímọ̀ pé yàtọ̀ sí pé ìṣòro oríléèdè Nàìjíríà yé òun, òun tún ní ìkápá láti wá ọ̀nà àbáyọ sí àwọn ìṣòro.
Amaechi, sì tọ́ka sí àwọn àkànṣe iṣẹ́ bíi ojú ọ̀nà ọkọ̀ ojúrin, àti ìdàgbàsókè èbúté tó ṣe lákòókò tó fi jẹ́ alákòóso iléeṣẹ́ ìjọba àpapọ̀, gẹ́gẹ́ bíi ẹ̀rí sí àwọn nǹkan tí òun leè ṣe tí òun bá dé ipò Ààrẹ oríléèdè Nàìjíríà.
Ó tún sọ pé pé òun ti kápá ìṣòro ètò ààbò rí, lákòókò tí òun wà nínú ìṣèjọ̀ba, pẹ̀lú àfikún pé àkọsílẹ̀ fi hàn pé òun dá yàtọ̀ sí àwọn míì náà tó ń fi èróńgbà hàn láti díje.
Ọ̀gbẹ́ni Amaechi, tó jẹ́ ara àwọn aṣáájú nínú Ẹgbẹ́ òṣèlú African Democratic Congress, bu ẹnu àtẹ́ lu ìṣàkóso tí Ààrẹ Bọlá Tinúbú, ń tukọ̀ rẹ̀, pẹ̀lú àfikún pé ọ̀rọ̀ ajé tí dojú rù lábẹ́ àmójútó rẹ̀.
Gẹ́gẹ́ bí Ọ̀gbẹ́ni Amaechi, ṣe ṣàlàyé, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọmọ Nàìjíríà ló ń kojú onírúurú ìṣòro àti ìnira.
Sẹ́gun Adélakùn










Leave a Reply