Enimere Àkànbí
Alákòóso ọ̀rọ̀ abẹ́lẹ́ lórílẹ̀èdè Nàìjíríà, Ọ̀gbẹ́ni Olúbùnmi Túnjí-Òjó, ti pàṣẹ fún iléeṣẹ́ tó ń rí sí ìwọlé-jáde lórílẹ̀èdè Nàìjíríà (Nigeria Immigration Service, NSC) láti tètè wọ́gilé ìwé àkọsílẹ̀ ìdánimọ̀ gbogbo àwọn tó ti kéde pé àwọn kìí ṣe ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà mọ́.
Àṣẹ yìí ló jẹ yọ nínú àtẹ̀jáde láti ọwọ́ olùrànlọ́wọ́ Alákòóso ọ̀rọ̀ abẹ́lẹ́, lórí ọ̀rọ̀ ìròyìn, Ọ̀gbẹ́ni Àlàó Babátúndé, pẹ̀lú àfikún pé ìgbésẹ̀ yìí yóò múlẹ̀ lórí àwọn tó fi tó ìjọba létí pé àwọn kò jẹ́ ọmọ oríléèdè Nàìjíríà mọ́.
Àtẹ̀jáde ọ̀hún jẹ́ kó di mímọ̀ pé Ọ̀gbẹ́ni Túnjí-Òjó, tọ́ka sí abala kọkàndínlọ́gbọ̀n, ẹsẹ kìnní àti ìkejì, nínú ìwé òfin oríléèdè Nàìjíríà, tí wọ́n ṣe àtúnṣe rẹ̀ kẹ́yìn ní ọdún Ẹgbàá-dín-kan(1999) tó fìdí àṣẹ náà mùlẹ́, ní ìbámu pẹ̀lú ojúṣe iléeṣẹ́ ọ̀hún sí àwọn aráàlú.
Ẹsẹ kìnní abala òfin náà sọ pé “ẹnikẹ́ni tí ó ti tó ọjọ́ orí tó leè ṣe ìpinnu fúnra rẹ̀, leè pinnu lọ́kàn ara rẹ̀ pé òun kò fẹ́ jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà mọ̀ọ́, nípa títọ ọ̀nà tó yẹ”
Nígbà tí ẹsẹ kejì sọ pé “Ààrẹ oríléèdè yìí yóò sì fi ọwọ́ sí ìbéèrè onítọ̀hún, tí wọn yóò sì wọ́gilé ìwé àkọsílẹ̀ tó fi jẹ́ ọmọ oríléèdè Nàìjíríà”
Àtẹ̀jáde náà fi kún-un pé Alákòóso ọ̀hún sọ pé lọ́gba tí ẹnikẹ́ni bá ti sọ pé òun kìí ṣe ọmọ oríléèdè yìí mọ́, onítọ̀hún kò ní ẹ̀tọ́ láti ní àwọn nǹkan ìdánimọ̀ oríléèdè Nàìjíríà lákàtà rẹ̀, tó fi mọ́ ìwé àṣẹ ìrìnnà ilẹ̀ yìí.

Bákan náà ni Ọ̀gbẹ́ni Túnjí-Òjó, ṣàpèjúwe ìgbésẹ̀ ọ̀tun yìí gẹ́gẹ́ bíi ara akitiyan àti iṣẹ́ takuntakun láti mú ìyípadà àti àtúntò bá ètò ìwé àṣẹ ìrìnnà àti ìgbélùú tí iléeṣẹ́ ọ̀hún ń ṣe láti bíi ọdún díẹ̀ sẹ́yìn.
Alákòóso fi kún-un pé àṣẹ tuntun ọ̀hún jẹ ara ìgbìyànjú láti fi òpin sí bí àwọn tó ti fìgbà kan rí jẹ́ ọmọ oríléèdè Nàìjíríà máa ṣe ń fi ìwé àṣẹ ìrìnnà rẹ̀ rìnrìn àjò lọ àwọn oríléèdè míì, lẹ́yìn tí wọ́n ti kéde pé àwọn kìí ṣe ọmọ ilẹ̀ yìí mọ̀.
Ṣẹ́gun Adélakùn












Leave a Reply