Enimere Àkànbí
Ìlú Ọ̀yọ́ ti ṣe tán fún ìrọ́kẹ̀kẹ̀ àti ìgbàlejò, ní bí àwọn akọni agbábọ́ọ̀lù láti tìbútòro ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ yóò ṣe má a kóra jọ pọ̀ fún àkànṣe ìdíje tí wọ́n gbé kalẹ̀ fún ìṣàmì ayẹyẹ ogún ọdún tí àgbà-ọ̀jẹ̀ akọ̀ròyìn eréèdárayá, Dayọ̀ Òjó, tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ mọ̀ sí “Okocha” ti ń ṣe iṣẹ́ gẹ́gẹ́ bíi akọ̀ròyìn eréèdárayá.
Ìdíje ọ̀hún tí wọ́n pe àkòrí rẹ̀ ní “Àkókò láti ṣe ayẹyẹ Ìperegedé” ni yóò gbìnnàyá, ní ọjọ́ kọkànlélọ́gbọ̀n, oṣù kínní, ọdún 2026 ní ilé ẹ̀kọ́ ìjọba àpapọ̀ tí wọ́n ti ń kọ́ nípa ilẹ̀ wíwọ̀n(Federal School of Surveying) tó ń bẹ ní ìlú Ọ̀yọ́, pẹ̀lú ìdíje bọ́ọ̀lù aláfẹsẹ̀gbá láàrin àwọn akọni.
Gẹ́gẹ́ bó ṣe jẹ yọ nínú àtẹ̀jáde láti ọwọ́ Alága ìgbìmọ̀ tó ń ṣe kòkárí ẹ̀ka Erédárayá ayẹyẹ ọ̀hún, Adéníyì Afẹ́, èyí tí Alága ìgbìmọ̀ tó ń ṣe kòkárí ètò ayẹyẹ ọ̀hún, Ọ̀gbẹ́ni Adédàmọ́lá Adégòkè, fi léde.
Nínú àtẹ̀jáde ọ̀hún ni wọ́n ti jẹ́ kó di mímọ̀ pé wọ́n ti pín àwọn olùdíje sí ìsọ̀rí láti jẹ́ kí ìdíje dọ́gba láàrin wọn, ní ìsọ̀rí àkọ́kọ́ ni a ti rí Ọ̀yọ́ Aláàfin Ambassadors, Ọ̀yọ Bankers All Stars, Akínyẹlé Living Legends, àti Advanced Ambassadors.
Ní ìsọ̀rí kejì, ni Wesley Ambassadors, New Castle Legends, àti Afijió Ambassadors, yóò ti máa figagbága, nígbà tí NFCA Ọ̀yọ́ Zone, All Stars Ọ̀yọ́, àti Ìbàdàn City All Stars, lé fùrùkọkọ sí ìsọ̀rí kẹta.
Àwọn ìfigagbága ọ̀sẹ̀ àkọ́kọ́ ni wọn yóò gbá láìní tàsé ọ̀kankan nínú bí wọ́n ṣe ṣe àlàkalẹ̀ rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ìgbìmọ̀ tó ń ṣe ìṣàkóso rẹ̀ ṣe tẹnumọ́ ọ pé kò ní sí àṣà ìdúró de ẹnikẹ́ni, èyí tó wọ́pọ̀ ní ilẹ̀ adúláwọ̀.
Aago mẹ́jọ ààbọ̀ òwúrọ̀ ni wọn yóò gbá ìfigagbága ti wọn yóò fi ṣíde ìdíje, èyí tí yóò wáyé láàrin Ọ̀yọ́ Aláàfin Ambassadors àti Advanced Ambassadors, tí Wesley Ambassadors, Ìbàdàn àti New Castle Legends, yóò sì fi ẹkẹ ṣènàjú ní aago mẹ́wàá ààbọ̀ òwúrọ̀.
Àwọn ìfigagbága yòókù ni ti NFCA Ọ̀yọ́ Zone kojú u Ìbàdàn City All Stars, ní déédéé aago méjìlà ọ̀sán, Ọ̀yọ́ Bankers All Stars yóò gbé pẹ́rẹ́gi kaná pẹ̀lú Akínyẹlé Living Legends, Ìbàdàn, ní aago kan ọ̀sán, aago méjì ọ̀sán ni Wesley Ambassadors, Ìbàdàn àti Afijió Ambassadors, yóò gbé ìjà kojú ara wọn.
Yàtọ̀ sí ìdíje bọ́ọ̀lù aláfẹ́sẹ̀gbá, àwọn ètò míràn tí wọ́n piyamọ fún ayẹyẹ ọ̀hún tí àṣekágbá rẹ̀ yóò wáyé ní ọjọ́ kọkànlá, oṣù kẹrin, ọdún 2026 ni fífún àwọn tó kópa ribiribi nínú ìrìn àjò ogún ọdún Dayọ̀ Òjó Okocha, láti mú ìdàgbàsókè bá eréèdárayá ní ìlú Ọ̀yọ́, ní àmì-ẹ̀yẹ àti ìwé ẹ̀rí ìmọrírì, ìdíje ta ló mọ àwọn ìbéèrè eréèdárayá àti ìtukọ̀ ètò yàjóyàjó eréèdárayá láàrin àwọn gbajúmọ̀ atọ́kùn ètò eréèdárayá ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́.
Àtẹ̀jáde ọ̀hún tún ṣe àpèjúwe ayẹyẹ náà gẹ́gẹ́ bíi ìmọrírì ipa tí Dayọ̀ Òjó tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ mọ̀ sí “Okocha” ti kó nínú iṣẹ́ ìròyìn eréèdárayá, ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú àwùjọ àti ìgbèlárugẹ eréèdárayá lẹ́sẹ̀kùkú ní tìbútùro ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, tí wọ́n sì fẹ́ lo Erédárayá bọ́ọ̀lù aláfẹsẹ̀gbá gẹ́gẹ́ bíi èròjà ìṣọ̀kan láti fi ṣe ayẹyẹ ìtayọ, ìkóraẹni níjàánu àti iyì Erédárayá.
Àwọn ìgbìmọ̀ náà sì tẹnu mọ́ ọ pé àwọn ikọ̀ kọ̀ọ̀kan gbọ́dọ̀ má a dé sí pápáṣerédárayá, ọgbọ́n ìṣẹ́jú ṣáájú kí ìfigagbága wọn tó bẹ̀rẹ̀, àti wípé kí wọ́n fi ìwà akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ hàn, bọ̀wọ̀ fún àgbékalẹ̀ àkókò àti ètò, gẹ́gẹ́ bí ara àwọn nǹkan tí wọ́n ń fi ìdíje náà ṣe ìgbèlárugẹ rẹ̀.
Ìdíje ọ̀hún ni yóò ṣe atọ́nà fún àǹfààní, ìgbèlárugẹ ẹ̀bùn àti ògo, àríyá tó kẹnú, lábẹ́ ààbò tó péye.












Leave a Reply