SpyPen (Gègé Alamí)

News as it breaks.

Wọn Yóò Fi Àmì Ẹ̀yẹ Dá Gómìnà Adélékè, Arápájà, Awólọ́wọ̀ Lọ́lá Níbi Ayẹyẹ Ẹ̀ṣọ́ Orí Lágbáyé

IMG 20251223 WA0009

Enimere Àkànbí

Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun, Adémọ́lá Adéléké, wa lára àwọn tí wọn yóò fi àmì ẹ̀yẹ ṣe lọ́jọ̀ níbi ayẹyẹ Ẹ̀ṣọ́ orí lágbáyé (World Headdress Celebration) ẹlẹ́ẹ̀kéjì irúurẹ̀ tí yóò wáyé ní ọjọ́ àìkú, ọjọ́ kejìdínlọ́gbọ̀n oṣù kejìlá, ọdún 2025, ní ìlú Ìbàdàn, tí ṣe olú ìlú ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́.

Lára àwọn gbajúmọ̀ tí wọn yóò tún fi àmì ẹ̀yẹ dá lọ́lá níbi ètò àgbáyé ọ̀hún ni olùdásílẹ̀ ibùdó Àṣà (Nike Art Foundation and Nike Art Gallery) Olóyè, Arábìnrin Níkẹ̀ Monica Okundaye, fún akitiyan rẹ̀ nínú ṣíṣe àwọn Ẹ̀ṣọ́ orí lọ́tun, Akọ̀wé àpapọ̀ fún Ẹgbẹ́ òṣèlú Peoples Democratic (PDP), ẹni tó ti fi ìgbà kan rí jẹ́ igbákejì Gómìnà ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Ambassador Taofeek Ọládẹ̀jọ Arápájà, Adarí àgbà Àjọ tó ń rí sí ìdàgbàsókè ìrìn àjò afẹ́ ní ìpínlẹ̀ Èkìtì, Amọ̀fin Wálé Òjó-Láńre àti ẹni tó fẹ̀yìntì gẹ́gẹ́ bí agbóhùnsáfẹ́fẹ́, ní iléeṣẹ́ ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ ti ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Broadcasting Corporation of Oyo State (BCOS), Alhaji Ọ̀nalápọ̀ Gbọ́lágún.

Nínú àtẹ̀jáde láti ọwọ́ Alága Ẹgbẹ́ ọmọ Yorùbá Àtàtà (Omo Yoruba Atata Socio-cultural Initiative, OYASI), Ọ̀gbẹ́ni Ọláwálé Àjàó, tó jẹ́ alákòóso ayẹyẹ Ẹ̀ṣọ́ orí lágbáyé.

IMG 20251223 WA0008 300x157

 

 

Gẹ́gẹ́ bó ṣe wà nínú àtẹ̀jáde náà, ayẹyẹ Ẹ̀ṣọ́ orí lágbáyé, tí àkọ́kọ́ rẹ̀ wáyé ní ọjọ́ àìkú, ọjọ́ kejìdínlọ́gbọ̀n oṣù kejìlá, ọdún 2024, ni ẹ̀ẹ̀kejì rẹ̀ yóò wáyé ní déédéé aago méjìlá, lọ́jọ́ àìkú, ní gbàgede Erédàárayá bọ́ọ̀lù ẹlẹ́yin lórí kankéré, nínú pápáṣèrédárayá Lékan Salami, tó ń bẹ ní agbègbè Adámásingbà, Ìbàdàn.

Ọ̀gbẹ́ni Àjàó, ṣàlàyé pé àfojúsùn ayẹyẹ náà ni láti ṣe ìfọnrere ìmọrírì Ẹ̀ṣọ́ orí lágbàyé àti láti ṣe iṣẹ́ tọ bí ayẹyẹ ọ̀hún yóò ṣe jẹ́ àtẹ̀wọ́gbà Àjọ UNESCO.

Lára àwọn ètò tí wọ́n tún piyamọ fún ayẹyẹ Ẹ̀ṣọ́ orí lágbáyé ọ̀hún ni fífi àmì ẹ̀yẹ dá méjì nínú àwọn ọmọ Yorùbá àtàtà tó ti rebi-àgbànrè lọ́lá, ìyun-ùn Ẹni tó kọ́kọ́ jẹ́ alákòóso ìjọba ẹkùn ìwọ̀-ọọ̀rùn oríléèdè Nàìjíríà, Olóyè Ọbáfẹ́mi Awólọ́wọ̀ àti Ẹni tó jẹ́ Ààrẹ Mùsùlùmí ilẹ̀ Yorùbá, ìpínlè Edo àti Delta nígbà ayé rẹ̀, Alhaji AbdulAzeez Aríṣekọ́lá Àlàó, fún ìmọrírì iṣẹ́ takuntakun tí wọ́n ṣe nígbà ayé wọn.

IMG 20251223 WA0010 200x300

Bákan náà ni ìdíje gèlè dídì yóò wáyé láàrin àwọn tó tó gbahungba sùn lọ́yẹ́, tí àwọn mẹ́ta tó bá fakọyọ jù lọ yóò sì gba ẹ̀bùn tó jọjú, àmì ẹ̀yẹ ń bẹ fún ẹni tó bá gẹ fìlà tàbí wé gèlè tó yááyì jù lọ wá síbi ayẹyẹ Ẹ̀ṣọ́ orí lágbáyé.

Wọ́n sì gbagbo àwọn tó ń bọ̀ wá síbi ayẹyẹ ọ̀hún níyànjú láti ríi dájú pé wọ́n gẹ fìlà tàbí wé gèlè sí aṣọ wọn, ní ìbámu pẹ̀lú ayẹyẹ Ẹ̀ṣọ́ orí lágbáyé

Níbi ètò náà ni àwọn gbajúmọ̀ Ọ̀mọ̀wé nípa Àṣà àti ìṣe, bíi Àràbà ìlú Òṣogbo, Àràbà Ifáyẹmí Ẹlẹ́bùìbọn, Olúwòó ti ìlú Ìwó, Ọba Abdulrasheed Adéwálé Àkànbí àti Àgbà-ọ̀jẹ̀ òǹkọ̀wé ni, Alàgbà Débọ̀ Awe, yóò ti ṣe ìdánilẹ́kọ̀ọ́ nípa pàtàkì ẹ̀ṣọ́ orí láàrin àwọn ọmọ Yorùbá.

Kódà, ìrètí wà pé Olúbàdàn ilẹ̀ Ìbàdàn, Ọba Rashidi Ládọjà, ni yóò gba àwọn ọba aládé bíi Ṣọ̀ún ti ìlú Ògbómọ̀ṣọ́, Ọba Ghandi Afọlábí Ọláoyè àti Asẹ́yìn ti ìlù Ìsẹ́yìn, Ọba Sefiu Ọláwálé Oyèbọ́lá, lálejò.

Àtẹ̀jáde ọ̀hún fi kún-un pé Alága ètò ọjọ́ náà ni Alága iléeṣẹ́ ìwé ìròyìn Aláròyé àti ibùdó àṣà Yorùbá lágbáyé, Ọ̀gbẹ́ni Adébáyọ̀ Àlàó, tí wọ́n sì ń retí àwọn lọ́kọlọ́kì bíi Olùdásílẹ̀ iléeṣẹ́ rédíò Àgídìgbo, Alhaji Oríyọmí Hamzat, Olùdásílẹ̀ iléeṣẹ́ Deborah Adefunke Nigeria Ltd, Arábìnrin Deborah Olúfúnkẹ́ Awóyẹlé

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *