Enimere Àkànbí
Gómìnà nígbà kan rí ní ìpínlẹ̀ Òǹdó, Ọ̀gbẹ́ni Olúṣẹ́gun Mímikòó, ti kọwé fi Ẹgbẹ́ òṣèlú People Democratic party, PDP, sílẹ̀.
Ìfitónilétí tí Ọ̀gbẹ́ni Mímikòó, kọ sí alága Ẹgbẹ́ òṣèlú náà, ní ibùdó keje, ní ìjọba ìbílẹ̀ ìwọ̀-oòrùn Òǹdó, ni àwọn oníròyìn ti fi ojú gán-ní ìgbésẹ̀ rẹ̀.
Ọ̀gbẹ́ni Mímikò tó jẹ gómìnà ìpínlẹ̀ Òǹdó, láàrin ọdún 2009 sí 2016, kọ ọ́ sínú ìwé ìfitónilétí ọ̀hún pé ọjọ́ kẹwàá oṣù kẹrin ọdún ẹgbàá-lé-mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n, ni ìgbésẹ̀ òun ti bẹ̀rẹ̀ sí ní múlẹ̀.
Ó jẹ́ kó di mímọ̀ pé ìpinnu ìkéde àti ìfitónilétí ọ̀hún kò sẹ́yìn awuyewuye tó jẹ yọ nípa Ẹgbẹ́ òṣèlú tí òun ń ṣe àtìlẹyìn fún gan ní pàtó.
Ó ṣe àfikùn rẹ̀ pé ó ti ṣe díẹ̀ tí òun ti yẹra kúrò nínú ètò Ẹgbẹ́ òṣèlú, òun sì pinnu láti jẹ́ kí àwọn èèyàn mọ̀ pé òun kò bá Ẹgbẹ́ òṣèlú PDP ṣe pọ̀ mọ́.
Ó fi kún àlàyé rẹ̀ pé ìpinnu òun kò ní nǹkan ṣe pẹ̀lú pé òun bá ẹnikẹ́ni jà.
Gómìnà nígbà kan rí ọ̀hún, ni ó ti takété sí ọ̀rọ̀ Ẹgbẹ́ òṣèlú láti bíi ọdún díẹ̀ sẹ́yìn.
Sẹ́gun Adélakùn








Leave a Reply