SpyPen (Gègé Alamí)

News as it breaks.

ONÍṢÈGÙN PÀDÁNÙ Ẹ̀MÍ RẸ̀ LẸ́YÌN ÌRỌBÍ ÌBẸTA NÍPÌNLẸ́ BAYELSA

Enimere Àkànbí
Akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ ọnímọ̀ṣẹ̀gùn, Arábìnrin Ere Ogbachi, gbé ẹ̀mí mì lẹ́yìn ìdojúkọ ìrọbí ìbẹta nípìnlẹ́ Bayelsa.

Ojú òpó ayélujára Facebook, ni Arákùnrin olóògbé, Meshack Sintei, ti fìdí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí múlẹ̀, pẹ̀lú àlàyé pé, wọ́n gbé Arábìnrin ọ̀hún dìgbà dìgbà lọ sí ẹ̀ka tí wọ́n ti ń pèsè ìlera fún àwọn tí àìlera wọn ti fẹ́ bọ́wọ́-órí, ní ilé ìwòsàn ìjọba àpapọ̀ tó ń bẹ nílùú Yenagoa, níbi tó ti gbé ẹ̀mí mì ní nǹkan aago mẹ́ta òru ku ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀dógún, lọ́jọ́ kẹrìnlá, oṣù kẹrin, ọdún ẹgbàá-lé-mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n (2026).

Gẹ́gẹ́ bíi aṣe ríi kà nínú àtẹ̀jáde láti ọwọ́ mọ̀lébí rẹ̀, ìdojúkọ náà wáyé lẹ́yìn tó bímọ tán, èyí tó mú kí wọ́n tètè gbé e lọ sí ẹ̀ka tí wọ́n ti ń pèsè ìlera fún àwọn tí àìlera wọn ti fẹ́ bọ́wọ́-órí.

Nígbà tí àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ̀ ń sọ̀rọ̀ nípa àkókò ìgbẹ̀yìn olóògbé, wọ́n sọ pé àwọn ọnímọ̀ṣẹ̀gùn sa ipá wọn láti dóòlà ẹ̀mí rẹ̀, ṣùgbọ́n pàbó ni gbogbo rẹ̀ já sí.

Wọ́n jẹ́ kó di mímọ̀ nínú àtẹ̀jáde náà pé agbára ẹ̀rọ tó ń ṣe ìrànwọ́ fún èémí, jáwálẹ̀ lójijì lákòókò tí wọ́n ń fún-un ní ìtọ́jú pàjáwìrì.

Sintei, sọ pé, ìpàdánù Arábìnrin náà ba ọkàn àwọn mọ̀lẹ́bí jẹ́ gidigidi, wọ́n sì ṣàpèjúwe olóògbé gẹ́gẹ́ bíi ẹni akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ oníṣègùn tó ní ìfarajìn.

Arábìnrin Ogbachi, tó bí ìbẹta jẹ́ akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ oníṣègùn, àti ọmọ ẹgbẹ́ oníṣègùn lórílẹ̀èdè Nàìjíríà, lẹ́yìn tó kọ́ ẹ̀kọ́ gboyè ní ilé ẹ̀kọ́ gíga Fáṣítì Niger Delta.

Sẹ́gun Adélakùn

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *