SpyPen (Gègé Alamí)

News as it breaks.

Alága Àná F’Àjọ OYSIEC Dọ́wọ̀ọ́ Ìdùnnú Ayẹyẹ Ọjọ́ Ìbí Pẹ̀lú Gómìnà Mákindé

IMG 20251225 WA0013

Enimere Àkànbí
Alága àná fún Àjọ elétò ìdìbò ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, OYSIEC, Ààrẹ Isiaka Ọlágúnjú (SAN) ti kí Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Ṣèyí Mákindé, kú u ayẹyẹ ọjọ́ ìbí ọdún kejìdínlọ́gọ́ta, ó sì ṣe àpèjúwe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi aṣáájú tó ní àfojúsùn, tí ìlànà ìṣèjọ̀ba rẹ̀ ń tẹ̀síwájú láti má a gbé ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ lékè láàrin àwọn ìpínlẹ̀ gbogbo tó ń bẹ ní oríléèdè Nàìjíríà.

Gẹ́gẹ́ bó ṣe jẹyọ nínú àtẹ̀jáde tí Àgbà-ọ̀jẹ̀ Agbẹjọ́rọ̀ ọ̀hún, tó tún jẹ́ Alága ìgbìmọ̀ ìṣàkóso Ẹgbẹ́ Amòfin Oòduà (The Yoruba Lawyers Forum), Ààrẹ Ọlágúnjú, buwọ́lu, tó sì gbóríyìn fún Gómìnà Mákindé, fún bó ṣe ń ṣe iṣẹ́ tọ ìdàgbàsókè jáléjáko, ìpèsè àti àtúnṣe àwọn nǹkan amáyédẹrùn, láì jẹ́ kó gbún ètò ìgbàyégbádùn àwọn ará ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́.

Bákan náà ló sọ pé lábẹ́ ìṣàkóso Gómìnà Mákindé, ìdàgbàsókè àti ìlọsíwájú aláìlẹ́gbẹ́ ti bá gbogbo ẹ̀ka, pẹ̀lú àfikún pé ìṣàkóso ònílànà tó ní ṣe pẹ̀lú àwọn aráàlú, ti mú kí àwọn ará ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ní ìgbàgbọ́ kíkún nínú ìṣèjọ̀ba.

Gẹ́gẹ́ bó ṣe ṣàlàyé, ìlànà ìfọmọnìyànṣe, ìgboyà àti ìgbésẹ̀ akin tí Gómìnà Mákindé ń lò fi ṣe ìjọba, mú u tayọ láàrin àwọn tó ti ṣe ìṣàkóso ìlú rí, tí yóò sì tún jẹ́ àwòkọ́ṣe fún àwọn aṣáájú lọ́jọ́ iwájú.

Ààrẹ Ọlágúnjú, wá ṣe bẹ Elédùmarè láti túbọ̀ má a ran Gómìnà Mákindé lọ́wọ́ pẹ̀lú àṣeyọrí nínú àwọn nǹkan tó bá ń dá ọwọ́ lé lórí.

Bákan náà ló fi àkókò ọ̀hún gba àwọn olùgbé ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ níyànjú láti túbọ̀ má a ṣe àtìlẹyìn fún ìṣàkóso Gómìnà Mákindé, nínú akitiyan láti túbọ̀ mú àṣeyọrí àti ìṣọ̀kan bá ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́.

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *