SpyPen (Gègé Alamí)

News as it breaks.

Alága Àjọ OYSIEC, Ààrẹ Ọlágúnjú, Gba Àmì Ẹ̀yẹ IMV

IMG 20241125 WA0015

Enimere Àkànbí
Ẹgbẹ́ Ìbàdàn Mega Voice, IMV, ti fi àmì ẹ̀yẹ dá alága àjọ elétò ìdìbò ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, (OYSIEC), Mọ́gàjí Isiaka Abíọ́lá Ọlágúnjú, tó jẹ́ àgbàọ̀jẹ̀ agbẹjórò SAN, lọ́lá gẹ́gẹ́ bíi ènìyàn tó tayọ jùlọ láwùjọ.

Gẹ́gẹ́ bí ẹgbẹ́ ọ̀hún ṣe sọ, àmì ẹ̀yẹ náà ni wọ́n gbé kalẹ̀ láti fi dúpẹ́ lọ́wọ́ Mọ́gàjí Ọlágúnjú, fún akitiyan rẹ̀ tó tayọ, nínú ìdàgbàsókè ìlú Ìbàdàn.

Nígbà tó ń fèsì, alága àjọ OYSIEC, Mọ́gàjí Isiaka Abíọ́lá Ọlágúnjú, tó jẹ́ àgbàọ̀jẹ̀ agbẹjórò SAN, fi ẹ̀mí ìmọore hàn sí ẹgbẹ́ ọ̀hún, nítorí bí wọ́n ṣe kàáyẹ fún àmì ẹ̀yẹ náà.

Mọ́gàjí Ọlágúnjú, tí alákòóso ẹ̀ka ìròyìn fún àjọ OYSIEC, Ọ̀gbẹ́ni Adédàmọ́lá Adégòkè, ṣojú fún, yin àwọn ọmọ ẹgbẹ́ IMV láwo, fún ìwà akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ tí wọ́n fi hàn nínú ṣe iṣẹ́ ìríjú wọn, ó sì gbà wọ́n níyànjú láti má ṣe yẹsẹ̀ kúrò ní ojú ọ̀nà tí wọn ń tọ̀.

Nínú ọ̀rọ̀ Ààrẹ ẹgbẹ́ Ìbàdàn Mega Voice IMV, Ààrẹ Kọ́lá Olomide, sàlàyé pé àwọn ọmọ bíbí ìlú Ìbàdàn àti àwọn tó jẹ́ àjòjì, tó ń kópa nínú ìdàgbàsókè agbègbè wọn àti ìlú Ìbàdàn ní àpapọ̀, ni àwọn fi àmì ẹ̀yẹ dá lọ́lá.

Ààrẹ Olomide, tó fi àkókò ọ̀hún mú ẹnu ba àwọn àkànṣe iṣẹ́ tí ẹgbẹ́ náà fẹ́ ṣe, ké sí ẹni gbogbo láti wá ṣe àtìlẹyìn àti ìkùnlọ́wọ́ fún ẹgbẹ́ náà nínú akitiyan láti kọ́ ibùjókòó ìyá ẹgbẹ́ náà, ríra ọkọ̀ akérò amúṣẹ́yá àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀lọ.

Bákan náà ló dúpẹ́ lọ́wọ́ gbogbo àwọn tó gba àmì ẹ̀yẹ, fún àjọṣepọ wọn pẹ̀lú ẹgbẹ́ Ìbàdàn Mega Voice.

Àwọn gbajúmọ̀ tí wọ́n fi àmì ẹ̀yẹ dá lọ́lá níbi ayẹyẹ àjọ̀dún kejì ẹgbẹ́ Ìbàdàn Mega Voice, tó wáyé nínúu gbọ̀ngàn àríyá Bọ̀dé Àmàó, tó ń bẹ ní agbègbè Òkè-Àrẹ̀mọ, ní ìlú Ìbàdàn, ni Ààrẹ kááfàtà fún àgbàríjọpọ̀ ẹgbẹ́ àwọn ọmọbíbí ìlú Ìbàdàn, Olóyè Sulaimon Ajéwọlé, Alága Àjọ tó ń ṣètò ìrìn àjò Hajj ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Sheikh Hashim Abdul-Wahab Atẹ́rẹ́, Mọ́gàjì Abdul-Sabur Ọláwóore, Ọnarébù Báyọ̀ Amusat-Gbénlá, gbajúgbajà olórin Fuji, Alhaji Táyé Adébísí àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀lọ.

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *