SpyPen (Gègé Alamí)

News as it breaks.

‎Ilé-ẹjọ́ Dájọ́’kú Fún Alfa, Tó Pa Akẹ́kọ̀ọ́ Fé’tùtù Ọlà Nílùú Ìlọrin

IMG 20250731 WA0013 1140x729 1

Enimere Àkànbí
‎Ilé-ẹjọ́ gíga ìpínlẹ̀ Kwara tó fìdí kalẹ̀ sílùú Ìlọrin, ti dá ẹjọ́ ikú fún ẹnìkan tó ní ìmọ̀ nípa ẹ̀sìn Islam, Abdulrahman Mohad, nítorí pé ó jẹ̀bi ẹ̀sùn ìṣekúpa akẹ́kọ̀ọ́ tó wà ní ìpele tó kẹ́yìn ní ilé-ẹ̀kọ́ olùkọ́ àgbà ti ìpínlẹ̀ Kwara, Hafsoh Yétúndé Lawal, láti fi ṣe ètùtù ọlà.
‎
‎Onídàjọ́ Hannah Àjàyí, ló gbé ìdájọ́ náà kalẹ̀, ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ẹ̀rí tí wọ́n mú wá sí Ilé-ẹjọ́ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀hún tó wáyé ní ọjọ́ kẹwàá, oṣù kejì, ọdún 2025.
‎
‎Hafsoh Lawal, ni wọ́n sọ pé ó nù lẹ́yìn tí ó gba ìpè lórí ẹ̀rọ ìbára-ẹnisọ̀rọ̀ níbi ayẹyẹ ìkọ́mọjáde tó lọ, tí àwọn ẹbí àti ọ̀rẹ́ sì wa títí, kó tó di pé wọ́n lọ fi tó àwọn ọlọ́ọ̀pá létí ní iléeṣẹ́ wọn tó ń bẹ ní agbègbè Ọjà Ọba, ní ìlú Ìlọrin, ní ọjọ́ kejì.

Related Stories: Ọ̀yọ́ Assembly Seeks To Preserve Yorùbá Culture, Urges Executive To Ẹ̀dá Onílé-Ọlá

‎Nínú iṣẹ́ẹ̀wádìí àwọn ọlọ́ọ̀pá, ni wọ́n ti lo ẹ̀rọ ìbára-ẹnisọ̀rọ̀ Hafsoh Lawal, láti tọpasẹ̀ Mohad, gẹ́gẹ́ bíi ẹni tí ó bá sọ̀rọ̀ kẹ́yìn, èyí ló ràn wọ́n lọ́wọ́ láti rí onímọ̀ nípa ẹ̀sìn Islam, náà mùú.
‎
‎Bákan náà ni ọwọ́ wọn tún ba Ahmed Abulwasiu, Sulaiman Muhydeen, Jamiu Uthman, àti AbdulRahman Jamiu, fún ẹ̀sùn pé wọ́n kún Mohad lọ́wọ́ nínú ìwà ọ̀daràn ọ̀hún.
‎
‎Ṣùgbọ́n nítorí pé agbèfọ́ba kúnà láti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé àwọn mẹ́rin náà tí ọwọ́ báà, lọ́wọ́ nínú bí Mohad ṣe pa Hafsoh Lawal, láti fi ṣe ètùtù ọlà, Onídàjọ́ Àjàyí, sì dá wọn sílẹ̀, pé kí wọ́n má a lọ.
‎
‎Onídàjọ́ Àjàyí, ló ṣe àmúlò àwọn ẹ̀rí tí wọ́n pèsè ní Ilé-ẹjọ́ gíga ọ̀hún àti fọ́nrán amóhùnmáwòrán tí Mohad, ti ṣe àpatẹnujẹ́wọ́ pé òun nìkan ló pa arábìnrin náà tó jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́, tí àwọn mẹ́rin yókù kò sì mọ ohunkóhun nípa rẹ̀.
‎
‎Ṣáájú ni àbọ̀ ìwádìí àwọn ọlọ́ọ̀pá fihàn pé àwọn mẹ́rin yókù, jẹ́wọ́ pé ọmọ ẹlẹ́gbẹ́ òkùnkùn kan-náà ni àwọn, tí àwọn síì ma ń lọ́wọ́ nínú olè jíjà àti Ìṣekúpa ni, ṣùgbọ́n nítorí bí Mohad ṣe tẹnu mọ́ọ̀ pé òun dá ìwà ọ̀daràn náà ṣe ni, ló yọ ọ̀ràn kúrò ní ọ̀run wọn.
‎

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *