Enimere Àkànbí
Ikọ̀ ológun oríléèdè Nàìjíríà ti dóòlà èèyàn mẹ́tàlá tó jẹ́ èrò inú ọkọ̀ tí àwọn agbébọn jí gbé ní ọjọ́rú tó kọjá lójú ọ̀nà Makurdi sí Otukpo, ní ìpínlẹ̀ Benue.
Àbọ̀ ìròyìn tí Àjọ tó ń kó ìròyìn jọ lórílẹ̀èdè Nàìjíríà, News Agency of Nigeria (NAN), fi léde, ni wọ́n ti jẹ́ kó di mímọ̀ pé nǹkan àfẹ̀mọ́jú òní, lákòókò tí àwọn ikọ̀ ológun ń tú inú igbó ńlá tó ń bẹ ní Okete Ward, ní ìjọba ìbílẹ̀ Ohimini, yẹ́bẹ́yẹ́bẹ́, ni wọ́n ṣe àwárí wọn.
Àbọ̀ ìròyìn ọ̀hún fi kún un pé mẹ́ta nínú àwọn èrò inú ọkọ̀ náà ló ti kọ́kọ́ gba òmìnira ṣáájú àkókò yìí, tí wọ́n sì ti darapọ̀ mọ́ àwọn ẹbí wọn, tí àwọn ikọ̀ aláàbò sì ń tẹ̀síwájú pẹ̀lú akitiyan láti ṣàwárí àwọn yòókù.
Ojú ẹsẹ̀ tí wọ́n rí àwọn èrò inú ọ̀hún ni wọ́n kó wọn lọ fún àyẹ̀wò ní ilé ìwòsàn ńlá ìjọba tó ń bẹ ní Otukpo, níbi tí wọ́n ti ń gba ìtọ́jú fún ìfarapa tí wọ́n ní lákòókò tí wọ́n wà ní ìgbèkùn.
Ṣáájú ni iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Benue àti Àjọ tó ń ṣètò ìdánwò aláṣewọ àwọn ilé ẹ̀kọ́ gíga lórílẹ̀èdè Nàìjíríà, jẹ́ kó di mímọ̀ pé àwọn èrò inú ọkọ̀ tí wọ́n jígbé lójú ọ̀nà Makurdi sí Otukpo nípìnlẹ́ Benue, kíi ṣe àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó fẹ́ lọ ṣe ìdánwò ọ̀hún tọdún 2026.
Igun méjèèjì nínú àtẹ̀jáde ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí wọ́n fi léde, ni wọ́n ti ṣe àfọ̀mọ́ ọ̀rọ̀ tó di tọ́rọ́fọ́nkálé láti ìgbà tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti wáyé lójúrú ọ̀sẹ̀ tó kọjá.
Àtẹ̀jáde ọ̀hún láti ọwọ́ agbenusọ iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Benue, DSP Edet Udeme, fi kún un pé ọwọ́ ti bá èèyàn méje tí wọ́n fura sí, tí díẹ̀ lára àwọn tí wọ́n mú sígbèkùn sì ti rí òmìnira gbà, láti ara akitiyan àwọn ikọ̀ aláàbò gbogbo.
Bákan náà ni agbenusọ Àjọ JAMB, Fabian Benjamin, nínú àtẹ̀jáde fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé àwọn tí wọ́n jígbé jẹ́ ara àwọn tó ń kópa nínú ètò ìgbani sí iṣẹ́ ọlọ́pàá, tí wọ́n ń padà sí Otukpo lákòókò tí ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀hún wáyé.









Leave a Reply