Enimere Àkànbí
Àjọ elétò ìdìbò nípìnlẹ́ Ọ̀yọ́ (OYSIEC) ti kọná mọ́ ìgbáradì fún ètò ìdìbò ìjọba ìbílẹ̀ tó fẹ́ wáyé lọ́dún ẹgbàá-lé-mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n, nípa ṣíṣe ìpàdé tó gbọhungbọ́n pẹ̀lú àwọn alákòóso ètò ìdìbò láwọn ìpínlẹ̀ mẹ́tàlélọ́gbọ̀n tó ń bẹ ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́.
Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ níbi ìpàdé ọ̀hún tó wáyé ní olú iléeṣẹ́ Àjọ OYSIEC, tó ń bẹ ní agbègbè Agodi-Gate, Ìbàdàn, Alága Àjọ náà, Ọ̀mọ̀wé Afees Adéníyì, pè fún àtìlẹyìn àti ìmúratán àwọn òṣìṣẹ́ Àjọ ọ̀hún láwọn ìjọba ìbílẹ̀, nínú ṣíṣe iṣẹ́ tọ ètò ìdìbò tó mányánlórí, ní ìlànà gbangba làṣá ń ta.
Ọ̀mọ̀wé Adéníyì, gba àwọn alákòóso ètò ìdìbò láwọn ìjọba ìbílẹ̀ (EOs) àti àwọn igbákejì wọn (AEOs) níyànjú láti ṣe iṣẹ́ ìríjú wọn bó ṣe yẹ àti ní ìbámu pẹ̀lú ìlànà Àjọ OYSIEC, ó fi kún pé wọ́n ní láti ṣe dédé pẹ̀lú àwọn olùdíje, kí wọ́n sì yẹra fún àwọn ìwà kòtọ́.
Ọ̀mọ̀wé Adéníyì, tó fi ìmúratán Àjọ náà láti ṣètò ìdìbò tó péye láwọn ìjọba ìbílẹ̀, fi kún-un pé àwọn òṣìṣẹ́ Àjọ náà ní láti ṣe ojúṣe wọn ní ìbámu pẹ̀lú àgbékalẹ̀ òfin, fún àǹfààní àwọn ará ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́.
Nínú ọ̀rọ̀ Alága àwọn aṣáájú Àjọ elétò ìdìbò ní àwọn ìjọba ìbílẹ̀ gbogbo tó ń bẹ ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Ọ̀mọ̀wé Olúṣẹ́gun Ọdẹ́kúnlé, gbóríyìn fún ìṣàkóso tuntun tó ń tukọ̀ Àjọ náà, fún bí wọ́n ṣe ń wá àtìlẹyìn àwọn, ó sì fi Àjọ OYSIEC lọ́kàn balẹ̀ pé àwọn yóò ríi dájú pé ohunkóhun kò gbún ètò ìdìbò náà láti jẹ́ kó mányánlórí, kí ohun gbogbo sì lọ létòletò.
Ọ̀mọ̀wé Ọdẹ́kúnlé, gba Àjọ OYSIEC, níyànjú láti tẹ̀síwájú láti má a mú ìgbàyégbádùn àwọn alákòóso ètò ìdìbò láwọn ìjọba ìbílẹ̀ (EOs) àti àwọn igbákejì wọn (AEOs) lọ́kùnkúndùn ṣáájú, lákòókò àti lẹ́yìn ètò ìdìbò ìjọba ìbílẹ̀ ọdún yìí.
Bákan náà ló ṣèlérí àtìlẹyìn wọn fún àṣeyọrí ètò ìdìbò ọ̀hún láti leè jẹ́ kó jẹ́ àtẹ́wọ́gbà àwọn aráàlú.












Leave a Reply