Enimere Àkànbí
Ìjọba ìpínlẹ̀ Borno ti fi àwọn aráàlú lọ́kàn balẹ̀ pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ikọ̀ agbésùnmọ̀mí tí wọ́n ń gbà padà sí ààrin ìlú nítorí pé wọ́n ti ronúpìwàdà, kò leè padà sínú ìwà ìríra wọn mọ́.
Àwọn onítọ̀hún ni wọ́n ń gbà padà sí àwùjọ lẹ́yìn tí wọ́n ṣe ètò ìlanilọ́yẹ fún wọn ní ibùdó ìtùnirọ.
Ìjọba ìpínlẹ̀ Borno ṣàlàyé pé lára ohun tí àwọn ṣe fún wọn ni fífi Quran búra pé àwọn kò ní padà sínú ìwà àtijọ́ wọn mọ́, ìgbésẹ̀ ọ̀hún ni ìjọba ìpínlẹ̀ náà wòye pé, ó gbéwọ̀n tó láti mú wọn takété sí àwọn nǹkan ìjà àti ìwà ìṣekúpa ni.
Alákòóso tó nri sí ọ̀rọ̀ àwọn obìnrin àti ìdàgbàsókè ètò amúlùúdùn nípìnlẹ́ Borno, Zuwaira Gambo, nínú ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò lórí ètò iléeṣẹ́ móhùnmáwòrán kan, ṣàlàyé pé kò sí èèyàn tó ṣe lòdì sí ìbúra tó fi ìwé mímọ́ ọ̀hún ṣe, tí ọ̀rọ̀ kò ní lẹ́yìn fún.
Ṣùgbọ́n sá, alákòóso náà tọ́ka sí ọ̀dá owó gẹ́gẹ́ bíi ọ́kan lára ìdojúkọ gbòógì tí ó ń ṣe àkóbá fún lílọ gerege ètò ọ̀hún
Ó ṣàlàyé síwájú pé ìjọba ní láti wá ọ̀nà bí yóò ṣe pèsè oúnjẹ, aṣọ àti àwọn ohun tó yẹ fún àwọn tí wọ́n ń kó wá sí ibùdó náà fún ìtúnrọ.
Sẹ́gun Adélakùn











Leave a Reply