SpyPen (Gègé Alamí)

News as it breaks.

Nítorí Owó Egúngún Fẹ́mi Gún Bùkúnmi Pa Lọ́ṣun

masquerade

Enimere Àkànbí
Àríyànjiyàn tó bẹ́ sílẹ̀ láàrin mẹ́ta lára àwọn tó kópa nínú ọdún Egúngún nílùú Ilare, nípìnlẹ́ Ọ̀ṣun, ti padà yọrí sí ikú fún ọ̀kan nínú wọn tí wọ́n pe orúkọ rẹ̀ ní Bùkúnmi.

Méjì lára àwọn tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣojú wọn, tí wọn kò fẹ́ kí orúkọ wọn jẹ yọ nínú ìròyìn, ṣàlàyé pé Bùkúnmi, Fẹ́mi àti Pẹ̀lúmi, kópa nínú ayẹyẹ ọdún Egúngún tó wáyé lọ́jọ́ ẹtì, kó wá tó di pé wọ́n lọ pín owó tí wọ́n rí níbẹ̀.

Ṣùgbọ́n àríyànjiyàn bẹ́ sílẹ̀ lákòókò tí wọ́n ń pín ẹgbẹ̀rún mẹ́jọ náírà tí wọ́n rí.

Ní nǹkan aago méje ààbọ̀ alẹ́ ọjọ́ ẹtì ni àwọn géńdé ọkùnrin nílùú Ilare ń dọ́wọ̀ọ́ ìdùnnú ọdún eégún, tí wọ́n sì ń gba owó lọ́wọ́ àwọn èèyàn

Lẹ́yìn gbogbo ètò, àwọn mẹ́ta tí wọ́n jọ ṣe iṣẹ́ pọ̀ gẹ́gẹ́ bíi ikọ̀, fẹ́ pín ẹgbẹ̀rún mẹ́jọ náírà tí wọ́n rí, ni èèṣù bẹ́ sílẹ̀ láàrin wọn.

Pẹ̀lúmi àti Bùkúnmi, tó wá láti inú ẹbí kan náà, ló ní èdè-àìyedè, tí Fẹ́mi sì bá wọn dá síi, pé kí wọ́n má jà, lójijì ni Bùkúnmi pajúdà sí Fẹ́mi, tó sì kàn-án ní ẹ̀ṣẹ́ lẹ́nu, èyí ló bí Bùkúnmi nínú, tó sì fi ọ̀bẹ gún Bùkúnmi pa.

Lẹ́yìn ìṣẹ̀lẹ̀ yìí, ni àwọn èèyàn tó wà nítòsí gbé Bùkúnmi dìgbà dìgbà lọ sí ilé ìwòsàn, àwọn míì múra láti gbé ìjà ko Fẹ́mi lójú, ṣùgbọ́n àwọn ikọ̀ ààbò ara ẹni lààbò ìlú, NSCDC, tó tètè dé ibi tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti wáyé, gbàá sílẹ̀ lọ́wọ́ wọn, wọ́n sì fi lé àwọn ọlọ́pàá ẹkùn Ẹ̀sà Òkè lọ́wọ́.

Ìròyìn padà kan àwọn èèyàn ku pé ọgbẹ́ ọ̀bẹ ọ̀hún ti gba ẹ̀mí Bùkúnmi, tí àwọn ọlọ́pàá sì ti mú ọ̀bẹ náà lọ, bákan náà ni wọ́n gbé ẹni tí wọ́n fura sí àti òkú Bùkúnmi, lọ.

Nígbà tí àwọn oníròyìn kàn sí agbẹnusọ iléeṣẹ́ ọlọ́pàá lórílẹ̀èdè yìí, ẹ̀ka ti ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun, Ọ̀gbẹ́ni Abíọ́dún Ọ̀jẹ̀labí, ó fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé òótọ́ ni ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀hún.

Pẹ̀lú àfikún pé àwọn ti gbé òkú Bùkúnmi sí ilé ìgbé òkú sí, tí ìwádìí sì ń tẹ̀síwájú.
Sẹ́gun Adélakùn

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *