Enimere Àkànbí
Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Ṣèyí Mákindé, ti kéde Ọ̀gbẹ́ni Bímbọ̀ọ́ Adékánḿbí, gẹ́gẹ́ bíi ààyò àti ẹni tí yóò rọ́pò rẹ̀ ní ipò Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ lẹ́yìn ètò ìdìbò gbogbogbò tí yóò wáyé lórílẹ̀èdè Nàìjíríà ní ọdún ẹgbàá-lé-mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n
Ọ̀gbẹ́ni Adékánḿbí, tó ti fìgbà kan rí jẹ́ Alákòóso ètò owónàá, lábẹ́ ìṣàkóso olóògbé Isiaka Ajúmọ́bi, ló jẹ́ alága ìgbìmọ̀ tó ń ṣe àmójútó àtúnṣe àti ìgbésẹ̀ sísọ pápákọ̀ òfurufú Ládòkè Akintọ́lá tó ń bẹ nílùú Ìbàdàn, di ti àgbáyé.
Agbẹnusọ Ẹgbẹ́ òṣèlú Peoples Democratic (PDP) ẹ̀ka ti ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Ọ̀gbẹ́ni Michael Ògúnṣínà, ló jẹ́ kó di mímọ̀ nínú àtẹ̀jáde.
Gẹ́gẹ́ bí Ọ̀gbẹ́ni Ògúnṣínà, ṣe ṣàlàyé nínú àtẹ̀jáde ọ̀hún, Ọ̀gbẹ́ni Adékánḿbí, ni Gómìnà Mákindé fi ọkàn tán pé ó leè tẹsẹ̀ bọ bàtà ipò tí òun fẹ́ bọ́ sílẹ̀, tí yóò sì má a bá iṣẹ́ rere tí òun ti ń ṣe bọ̀ láti ọdún ẹgbàá-lé-mọ́kàndínlógún, lọ.
Ọ̀gbẹ́ni Adékánḿbí tó darapọ̀ Mọ́ Ẹgbẹ́ òṣèlú PDP ní kété tí Gómìnà Mákindé wọlé ìbò ipò Gómìnà fún sáà kejì, ní ọdún ẹgbàá-lé-mọ́kànlélógún, ló ti fìgbà kan rí jẹ́ igbá-kejì olórí òṣìṣẹ́ ní ọ́fìsìì Gómìnà nígbà ìṣàkóso Olóògbé Ajímọ̀bi.
Gómìnà Mákindé tó ń lo sáà kejì rẹ̀ lọ́wọ́ nípò àṣẹ tó ga jù lọ nípìnlẹ́ Ọ̀yọ́, ni yóò gbé ìjọba kalẹ̀ ní ọjọ́ kọkàndínlọ́gbọ̀n, oṣù karùn-ún, ọdún ẹgbàá-lé-mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n.
Bẹ́ẹ̀ oṣù kínní ọdún ẹgbàá-lé-mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n ni ètò ìdìbò gbogbogbò yóò bẹ̀rẹ̀ láti yan àwọn tí yóò ṣe ìṣàkóso fún ọdún mẹ́rin míì.
Nínú ìròyìn míì láti gbọ́ pé Gómìnà Mákindé, tó ṣẹ̀ṣẹ̀ dé láti ìlú Abuja, ṣe ìpàdé bòńkẹ́lẹ́ pẹ̀lú àwọn tọ́rọ̀ kàn nínú Ẹgbẹ́ òṣèlú Allied Peoples Movement (APM), ní ilégbèé rẹ̀ tó ń bẹ ní agbègbè Ìkọ́làbá, Ìbàdàn.
Ìpàdé ọ̀hún wáyé lákòókò tí ọ̀rọ̀ ń jà rọ̀hìnrọ̀hìn pé, ó ṣe é ṣe kí Gómìnà Mákindé fi Ẹgbẹ́ òṣèlú PDP sílẹ̀ nítorí ọ̀rọ̀ tí kò tíì níyanjú láàrin àwọn aṣáájú Ẹgbẹ́ òṣèlú náà.











Leave a Reply