Enimere Àkànbí
Ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Arsenal, ti oríléèdè England ti peregedé sí àṣekágbá ìdíje àwọn akọni Ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù ní ilẹ̀ aláwọ̀ funfun, UEFA Champions League.
Èyí rí bẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n fi àgbà han Ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Athletico Madrid, láti oríléèdè Spain, pẹ̀lú àpapọ̀ àmì méjì sí ẹyọ̀kan, ní ìgbéṣẹ̀ méjì ìpele tó kángu sí àṣekágbá.
Ìgbésẹ̀ àkọ́kọ́ tó wáyé ní oríléèdè Spain parí sí ọ̀mì ayò kọ̀ọ̀kan láàrin Ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù méjèèjì, tí Arsenal sì ṣe àṣeparí iṣẹ́ wọn ní pápáṣeré ìdárayá Emirates, ní ìgbésẹ̀ kejì, pẹ̀lú àmì ayò kan sí òfo.
Bùkáyọ̀ Saka, ló gbá bọ́ọ̀lù ọ̀hún wọ inú àwọn Athletico Madrid, tí Arsenal fi ní ìṣẹ́gun.
Èyí sì ni ìgbà àkọ́kọ́ láti ogún ọdún sẹ́yìn tí Ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Arsenal yóò wọ àṣekágbá ìdíje náà tó ńíkìmí jùlọ ní ààrin àwọn Ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù tó ń bẹ láwọn oríléèdè aláwọ̀ funfun.
Wọn yóò má a retí ọ̀kan láàrin Ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Bayern Munich àti Paris Saint German, PSG, ní àṣekágbá, tí yóò wáyé nílùú Budapest.
Ọdún ẹgbàá-lé-mẹ́fà tí Arsenal wọ àṣekágbá ọ̀hún fún ìgbà àkọ́kọ́ àti èyí tó kẹ́yìn, wọ́n fìdírẹmi sọ́wọ́ Ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Barcelona, láti oríléèdè Spain.












Leave a Reply