SpyPen (Gègé Alamí)

News as it breaks.

Owoṣeéní Tó Kọ Iṣẹ́ Mákindé Sílẹ̀, Fi Ìfẹ́ Hàn Láti Di Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́

images (1)

…..Nígbà Tí Mákindé Ṣe Ìpàdé Lórí Ìtẹ̀síwájú Iṣẹ́ Rere Nípìnlẹ́ Ọ̀yọ́

Enimere Àkànbí
Ọjọ́ díẹ̀ lẹ́yìn tí ó kọ̀wé fi ipò sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi olùrànlọ́wọ́ Gómìnà Ṣèyí Mákindé lórí ọ̀rọ̀ ètò ààbò, ẹni tó ti fìgbà kan rí jẹ́ Ọ̀gá àgbà ọlọ́pàá nípìnlẹ́ Benue àti ìpínlẹ̀ Èkó, kó tó di pé ó fi ẹ̀yìn tì nínú iṣẹ́ ọlọ́pàá, Fatai Owoṣeéní, ti darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú Accord nípìnlẹ́ Ọ̀yọ́.

images (2)

Níbi ètò kan tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn olóṣèlú àti alátìlẹyìn péjúpésẹ̀ sí ní olú ilé ìyá Ẹgbẹ́ òṣèlú Accord nípìnlẹ́ Ọ̀yọ́, tó ń bẹ lágbègbè Yemetu nílùú Ìbàdàn, ni Owoṣeéní, ti darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú ọ̀hún, tó sì gba àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú náà níyànjú láti fi ààyè gba àjùmọ̀ṣe pọ̀ àti ṣíṣe iṣẹ́ gẹ́gẹ́ bíi ikọ̀ láti gbé Ẹgbẹ́ wọn dé ibi gíga.

Bákan náà ló gba ìwé ìfèròngbà hàn láti díje dupò Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ lọ́dún ẹgbàá-lé-mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n.

Owoṣeéní, fi kún pé jíjókòó tẹtẹrẹ kò leè ran yálà Ẹgbẹ́ òṣèlú tàbí ìṣèjọ̀ba àwarawa lápapọ̀ lọ́wọ́ nínú ìmúṣẹ àfojúsùn.

img 20260509 wa0021

Bẹ́ẹ̀, nígbà tí Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Ṣèyí Mákindé, ń bá àwọn ikọ̀, àṣọmọgbè àti àwọn alábàáṣepọ̀ rẹ̀ lágbo òṣèlú, ṣe ìpàdé, ó gbà wọ́n níyànjú láti ṣe ara wọn lọ́kàn, lójúnà láti ríi dájú pé afẹ́fẹ́ ìdàgbàsókè tó ń fẹ́ nípìnlẹ́ Ọ̀yọ́ tẹ̀síwájú kọjá ọdún ẹgbàá-lé-mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n.

Gómìnà Mákindé, jẹ́ kó di mímọ̀ pé àwọn kan ti ń yin òun fún ìṣèjọ̀ba tó yàtọ̀ tí òun gbé kalẹ̀ nípìnlẹ́ Ọ̀yọ́, ó sì wí pé àwọn ikọ̀ ọ̀hún gan ni ó yẹ kó gba oríyìn ọ̀hún.

Mákindé sì gba gbogbo àwọn aṣáájú Ẹgbẹ́ òṣèlú rẹ̀, àwọn tọ́rọ̀ kàn àti pàápàá jù lọ àwọn tó ń fi ìfẹ́ hàn fún ipò òsèlú lọ́dún ẹgbàá-lé-mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n níyanjú, láti di ara wọn mú ṣinṣin, kí wọ́n ṣe iṣẹ́ pọ̀ bíi ikọ̀, kí iṣẹ́ rere tó ti bẹ̀rẹ̀ láti ọdún ẹgbàá-lé-mọ́kàndínlógún, le má a tẹ̀síwájú.

img 20260509 wa0022

Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, tún gbà wọ́n nímọ̀ràn láti má ṣe gba èróńgbà wọn láàyè láti fa ìyapa nínú ikọ̀ wọn, pẹ̀lú àfikún pé àpapọ̀ ipò mọ́kànléláàdọ́ta tó ṣí sílẹ̀ nínú ètò ìdìbò gbogbogbò, wà fún èèyàn péréte tó nílò àtìlẹyìn ogunlọ́gọ̀ èèyàn láti gbégbá orókè.

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *