SpyPen (Gègé Alamí)

News as it breaks.

OLÓRÍ ILÉ AṢÒFIN Ọ̀YỌ́ YIN GÓMÌNÀ MÁKINDÉ FÚN ÌDÚRÓ ṢINṢIN

DEBO OYO @50 2

Enimere Àkànbí
Lẹ́yìn tí ilé ẹjọ́ tó ga jù lọ lórílẹ̀èdè Nàìjíríà gbé ìdájọ́ rẹ̀ kalẹ̀ lórí ìṣòro abẹ́nú tó wà láàrin àwọn aṣáájú Ẹgbẹ́ òṣèlú Peoples Democratic, PDP, adarí ilé aṣòfin ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Adébọ̀ Ògúndoyin, ti túbọ̀ fìdí ìjólóòtọ́ rẹ̀ sí Gómìnà Ṣèyí Mákindé, múlẹ̀.

Nínú àtẹ̀jáde, ni Ògúndoyin, ti ṣàpèjúwe àbájáde ilé ẹjọ́ ọ̀hún gẹ́gẹ́ bíi ìkòríta àyípadà tó ṣe ìfìdìmúlẹ̀ ìpinnu Gómìnà Mákindé, ní ọ̀kan lára àwọn àkòókò ìdojúkọ nínú Ẹgbẹ́ òṣèlú PDP.

Ó ṣàlàyé pé àbájáde ilé ẹjọ́ fihàn pé àwọn ìgbésẹ̀ Gómìnà Mákindé, bá ìlànà òfin àti ìlànà òṣèlú dọ́gba, pẹ̀lú ìwòye pé ìdájọ́ ọ̀hún ti fi òpin sí ìjà tó ti fa ìyapa láàrin àwọn aṣáájú Ẹgbẹ́ náà lápapọ̀ lórílẹ̀èdè Nàìjíríà.

Gẹ́gẹ́ bó ṣe sọ, ìpinnu ilé ẹjọ́ ọ̀hún kọjá àfẹnukò òfin nìkan, ṣùgbọ́n ó ṣe àfihàn èrè akitiyan àwọn aṣáájú Ẹgbẹ́ tó mú ìdúró wọn ṣinṣin, láì náání ìdojúkọ tàbí èdè-àìyede àti ìyapa tó ń bẹ nínú Ẹgbẹ́ ọ̀hún.

Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa odì tó ń bẹ láàrin àwọn aṣáájú Ẹgbẹ́ òṣèlú PDP, aṣojúṣòfin náà, sọ pé ìlànà tí tẹ́ etí sí àti ṣíṣe ohun tó jẹ àwọn aráàlú lógún, ló mú Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, dá yàtọ̀ sí àwọn irọ̀ rẹ̀.

IMG 20260406 WA0006 226x300

Bákan ló fi àmúyẹ aṣáájú rere tó ń bẹ lára Gómìnà Mákindé wé ti àwọn akọni bíi Olóògbé Ọbáfẹ́mi Awólọ́wọ̀, olóògbé Samuel Ládòkè Akíntọ́lá àti olóògbé Bọlá Ìgè, pẹ̀lú àfikún pé ọ̀nà tó ń gbà ṣe ìjọba ti mú fi orúkọ rẹ̀ sínú ìwé ìtàn mọnigbàgbé òṣèlú.

Ògúndoyin, sì ṣèlérí pé òun yóò túbọ̀ má a ṣàtìlẹyìn fún ìṣàkóso Gómìnà Mákindé, pẹ̀lú àfikún pé ipa àti àgbékalẹ̀ ìṣèjọ̀ba tí àwọn ará ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ń jẹ ìgbádùn rẹ̀ lákòókò Gómìnà Mákindé, ni wọn yóò ró lágbára síi, láti jẹ́ kí wọ́n pẹ́ kánrinkánṣe.

Adarí ilé aṣòfin ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, ṣàlàyé kíkún nípa ìdí tí ìṣọ̀kan káàkiri ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ fi ṣe pàtàkì, tó sì sọ pé ìṣàkóso Gómìnà Mákindé, ti ṣe ìrólágbára àjọṣe pọ̀ ní tìbútùro ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́.

Bẹ́ẹ̀, wọ́n ti yan Gómìnà Mákindé, gẹ́gẹ́ bíi alága àwọn Gómìnà nínú Ẹgbẹ́ òṣèlú PDP, èyí wáyé lẹ́yìn tí Gómìnà ìpínlẹ̀ Bauchi, Bala Mohammed, fi Ẹgbẹ́ òṣèlú náà sílẹ̀.

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *