Enimere Àkànbí
Gbajúmọ̀ Ajìjàgbara, Aisha Yesufu, ti fi ẹgbẹ́ òṣèlú African Democratic Congress, ADC, sílẹ̀, tó sì darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú Nigeria Democratic Congress, NDC.
Bákan ni ó fi èròngbà láti díje dupò gẹ́gẹ́ bíi aṣòfin tí yóò ṣojú ẹkùn ìdìbò ìlú Abuja ní ilé aṣòfin àgbà, nínú ètò ìdìbò gbogbogbò ọdún ẹgbàá-lé-mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n.
Bẹ́ẹ̀ arábìnrin Ìrètí Kingibe, tó ń ṣojú ẹkùn ìdìbò ìlú Abuja, lọ́wọ́ yìí, dé ipò náà láti inú Ẹgbẹ́ òṣèlú Labour, LP, tí àwọn èèyàn mọ Arábìnrin Yesufu, mọ́.
Ojú òpó ayélujára X, ni Arábìnrin Yesufu, ti jẹ́ kó di mímọ̀, pẹ̀lú àlàyé pé ìpinnu ọ̀hún wáyé lẹ́yìn nǹkan tó ṣàpèjúwe gẹ́gẹ́ bíi ìronú jinlẹ̀ nípa ọjọ́ iwájú oríléèdè Nàìjíríà àti ìtẹ̀sìwájú ìṣedọ́gba pẹ̀lú àfojúsùn òṣèlú, ẹni tó ti fìgbà kan rí jẹ́ olùdíje dupò Ààrẹ oríléèdè yìí, Peter Obi.
Yusufu kọ ọ́ pé “ọjọ́ díẹ̀ sí àkókò yìí ni yóò sọ bí ọjọ́ iwájú oríléèdè yìí yóò ṣe rí, ìronú jinlẹ̀ yìí ló mú mi kọ̀wé fi Ẹgbẹ́ òṣèlú African Democratic Congress (ADC) sílẹ̀ lọ darapọ̀ mọ́ Nigeria Democratic Congress (NDC), gẹ́gẹ́ bí mo ṣe ń tẹ̀lé ìtọ́ni aṣáájú ti Peter Obi, tó jẹ́ pé lónìí yìí, òun ni ìrètí àti ìtanijí oríléèdè Nàìjíríà tó leè ṣe iṣẹ́ ń bẹ lọ́wọ́ rẹ̀”
Ó jẹ́ kó di mímọ̀ pé ìpinnu ìṣáájú láti ṣe àtìlẹyìn fún Obi, ló mú òun darapọ̀ mọ́ ADC, pẹ̀lú àfikún pé ìdarapọ̀ òun mọ́ NDC wà lára ìtẹ̀sìwájú àtìlẹyìn òun fún-un.
Ní àfikún ọ̀rọ̀ rẹ̀ “nígbà ti n bá sọ̀rọ̀, mo má a ń mú u ṣẹ, ìpinnu mi láti ṣe àtìlẹyìn fún Peter Obi, ló mú mi darapọ̀ mọ́ Ẹgbẹ́ òṣèlú ADC. Láti lè má a túbọ̀ mú ìlérí mi ṣẹ, mòó ń darapọ̀ mọ́ NDC”
Sẹ́gun Adélakùn











Leave a Reply