SpyPen (Gègé Alamí)

News as it breaks.

EFCC Ń Wá Alákòóso Nígbà Kan, Sadiya Farouq

images (3)

Enimere Àkànbí
Àjọ tó ń gbógun ti ìwà ibajẹ lẹ́ka ọrọ̀ ajé àti ìnákúnàá owó lórílẹ̀èdè yìí, EFCC, ti kéde pé àwọn ń wá ẹni tó ti fìgbà kan rí jẹ́ alákòóso ọ̀rọ̀ ọmọnìyàn àti ìdàgbàsókè ètò amúlùúdùn lórílẹ̀èdè Nàìjíríà, Arábìnrin Sadiya Umar Farouq, fún ẹ̀sùn àsìlò agbára àti dídarí owó ìlú gba ibòmíràn lọ.

Ojú òpó ayélujára ni Àjọ EFCC ti ṣe ìkéde náà, wọ́n sì rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí ẹnikẹ́ni tó bá ní ìfitónilétí tó leè wúlò láti fi ṣe àwárí tàbí mọ ibi Arábìnrin Farouq, wà, kó fi tó àwọn létí.

Arábìnrin Farouq, ni Ààrẹ àná lórílẹ̀èdè yìí, olóògbé Muhammadu Buhari, yàn lóṣù keje, ọdún ẹgbàá-lé-mọ́kàndínlógún, sípò gẹ́gẹ́ bí alákòóso ọ̀rọ̀ ọmọnìyàn àti ìdàgbàsókè ètò amúlùúdùn lórílẹ̀èdè Nàìjíríà.
Sẹ́gun Adélakùn

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *