Enimere Àkànbí
Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun, Adémọ́lá Adélékè, ti yan Arábìnrin Victoria Samson, tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ mọ̀ sí “BOVAS” sípò gẹ́gẹ́ bíi alámòjútó ilé ẹ̀kọ́ gíga Fáṣítì ti ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun, tó ń bẹ nílùú Òṣogbo.
Ọjọ́ kẹwàá oṣù karùn-ún ọdún ẹgbàá-lé-mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n, ni wọ́n kéde ìyànsípò yìí, èyí tó wáyé lẹ́yìn Ajíhìnrere Fọ́lọ́runṣọ́ Alákijà, tó di ipò ọ̀hún mú láti ọdún ẹgbàá-lé-mẹ́rìndínlógún títí di ọdún ẹgbàá-lé-mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n, parí sáà rẹ̀ nípò náà.
Nínú àtẹ̀jáde tí agbẹnusọ ìjọba ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun, Ọláwálé Rasheed, gbé sí ojú òpó ayélujára, ṣàlàyé pé ìyànsípò náà ṣe àpẹrẹ ìgbà ọ̀tun lẹ́ka adarí ilé ẹ̀kọ́ gíga Fáṣítì ọ̀hún.
Arábìnrin Samson, tó jẹ́ olùdásílẹ̀ iléeṣẹ́ epo BOVAS, ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ gbà pé ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn gbajúmọ̀ obìnrin olókoòwò lẹ́ka epo rọ̀bì.
Gómìnà Adélékè, gbóríyìn fún Ajíhìnrere Fọ́lọ́runṣọ́ Alákijà, tó yẹ̀bá kúrò ní ipò ọ̀hún, pẹ̀lú àfikún pé ó fi ipa mánigbàgbé sílẹ̀ ní ilé ẹ̀kọ́ ọ̀hún láàrin ọdún mẹ́wàá tó fi di ipò náà mù ú.
Gómìnà Adélékè, tọ́ka sí àgbékalẹ̀ ibùdó ìpèsè ìlera gbòógì tí Ajíhìnrere Alákijà, ṣe sínú ilé ẹ̀kọ́ náà, gẹ́gẹ́ bíi ọ̀kan nínú àwọn gudugudu méje àti yàyà mẹ́fà tó ṣe.
Bákan náà ló kan sárá sí Arábìnrin Samson, fún àṣeyọrí gbogbo tó ti ṣe nínú ètò ọrọ̀ ajé, ó sì ṣàpèjúwe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi àwòkọ́ṣe nínú ṣíṣe iṣẹ́ sin ọmọnìyàn àti ìwà ọmọlúwàbí.
Sẹ́gun Adélakùn











Leave a Reply