SpyPen (Gègé Alamí)

News as it breaks.

Mákindé Kò Mú Àdéhùn Ṣẹ, Mùsùlùmí Nipò Gómìnà Kàn – Ọ̀yọ́ Political Equality

images (4)

Enimere Àkànbí
Ìgbìmọ̀ tó ṣe iṣẹ́ tọ ìpín dọ́gba lágbo òṣèlú nípìnlẹ́ Ọ̀yọ́, ti fi ẹ̀sùn kan Gómìnà Ṣèyí Mákindé, pé kò ṣe dédé pẹ̀lú àfẹnukò pé ẹni tó jẹ́ ẹlẹ́sìn Islam, ló gbọ́dọ̀ ṣe àtìlẹyìn fún láti rọ́pò rẹ̀ nígbà tí ìṣàkóso rẹ̀ bá parí ní ọdún ẹgbàá-lé-mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n, tí ètò ìdìbò gbogbogbò yóò wáyé.

Ìgbìmọ̀ ọ̀hún jẹ́ kó di mímọ̀ pé níbi ìpàdé àwọn aṣáájú àti aṣojú ẹ̀sìn, tó wáyé nílùú Ògbómọ̀ṣọ́, ṣáájú ètò ìdìbò tó padà gbé Mákindé wọlé, ní ẹ̀ẹ̀kejì, ni àfẹnukò náà wáyé.

Ìfẹ̀sùn kan ni yìí ló wáyé lákòókò tí ìròyìn ń jà rọ̀hìnrọ̀hìn pé Gómìnà Mákindé, ti yan Bímbọ̀ọ́ Adékánḿbí, gẹ́gẹ́ bíi ààyò rẹ̀ fún ipò Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, fún ọdún mẹ́rin míì.

Nígbà tó ń bá àwọn oníròyìn sọ̀rọ̀ nílùú Ìbàdàn, tí ṣe olú ìlú ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Alákòóso ìgbìmọ̀ ọ̀hún, Alhaji Rafiu Akinwálé, gba Gómìnà Mákindé, níyànjú láti tẹ́lẹ̀ àfẹnukò àwọn, lójúnà láti dènà ọ̀hún tó ṣe àpèjúwe gẹ́gẹ́ bíi rúkèrúdò lágbo òṣèlú àti sísọ ìgbẹ́kẹ̀lé nù nínú ara ẹni láàrin àwọn tí ọ̀rọ̀ kàn.

Akinwálé, fi kún àlàyé rẹ̀ pé àwọn gbajúgbajà aṣáájú ẹ̀sìn, tó fi mọ́ Ààrẹ Mùsùlùmí ní ilẹ̀ Yorùbá àti Alága nígbà kan rí fún Ẹgbẹ́ àwọn ọmọ lẹ́yìn Kírísítì, lórílẹ̀èdè Nàìjíríà, ẹ̀ka ti ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, náà wà níbi ìpàdé ọ̀hún.

Ìgbìmọ̀ náà sọ pé ohun tí àwọn ń bèèrè fún lọ́wọ́ Gómìnà Mákindé, kìí ṣe láti fa ìyapa tàbí mú ẹ̀sìn wọ inú òṣèlú, ṣùgbọ́n ìpín dọ́gba, ìdájọ́ òdodo àti dídúró lójú ipa tí àwọn là kalẹ̀.

Wọ́n fi kún un pé, yíyẹ àfẹnukò ọ̀hún sílẹ̀ leè ṣokùnfà fífi àáké kọ́rí láàrin àwọn tọ́rọ̀ òṣèlú àti ẹ̀sìn kàn nípìnlẹ́ Ọ̀yọ́.

Bẹ́ẹ̀ Bímbọ̀ọ́ Adékánḿbí, tó jẹ́ Alága ìgbìmọ̀ tó ń ṣe àtúnṣe pápákọ̀ òfurufú Ládòkè Akintọ́là, tó ń bẹ nílùú Ìbàdàn, ni ààbọ̀ ìròyìn sọ pé ó jẹ́ ọmọ lẹ́yìn Kírísítì.

 

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *