…..Ó ṢÈLÉRÍ LÁTI MÁ A ṢE OLÓÒTỌ́ TÍTÍ LÁÍ SÍ MÁKINDÉ
Enimere Àkànbí
Adarí ilé aṣòfin ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Adébọ̀ Ògúndoyin, ti sẹ́kanlẹ̀ pé òun kò gba owó kankan lọ́wọ́ àwọn aṣojú Ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress, APC, láti ṣe atọ́nà ìyọnípò Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Ṣèyí Mákindé, ó sì ṣàpèjúwe ọ̀rọ̀ ọ̀hún gẹ́gẹ́ bíi irọ́ àti nǹkan tó ní ọwọ́ òṣèlú nínú.
Nígbà tó ń fèsì sí ẹ̀sùn náà tí wọ́n lọ́ mọ́ ọ lọ́rùn nínú àtẹ̀jáde láti ọwọ́ olùrànlọ́wọ́ rẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ ìròyìn, Ọ̀gbẹ́ni Oyètúnjí Oyèkúnlé, ni Olórí ilé aṣòfin ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Ògúndoyin, ti ṣàfọ̀mọ́ ara rẹ̀ pé òun kò gba owó lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni níbi ìpàdé kankan, pẹ̀lú àfikún pé wọ́n hun ọ̀rọ̀ ọ̀hún ni láti fi ba òun lórúkọ jẹ́ àti láti fi fa èdè àìyedè láàrin ìjọba àti ilé aṣòfin ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́.
Aṣòfin Ògúndoyin, jẹ́ kó di mímọ̀ pé òun kò leè já àwọn ará ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ tó fi ọkàn tán òun kulẹ̀ tàbí yẹpẹrẹ akitiyan ìṣàkóso Gómìnà Mákindé.
Adarí ilé aṣòfin náà túbọ̀ fìdí ọ̀títọ́ inú tí kò yin jẹ tó ní fún Gómìnà Mákindé àti Ẹgbẹ́ òṣèlú tó ń ṣe ìṣàkóso ìjọba ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ lákòókò yí, múlẹ̀, ò si fi kún un pé alàgàta kò leè wá bá àjọṣe pọ̀ tó ń bẹ láàrin òun, ilé aṣòfin àti ìjọba ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, jẹ́.
Ògúndoyin, tẹ̀síwájú pẹ̀lú àlàyé rẹ̀ pé, lábẹ́ ìṣàkóso ọ̀hún, digbí ni ilé aṣòfin náà wà láti ṣe iṣẹ́ríjú rẹ̀, tó ní ṣe pẹ̀lú àgbékalẹ̀ òfin, ìṣèjọ̀ba rere àti ohun tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn aráàlú jùmọ̀ nílò.
Ó jẹ́ kó di mímọ̀ pé ní gbogbo ìgbà ni òun ma ń bun Gómìnà Mákindé gbọ́ nípa àwọn ìgbésẹ̀ tí òun bá fẹ́ gbé, pẹ̀lú àfikún pé àbẹ̀wò tí òun ṣe sí olúbàdàn ilẹ̀ Ìbàdàn, Ọba Rashidi Ládọjà, dá lórí ìbọ̀wọ̀ fún àgbà àti àṣà àti ìgbìyànjú òun láti gba ìmọ̀ràn àti ìwúre lọ́dọ̀ àwọn tọ́rọ̀ kan, lórí èróńgbà òun fún ipò Gómìnà lọ́dún 2027.
Ògúndoyin sì gba àwọn ará ìlú ní ìyànjú láti má ṣe gba ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀hún tó ṣàpèjúwe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi ìgbìyànjú láti dá ìyapa sílẹ̀ láàrin àwọn aṣáájú òṣèlú àti ìṣèjọ̀ba ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́.












Leave a Reply