SpyPen (Gègé Alamí)

News as it breaks.

ỌMỌ ORÍLÉÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ RONÚ KÚ NÍ UK

images (7)

Enimere Àkànbí
Lẹ́yìn-in bíi ọ̀sẹ̀ kan tí àìsàn jẹjẹrẹ mú ẹ̀mí ìyá ọlọ́mọ mẹ́ta tó wá láti oríléèdè Nàìjíríà lọ ní ilẹ̀ gẹ̀ẹ́sì, ni wọ́n tún pàdánù ẹlòmíràn tí òun jẹ́ Bàbá ọlọ́mọ mẹ́ta, tí wọ́n pe orúkọ rẹ̀ ní, Herbert, ẹni tí wọ́n bá òkú rẹ̀ nínú ilégbèé rẹ̀.

Olóògbé ló fi ìyàwó àti àwọn ọmọ kéékèèké mẹ́ta sílẹ̀ sáyé lọ, tí àwọn ẹbí rẹ̀ sì ń rawọ́ ẹ̀bẹ̀ fún ìrànwọ́ owó láti fi ṣe ètò ìsìnkú rẹ̀ àti ọ̀nà bí wọn yóò ṣe gbé òkú ọ̀hún wá sí oríléèdè Nàìjíríà.

Ẹni tí wọ́n mọ̀ sí The Stress Manager, lójú òpó ayélujára X, ló kọ ọ́ pé Herbert, tí ó ń gbé ní Thornaby, ti ojú oorun dé ojú ikú ni, ní ọ̀sẹ̀ tó kọjá, èyí tí àwọn ìbátan rẹ̀ ṣàpèjúwe gẹ́gẹ́ bíi nǹkan tó bá àwọn ní ẹ̀jafùú àti èyí tó ba àwọn lọ́kàn jẹ̀ẹ́.

Gẹ́gẹ́ bí ohun tí Stress Manager, kọ, olóògbé ló ní ìdojúkọ ẹ̀dùn ọkàn àti àìrówóná, láti ìgbà tó ti pàdánù Bàbá rẹ̀ lórílẹ̀èdè Nàìjíríà, ní nǹkan ọjọ́ díẹ̀ kí òun náà tó gbé ẹ̀mí mì.

Òǹlò ojú òpó ayélujára ọ̀hún fi kún un pé, ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti fa ìbàjẹ́ ọkàn fún àwọn mọ̀lẹ́bí olóògbé, pẹlu bó ṣe jẹ́ pé àwọn ọmọ Herbert, ni wọ́n rí òkú bàbá wọn nínú ilé tó sùn bọrọgidi sí.

Ó fi kún un pé ọkọ àti bàbá rere, tí èèyàn fi ń tọrọ ni Herbert, tí èyí tó kéré jù lọ nínú àwọn ọmọ náà, kò ju ọdún mẹ́jọ lọ.

Ó jẹ́ kó di mímọ̀ pé ìpapòdà náà, ti jẹ́ kó di àjàgà fún ẹbí rẹ̀ láti ṣe ìtọ́jú àwọn ọmọ rẹ̀, àti ọ̀nà bí wọn yóò ṣe rí owó tí wọn yóò fi gbé òkú rẹ̀ wá sí oríléèdè Nàìjíríà, láti sin.
Sẹ́gun Adélakùn

 

 

 

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *