SpyPen (Gègé Alamí)

News as it breaks.

Ọ̀rọ̀ Ti Níyanjú Láàrin Gómìnà Mákindé, Olúbàdàn – Ẹgbẹ́ CCII

rasheed ladoja and seyi makinde

Enimere Àkànbí
Àwọn ọmọ bíbí ìlú Ìbàdàn lábẹ́ Àgbáríjọpọ̀ Ẹgbẹ́ àwọn ọmọ ìlú Ìbàdàn, Central Council of Ibadan Indigenes (CCII), ti jẹ́ kó di mímọ̀ pé àwọn ti yanjú èdè-àìyedè tó ṣẹlẹ̀ láàrin Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Ṣèyí Mákindé àti Olúbàdàn ilẹ̀ Ìbàdàn, Ọba Rashidi Ládọjà.

Nínú àtẹ̀jáde tí Ààrẹ àpapọ̀ Ẹgbẹ́ CCII, Amòfin Ajéníyì Ajéwọlé, tí akọ̀wé ìpolongo Ẹgbẹ́, Ọ̀gbẹ́ni Kọ́là Olómidé, sì fi ṣọwọ́ sí àwọn oníròyìn, ni wọ́n ti jẹ́ kó di mímọ̀.

Ṣáájú ni onírúurú àwọn iléeṣẹ́ ìròyìn kọ ọ́ pé gbodónrósọ ń bẹ láàrin Gómìnà Mákindé àti Ọba Ládọjà.

Èyí kò sẹ́yìn ìròyìn tó di tọ́rọ́fọ́n kálé pé Gómìnà ń gbèrò láti rọ Olúbàdàn lóyè, tí Ọba Ládọjà náà sì ń wá ọ̀nà bí yóò ṣe yọ Mákindé kúrò nípò Gómìnà.

Ẹgbẹ́ CCII nínú àtẹ̀jáde ọ̀hún, fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé, ọ̀rọ̀ tó ṣẹlẹ̀ láàrin àwọn aṣáájú méjèèjì ti yanjú, tí ó sì ti rodò lọ momi.

Bákan náà ni wọ́n sọ pé, kò sí ohun tó jọ pé àwọn aṣáájú méjèèjì ń gbèrò láti yọ ara wọn kúrò nípò tí wọ́n dì mú.
Sẹ́gun Adélakùn

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *