SpyPen (Gègé Alamí)

News as it breaks.

FÁYÓṢE YỌJÚ S’OLÚBÀDÀN, Ó TẸNU MỌ́ Ọ PÉ GÓMÌNÀ MÁKINDÉ FẸ́ YỌ ỌBA LÁDỌJÀ

IMG 8110 1200x675 1

Enimere Àkànbí
Gómìnà nígbà kan rí nípìnlẹ́ Èkìtì, Ọ̀gbẹ́ni Ayọ̀délé Fáyóṣe, ti ṣe àgò láàfin sí Olúbàdàn ilẹ̀ Ìbàdàn, Ọba Rashidi Ládọjà, ní ilégbèé rẹ̀ tó ń bẹ ní agbègbè Bódìjà, ní ìlú Ìbàdàn tí ṣe olú ìlú ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́.

Àbẹ̀wò náà ló wáyé lẹ́yìn bíi wákàtí méjìdínláàdọ́ta, tí Ọ̀gbẹ́ni Fáyóṣe, fọ́gbá yángan ọ̀rọ̀ pé, Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Ṣèyí Mákindé, ń gbèrò láti rọ Ọba Ládọjà, nípò Olúbàdàn, èyí tó ti bí onírúurú ìwòye àti àríyànjiyàn láàrin àwọn aráàlú.

IMG 20260406 WA0006 1 226x300

Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lákòókò àbẹ̀wò ọ̀hún, Ọ̀gbẹ́ni Fáyóṣe, ṣàlàyé pé òun wá sí ìlú Ìbàdàn láti kí Olúbàdàn àti láti fi àtìlẹyìn hàn fún ọba aládé náà.

Àbẹ̀wò ọ̀hún jẹ́ ìpele ọ̀tun nínú àríyànjiyàn òṣèlú gbogbo tó ń lọ lọ́wọ́ ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, pàápàá jù lọ àwọn èróńgbà ìyọnípò àwọn aṣáájú ìlú àti lágbo òṣèlú.

Nígbà tó ń bá àwọn oníròyìn sọ̀rọ̀, Ọ̀gbẹ́ni Fáyóṣe, dúró lórí ọ̀rọ̀ tó sọ pé Gómìnà Mákindé, ń gbèrò láti yọ Ọba Ládọjà kúrò nípò.

Ó sì gba Gómìnà níyànjú láti tẹ ilẹ̀ jẹ́ jẹ́, pẹ̀lú àfikún pé ìṣàkóso rẹ̀ kò ní pẹ́ dópin.

 

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *