Emmanuel Akintóyè
Láti bíi ọdún díẹ̀ sẹ́yìn ni òṣèlú àti ìṣèjọ̀ba ti ń wọ inú ara wọn, mo sì fìdí eléyìí múlẹ̀ ní àìpẹ́ yìí, mo ṣe ìwádìí gidigidi nípa orísun ìṣèjọ̀ba rere ní àwọn oríléèdè ilẹ̀ adúláwọ̀ bíi Ghana, Burkina Faso, Ilẹ̀ Olómìnira Benin àti àwọn oríléèdè tó ti làmìlaka ní àgbáyé bíi Ilẹ̀ gẹ̀ẹ́sì, Ilẹ̀ America, Ukraine, Finland, Canada àti àwọn mìíràn, mo sì le è fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn aṣáájú wọn ló ní agbára òṣèlú àti àwọn nǹkan àmúyẹ tó ń sọ wọ́n di òmìnira.
Àwọn nǹkan wọ̀nyí ló sì ń ràn wọ́n lọ́wọ́ láti jẹ́ kí ìdàgbàsókè bá ẹ̀ka ètò ẹ̀kọ́, ìdára ẹni lókòwò, ètò ààbò, owónàá, eré ìdárayá, ẹ̀ka òfin òhun ìdájọ́, Ìmọ̀ ẹ̀rọ, ọrọ̀ ajé àti àwọn nǹkan amáyérọrùn.
Gẹ́gẹ́ bí olùpolongo fún ìròrí ọmọnìyàn, Ọ̀gbẹ́ni Warren Bennis, ṣe tọ́ka síi “Aṣáájú jẹ́ ipá láti le è sọ àfojúsùn di òótọ́”, ojúṣe àwọn aṣáájú ni láti sọ àwọn nǹkan tó ṣe é ṣe di nǹkan tó ènìyàn le è jà fún. Ipò aṣáájú ní àwọn oríléèdè àgbáyé tó ti lajú jù báyìí lọ, jẹ́ ẹ̀ka tó ní agbára. Ó le è yí Àjọ padà, ta àwọn ikọ̀ jí, ó sì leè ṣe atọ́nà àyípadà tó nítumọ̀. Kí èèyàn ní àmúyẹ aṣáájú tó leè ṣe ojúṣe, jẹ́ nǹkan tó ṣe pàtàkì fún aṣáájú tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń kó èrò jọ, ṣe àmójútó ikọ̀ tàbí díje láti ṣe ìṣàkóso ìpínlẹ̀ tàbí oríléèdè.
Aṣáájú rere gbọ́dọ̀ mọ ara rẹ̀ àti nǹkan tó leè ṣe, agbára láti leè ronú jinlẹ̀ lórí nǹkan, ìfaradà àti ìlànà ìbaraẹnisọ̀rọ̀ tó gbó pan, nígbà tí wọ́n bá ń ṣe àfihàn ìwà ọmọlúwàbí, ìkáànú àti ìforítì. Wọ́n ma ń ṣáájú pẹ̀lú àgbọ́yé, ìgboyà, ìgbẹkẹ̀lé tó leè tani jí àti ìfàyègba ìdọ́wọ́ iṣẹ́ pọ̀ ẹ̀ka gbogbo. Láti ara fífi ìfẹ́ hàn sí gbígba ìmọ̀ kún ìmọ̀, dídúró de èsì àti fífi ara wọn hàn gẹ́gẹ́ bíi àwòkọ́ṣe nínú ìṣe àti ìwà, àwọn àmúyẹ aṣáájú yìí leè gbòòrò, kí wọ́n sì ní agbára ni ẹ̀ka tàbí àwùjọ yòówù tí wọ́n bá ba ara wọn. Kí wá ni ohun tí ó ń ṣe wá gan ní oríléèdè Nàìjíríà? A ti máa ń yàrá jù láti mú aṣáájú.
Ní òótọ́ ni pé ìṣèjọ̀ba àwarawa fún ni ní àǹfààní láti yan àwọn aṣojú ní ẹ̀ka òṣèlú àti ìṣàkóso, bí oríléèdè yìí ṣe ń ìgbáradì fún àkókò míì láti yan àwọn tí yóò má a ṣe ìṣàkóso rẹ̀, ń jẹ́ ó yẹ kí a tún ṣe àṣìṣe míì, ní ọdún ẹgbàá-lé-mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n, pàápàá jù lọ ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́? Rárá. Ẹ jẹ́ kí á yan Amòjú-ẹ̀rọ PÓPÓỌLÁ OLÚKÁYỌ̀DÉ JOSHUA, tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ mọ̀ sí POJ.
Nítorí ìdí èyí máà ṣàlàyé kíkún nípa àwọn àmúyẹ aṣáájú rere tó ń bẹ lára rẹ̀, tó dàpè ní “V.I.A.E.C.A” èyí tó túmọ̀ sí Vision: Àfojúsùn, Integrity: Ìwà Ọmọlúwàbí, Actions: Ìgbésẹ̀ akin, Empathy: Ìkáanú, Communication: ìbaraẹnisọ̀rọ̀ àti Accountability: Àkọ̀ya
POJ jẹ́ ọkùnrin tó ní àfojúsùn, fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún ló ti ń sọ fún àwọn alábáṣepọ̀ àti mọ̀lẹ́bí rẹ̀ nípa àlá rere tó ní fún ìgbéga àti ìdàgbàsókè ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́. Èyí ló mú kí ó díje fún ipò Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ní ọdún ẹgbàá-lé-mẹ́tàlélógún, nínú Ẹgbẹ́ òṣèlú New Nigeria People’s Party, NNPP, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn tí wọn kò ní àgbọ́yé èrò ọkàn àti àlá rẹ̀, dìbò fún olùdíje láti inú Ẹgbẹ́ òṣèlú míì. Síbẹ̀ kò jẹ́ kí eléyìí bu omi pa ìfẹ́, ìtara àti àfojúsùn rẹ̀, ó sì darapọ̀ mọ́ Ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressive Congress, APC, lójúnà láti jẹ́ kí èróńgbà àti àlá rẹ̀ fún àwọn ará ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ wá sí ìmúṣẹ. Ó tún ti dé padà láti díje du ipò Gómìnà, àwọn aṣáájú, àṣọmọhbè àti ará ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ lápapọ̀, gbọ́dọ̀ tẹ́wọ́ gbàá, fún ìmúṣẹ àfojúsùn rẹ̀.

POJ jẹ́ ọmọlúwàbí, à ń sọ nípa akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ a ojú ẹ̀rọ àti olóṣèlú tí wọ́n ń wárí fún. Kí ló fà á, ó ń fi ìwà ọmọlúwàbí hàn láti ara bí ó ṣe ń dáàbò bo orúkọ àti ọjọ́ ọ̀la rẹ̀. Ọ̀pọ̀ ìgbà ló ti takété fún àwọn nǹkan tó leè fa àbààwọ́n. Kò ní àkọsílẹ̀ pé ó jẹ ilé ìfowópamọ́ kankan ní gbèsè, yálà ìwà àjẹbánu tàbí àṣìlò agbára, kankan. Àṣeyọrí aláìlẹ́gbẹ́ ni. Àwọn nǹkan wọ̀nyí ni ó sì fẹ́ gbé kalẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́. Ìlànà àti ètò rẹ̀ yóò mú àyípadà ọ̀tun bá àwọn nǹkan tí kò tọ́, tí wọn yóò sì padà já sí èrè tabua lẹ́ka ìdókòwò àti amáyérọrùn wá.
POJ má ń gbé ìgbésẹ̀ akin, kìí fi àkókò ṣòfò lórí ìpinnu, tó sì ṣe tán láti túbọ̀ gbé àwọn ìgbésẹ̀ akin, tí ó bá rí àwọn èròjà àti irinṣẹ́, ó ti fi eléyìí hàn ní àwọn iléeṣẹ́ aládàáni, tí àwo èèbó kò sì fọ̀ mọ́ ọ lọ́wọ́ títí di àkókò yìí, èyí náà sì ni ara nǹkan tó ṣèlérí láti ṣe fún àwọn ará ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, bí wọ́n bá le fi ìbò yàn-án. Àìsúnmọ́ni, ni kò jẹ́ kí a mọ ìṣe ẹni. POJ ti ṣe tán láti sin ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Ẹ gbìyànjú rẹ̀ wò, Ẹ ó sì ríi pé àyípadà rere yóò bá ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ láti ara àwọn ìgbésẹ̀ akin tí yóò má a gbé.
POJ jẹ́ olùkáànú, ó yá a lára láti fi ara da ìdojúkọ fún ìrọ̀rùn ẹlòmíràn, kódà ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn tó rọ̀gbọ̀ yí i ká ni ó ma ń wù ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà pé kò jẹ́ pé àwọn ni elédùmarè fún ní àwọn nǹkan àmúyẹ tó ń bẹ lára POJ, ṣùgbọ́n kò rọrùn fún wọn láti ṣe é. Nítorí pé ẹyẹ tó bá dorí kodò bí àdàn, yóò pọ ẹ̀jẹ̀ lẹ́nu. Ojúlówó ọmọ ìlú Ìbàdàn ni. Ó ní ìfẹ́ àwọn èèyàn tó ń bẹ ní àyíká rẹ̀. Ó jẹ́ olóṣèlú tó bẹ̀rẹ̀ láti ẹṣẹ̀kùkú. Ó ma ń lọ sí ibi tí àwọn èèyàn bá ń lọ, ó ní ojú àánú púpọ̀. Irú ọkùnrin yìí gan-an ni ó yẹ ní ẹni tí ó yẹ kí ó bọ́ sípò ìṣàkóso ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ní ọdún ẹgbàá-lé-mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n, fún àyípadà rere aláìlẹ́gbẹ́. Owó oṣù, àjẹmọ́nú, ìgbéga àwọn òṣìṣẹ́ àti àwọn òṣìṣẹ́fẹ̀yìntì yóò má a tẹ̀ wọ́n lọ́wọ́ ní àkókò tó yẹ, ìpèsè àwọn nǹkan amáyérọrùn níbi gbogbo, ìpèsè ètò ìrólágbára fún àwọn ọ̀dọ́, ìpèsè ètò ààbò tó péye, àyíká tí yóò mú ìdókòwò rọrùn, ni àwọn èróńgbà gbòógì tó ní fún àwọn aráàlú. Ó jẹ́ ẹni tí má a mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ, olóṣèlú yánhànhàn, olóṣèlú tó ní ìbẹ̀rù Ọlọ́run, kò leè ní lára láti tẹ́ àwọn ọmọ bíbí ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ lọ́rùn. Ẹ jẹ́ kí á gbà á láàyè láti wá darí wa. Yóò mú ìdẹ̀rùn bá àwọn aráàlú lórí àwọn ìnira tí kò yẹ tí wọ́n ń kojú àti ọrọ̀ ajé tó ń fi ìdí wọ́.

POJ nífẹ̀ẹ́ ìbaraẹnisọ̀rọ̀, yóò sọ òtítọ́ fún yín, kò ní sọ pé òun wà nílùú Abuja, nígbà tó wà nínú ilé rẹ̀, yóò sọ̀rọ̀, yóò sì má a retí èsì, kó tó di pé yóò bẹ̀rẹ̀ ìgbésẹ̀, yóò ṣe àwọn ètò tí àwọn aráàlú yóò fi fi èrò wọn hàn àti ìpàdé oníròyìn. Kò sí ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn, kò ní sí ìfọwọ́ bo ohunkóhun. Òun gan-an ló yẹ nípò ìṣàkóso ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́.
POJ yóò fi ààyè gba àkóyawọ́, èyí gan-an ni ṣóńṣó ìṣèjọ̀ba àwarawa, yóò fi ààyè sílẹ̀ fún ìbú-ẹnu àtẹ́ lù nígbà tí ìlànà bá kù díẹ̀ káàtó, kò ní sọ pé kí àwọn aráàlú pa ẹnu mọ́ lórí nǹkan tí kò tọ́, Ẹ ó rí ní àwùjọ tí yóò má a bá àwọn aráàlú tàkùrọ̀sọ, kódà nígbà tí àwọn ẹ̀sọ́ aláàbò bá ń tẹ̀síwájú láti dáàbò bòó, kò ní jókòó lé àwọn alákòóso ìjọba ìbílẹ̀ lọ́rùn mọ́lẹ̀, yóò gba àwọn aṣáájú ní ẹṣẹ̀kùkú láti ṣe ohun tí àwọn aráàlú ń fẹ́ fún wọn, àwọn ibi tí kùdìẹ̀kudiẹ bá wà, àwọn aráàlú yóò ní àǹfààní láti so wọ́n létí aṣọ mú. Mo ní ìgbàgbọ́ pé pẹ̀lú ìwúre, ìfẹ́ àti ìfọnrere fún POJ gẹ́gẹ́ bíi ẹni tí a fẹ́ ní ipò Gómìnà ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, láti inú Ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress, APC. Ó jẹ́ agbáṣàga, ó sì tún jẹ́ Mọ́gàjí agbo ilé wọn ní ìlú Ìbàdàn.
Ní àkótán, aṣáájú tó ń ṣe ojúṣe rẹ̀, tó sì nítumọ̀, kìí ṣe ìparí ìrìn-àjò, ó jẹ́ ìrìn-àjò tó ń tẹ̀síwájú nínú ìmọ̀, ìdàgbàsókè àti ìdàgbàsókè ara ẹni. Àwọn aṣáájú tó lókìkí ní ìgbẹ́kẹ̀lé, ìtanijí ìgbésẹ̀ akin àti bá ìdojúkọ dọ́gba, láti ara fífi èrò tó yẹ, ìṣe àti ìhùwàsí tó bójú mu hàn. Bí ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ṣe nílò Amòjú-ẹ̀rọ PÓPÓỌLÁ OLÚKÁYỌ̀DÉ JOSHUA, tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ mọ̀ sí POJ, bẹ́ẹ̀ ni òun náà nílò wa.









Leave a Reply