SpyPen (Gègé Alamí)

News as it breaks.

ẸGBẸ SSANU SỌ Ọ̀NÀ ÀBÁYỌ FÚN ÌJỌBA ÀPAPỌ̀

ssanu 1 860x484

Enimere Àkànbí
Ìgbìmọ̀ Aláṣẹ àpapọ̀ Ẹgbẹ́ àwọn lọ́gàlọ́gàá òṣìṣẹ́ láwọn ilé ẹ̀kọ́ gíga Fáṣítì lórílẹ̀èdè Nàìjíríà, SSANU, ti laago ìkìlọ̀ fún ìjọba àpapọ̀, lórí ìjíròrò owóoṣù tí àwọn Ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ láwọn ilé ẹ̀kọ́ gíga Fáṣítì àti àwọn aṣojú ìjọba àpapọ̀ ń padà ṣe, wọ́n sì jẹ́ kó di mímọ̀ pé àfẹnukò kankan kò tíì wáyé àti wí pé àwọn yóò gùn lé ìyanṣẹ́lódì bí wọn kò bá fi ẹnu ọ̀rọ̀ jóná kó tó di ìparí oṣù kẹrin.

Ọ̀rọ̀ yìí ló jẹ yọ nínú àfẹnukò àkànṣe ìpàdé tí àwọn ìgbìmọ̀ ọ̀hún ṣe ní ilé ìyá Ẹgbẹ́ náà, tó ń bẹ nílùú Abuja, níbẹ̀ sì ni àwọn aṣáájú Ẹgbẹ́ ti ṣe àgbéyẹ̀wò ipò tí ìjíròrò ọ̀hún dé dúró.

Àfẹnukò ìpàdé náà tí Ààrẹ àpapọ̀ Ẹgbẹ́ SSANU, Muhammad Ibrahim, bu ọwọ́ lù, ni ìgbìmọ̀ aláṣẹ ọ̀hún ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé àwọn kò tíì fi ẹnu ọ̀rọ̀ jóná lórí i ìjíròrò owóosù tí àwọn ń ṣe pẹ̀lú àwọn aṣojú ìjọba àpapọ̀.

Ìgbìmọ̀ SSANU tún kọminú nípa nǹkan tí wọ́n ṣàpèjúwe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi ìròyìn asinilọ́nà tí wọ́n ń gbé kiri pé àfẹnukò ti wà lórí ìjíròrò owóosù.

Wọ́n jẹ́ kó di mímọ̀ pé ìwé kan ti wọ́n ń pín kiri ni wọ́n kọ ọ́ sí inú rẹ̀ pé àwọn ti fi ẹnu kò pé kí àlékún ìdá ọgbọ́n bá owó àjẹmọ́nú àwọn, ṣùgbọ́n ìgbìmọ̀ náà ṣe àfọ̀mọ́ rẹ̀ pé, irọ́ lásán ni, àwọn kò ti ọwọ́ bọ ìwé kankan.

Ìgbìmọ̀ aláṣẹ àpapọ̀ Ẹgbẹ́ SSANU sọ pé “àwọn kò ní gba ohunkóhun tó bá yàtọ̀ sí ohun tí àwọn ń bèèrè fún nínú ìjíròrò pẹ̀lú ìjọba àpapọ̀, pẹ̀lú àfikún wọ́n gbọ́dọ̀ bọ̀wọ̀ fún ìgbésẹ̀ àti ìlànà òdodo nínú ìdíyelé tí ó bá ń ṣẹlẹ̀ láàrin igun méjèèjì”

Nígbà tí wọn ń tẹpẹlẹ mọ́ nǹkan tí wọ́n ń bèèrè fún lábẹ́ àgbàríjọpọ̀ ìgbìmọ̀ tó ń gbé ìgbésẹ̀ akin lórí ẹ̀tọ́ Ẹgbẹ́ SSANU àti Ẹgbẹ́ àwọn òṣìṣẹ́ tí kìí ṣe olùkọ́ láwọn ilé ẹ̀kọ́ gíga Fáṣítì lórílẹ̀èdè Nàìjíríà, NASU, wọ́n sọ pé àǹfààní tí àwọn fún ìjọba àpapọ̀, bẹ̀rẹ̀ láti ọjọ́ kìnní títí di ọgbọ̀njọ́ oṣù kẹrin, láti fi ẹnu kò, kí wọ́n sì ti ọwọ́ bọ̀wé àdéhùn, kò yí padà.

Wọ́n sì ṣe ìkìlọ̀ pé, ìkùnà láti ṣe nǹkan tí àwọn bèèrè fún láàrin àkókò ọ̀hún yóò mú àwọn kọ iṣẹ́ sílẹ̀.
Sẹ́gun Adélakùn

 

 

 

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *