Enimere Àkànbí
Olúbàdàn ilẹ̀ Ìbàdàn, Ọba Rashidi Ládọjà àti Arábìnrin Florence, tó jẹ́ opó Gómìnà àná nípìnlẹ́ Ọ̀yọ́, Abíọ́lá Ajímọ̀bi, ti se àfọ̀mọ́ ara wọn lórí èróńgbà ìyọnípò Gómìnà Ṣèyí Mákindé, tí àwọn ọmọ ilé aṣòfin ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, fẹ́ fi kọ́ wọn lọ́rùn.
Adarí ilé aṣòfin ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Adébò Ògúndoyin, ló kọ́kọ́ jáde tako ìròyìn tó ní ṣe pẹ̀lú èróńgbà yìí, lẹ́yìn náà ni àwọn ọmọ ilé aṣòfin ọ̀hún, bẹ̀rẹ̀ sí ní fi àtẹ̀jáde síta láti fi wẹ ara wọn mọ́ lórí ìpàdé tó wáyé láàrin Adarí ilé àti Olúbàdàn òhun ìyàwó Ajímọ̀bi.
Nínú àtẹ̀jáde tí Akójàánu ilé aṣòfin ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Gbénga Oyèkọ́lá, fi síta, ló ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé Olúbàdàn àti Arábìnrin Ajímọ̀bi, pe Ògúndoyin.
Ó sì jẹ́ kó di mímọ̀ pé Olúbàdàn gba Adarí ilé ní ìmọ̀ràn pé kó fi èróńgbà láti di ọmọ ilé aṣojúṣòfin ìjọba àpapọ̀ rọ́ pò èróńgbà láti di Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ lọ́dún 2027, tó sì fi lọ́kàn balẹ̀ pé wọn yóò fún ní àǹfààní náà nínú Ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress, APC, pẹ̀lú owó tó tówó láti fi mú àfojúsùn rẹ̀ ṣẹ.
Àbọ̀ ìròyìn sọ pé Ògúndoyin, kọ àwọn nǹkan tí wọ́n fi lọ̀ọ́, bákan náà ni ìròyìn sọ pé Arábìnrin Ajímọ̀bi, náà pe Adarí ilé fún ọ̀rọ̀ yìí kan náà.
Bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn ọmọ ilé aṣòfin ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ yòókù tó sọ̀rọ̀, pọ̀n sẹ́yìn Oyèkọ́lá, tí wọ́n sì túbọ̀ fìdí àtìlẹyìn àti ìjólóòtọ́ wọn fún Gómìnà Mákindé, múlẹ̀, tí wọ́n sì yọ ara wọn lágá kúrò nínú èróńgbà ìyọnípò Gómìnà Mákindé.
Nígbà tí Olúbàdàn ń fèsì láti ẹnu olùrànlọ́wọ́ rẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ ìròyìn, Ọ̀gbẹ́ni Adéọlá Ọlọ́kọ̀, ṣe ìkìlọ̀ pé kí ẹnikẹ́ni má ṣe fi ẹrẹ̀ àti ìdọ̀tí òṣèlú yí aṣọ iyì òun.

Nínú ọ̀rọ̀ ti ẹ̀, Abilékọ Ajímọ̀bi, kéde pé òun kò lọ́wọ́ nínú ìgbésẹ̀ gbígbé owó kalẹ̀ fún àwọn ọmọ ilé aṣòfin ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, láti fi ṣe atọ́nà ìyọnípò Gómìnà Mákindé.
Abilékọ Ajímọ̀bi, tí ẹ̀ka ìròyìn rẹ̀ gba ẹnu sọ fún, ṣàpèjúwe ọ̀rọ̀ ọ̀hún gẹ́gẹ́ bíi irọ́ pátápátá, nǹkan tí kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ àti ìtànjẹ láti fi ba orúkọ òun jẹ́ àti láti fi ṣi àwọn aráàlú lọ́nà.
Ṣùgbọ́n ṣá, Ṣọlá tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọmọ bíbí lọ́kùnrin Ọba Ládọjà, sọ pé òun yóò gbé ẹ̀rí ìpàdé ọ̀hún síta bí Adarí ilé aṣòfin ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ bá kùnà láti ṣe nǹkan tó yẹ.
Gẹ́gẹ́ bí Ṣọlá ṣe kọ́ ní èdè gẹ̀ẹ́sì sójú òpó ayélujára X “Èmi ni mo mú Débọ̀ Ògúndoyin lọ sí ọ̀dọ̀ Kábíyèsí (Baba mi) nítorí pé ó bẹ̀ mí. Ọ̀rẹ́ wa Akójàánu ilé, ó ti fi ara rẹ̀ sílẹ̀ fún ojo àti òpùrọ́ láti lò ọ́, mà á fi ẹ̀rí (Receipt) síta, bí Débọ̀ kò bá ṣe nǹkan tó yẹ. Gbogbo rẹ̀ nítorí ìmọ̀ tara ẹni nìkan rẹ̀ láti di Gómìnà.
Bẹ́ẹ̀ nínú ọ̀rọ̀ míì tó kọ sójú òpó ayélujára, ló ti ṣàlàyé pé òun pinnu láti pa ohun tí òun kọ́kọ́ kọ rẹ́, nítorí pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ lérò pé òun ń sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀rí owó, pẹ̀lú àfikún pé ohun tí òun sọ ni ẹ̀rí Àjọ́sọ ọ̀rọ̀ ìpàdé Ògúndoyin àti Olúbàdàn.
Ẹ̀wẹ̀, díẹ̀ lára àwọn ọmọ ilé aṣòfin ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ sọ fún iléeṣẹ́ ìwé ìròyìn The PUNCH, pé ìjọba àpapọ̀ ló ń bẹ lẹ́yìn èróńgbà láti yọ Mákindé nípò Gómìnà, nítorí pé ó ń tako Ààrẹ Bọ́la Tinúbú.
Wọ́n wí àwíjàre pé ìgbìyànjú ìjọba àpapọ̀ ni láti sọ Mákindé sínú ìdààmú, ṣáájú ètò ìdìbò gbogbogbò ọdún 2027.








Leave a Reply