……Àlàní Pamilẹ́kún Haaland, Cherki, Ló Pa Wọ́n Lẹ́kún
Enimere Àkànbí
Òjò pa eégún, òde kò dáa fún Ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Arsenal àti àwọn olólùfẹ́ wọn, pẹ̀lú bí wọ́n ṣe fìdí rẹmi sí ọwọ́ Manchester City.
Àmì ayò méjì sí ẹyọ̀kan ní ìfigagbága ọ̀hún tó wáyé ní pápáṣeré ìdárayá Etihad, tó jẹ́ ti Manchester City, parí sí.
Ryan Charki, ló kọ́kọ́ gbá bọ́ọ̀lù sí àwọ̀n Arsenal ní ìṣẹ́jú mẹ́rìndínlógún tí ìfigagbága náà bẹ̀rẹ̀.
Cherki, da àwọn agbábọ́ọ̀lù Arsenal ríbarìbo kó tó gbá bọ́ọ̀lù ọ̀hún wọ inú àwọ̀n alátakò, ṣùgbọ́n ìdùnnú Manchester City, kò pẹ́ títí, ìṣẹ́jú méjì sí ìgbà náà, ni Arsenal, rí àwọ̀n e.
Aṣọ́lé Manchester City, G. Donnaroma, ni ó gbá bọ́ọ̀lù mọ́ Kai Havertz, agbọ́wọ́ iwájú Arsenal, tó pakuru mọ́ ọ, lára.
Èyí ni wọ́n gbá lọ bẹ́ẹ̀ ní abala àkọ́kọ́, ní abala kejì, oníkálukú tún padà sí orí i pápá láti tẹ̀síwájú nínù ìgbìyànjú.
Bó ti lẹ̀ jẹ́ pé ọwọ́ City dun Gunners nínú dìdani ríbarìbo àti àǹfààní, síbẹ̀ kò sí ẹni tó ṣe àmúlò àwọn àǹfààní gbogbo tó fi ojú hàn, títí tó fi di ìṣẹ́jú márùndínlọ́gọ́rin.
Erling Haaland, ni ó fi ìdùnnú sí ẹ̀ẹ̀kẹ́ àwọn olólùfẹ́ Manchester City, tó jẹ́ olùgbàlejò, nípa ṣíṣe àmúlò àǹfààní tó bọ́ síi ní ẹsẹ̀.
Arsenal, gbìyànjú láti jẹ́ kí ìfigagbága ọ̀hún parí sí ọ̀mì ayò ṣùgbọ́n, gbogbo ìgbìyànjú wọn fi orí ṣánpọ́n.
Ní báyìí àmì mẹ́ta ni Arsenal tó ń bẹ ní ipò àkọ́kọ́ fi ń la Manchester City, tó wà ní ipò kejì, pẹ̀lú àjẹsílẹ̀ ìfigagbága kan, tí wọn yóò gbá kojú u Burnley.
Ọjọ́rú ọ̀sẹ̀ yìí ni ìfigagbága náà yóò wáyé ní ilé Burnley.
Wọ̀n yìí ni àlàkalẹ̀ ìfigagbága tí Manchester City àti Arsenal ní láti gbá ní bí sáà yìí ṣe ń parí lọ.
Man Cityyóò kọjú u
Burnley (A) – Wed, April 22 Everton (A) – Mon, May 4 Brentford (H) – Sat, May 9
Bournemouth (A) – Sun, May 17
Crystal Palace (H) – TBC
Aston Villa (H) – Sun, May 24
Arsenal yóòkojú
Newcastle (H) – Sat, April 25
Fulham (H) – Sat, May 2
West Ham (A) – Sun, May 10
Burnley (H) – Sun, May 17
Crystal Palace (A) – Sun, May 24












Leave a Reply