SpyPen (Gègé Alamí)

News as it breaks.

Real Sociedad, Ya Karanjángbọ́n, Ó Fi Ìyà Rán Àwọn Agbábọ́ọ́lù Barcelona Lọ Sí Ilẹ̀ Baba Oníkálukú Wọn

Images 13

Enimere Àkànbí
Ìbànújẹ́ ọkàn ni àwọn agbábọ́ọ́lù Barcelona yóò fi tàtapínsẹ̀ lọ sí orílèdè oníkálukú wọn, nítorí bí ẹgbẹ́ agbábọ́ọ́lù Real Sociedad, ṣe fi àmì ayò kan, kàn wọ́n lábùkù nínú líìgí orílèdè Spain.

Ṣáájú ìfigagbága náà, tó jẹ́ èyí tí àwọn agbábọ́ọ́lù ń gbá kó tó di pé wọ́n yóò jẹ́ ìpè ilẹ̀ baba wọn, ni ẹgbẹ́ agbábọ́ọ́lù kankan kò rí Barcelona fi ìyà jẹ nínú ìfigagbága méje tí wọ́n gbá sẹ́yìn nínú gbogbo ìdíje tí wọ́n ti ń kópa.

Wọ́n gbìyànjú láti fi Real Sociedad náà pata, ṣùgbọ́n ẹ̀rọ ayàwòrán ìdọdẹ tó ń ran àwọn adarí ayò lọ́wọ́, VAR, wọ́ igi lé bọ́ọ́lù tí Robert Lewandowski, gbá wọn inú àwọ̀n.

Ní ẹ̀yìn ìgbà náà ni Sheraldo Becker, fún Real Sociedad, ní ìjáwé olúborí, pẹ̀lú ú bọ́ọ́lù tó gbá wọ ilé Barcelona.

Ìjákulẹ̀ Barcelona ló fi òpin sí ìjẹgàba àti ìjáwé olúborí tí wọ́n ní, ní pápáṣerédárayá Estadio Anoeta, ní ẹ̀ẹ̀mẹrin ọ̀tọ̀tọ̀ sẹ́yìn tí wọ́n ti lọ kọjú Real Sociedad, níbẹ̀.

Bákan náà ló fún Real Madrid, tó ní àjẹsílẹ̀ ìfigagbága, tó sì wà ní ipò kejì lórí ìgbéléwọ̀n líìgí, ní àǹfààní láti sún mọ́ Barcelona.

 

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *