SpyPen (Gègé Alamí)

News as it breaks.

Òjò Peégún, Òde Ò Dáa, Bẹ́kùnbẹ́kùn El-Kanemi Warriors, Pàdé Ẹni Tí Yóò Lúùpa, 3SC Fi Àmì Ayò Mẹ́ta, Kun-ún Bíi Ẹran Gífà Ní Ìlú Ìbàdàn

Images 12

Enimere Àkànbí
Ayé ò lọ bí ọ̀pá ìbọn, ìgbà ò lọ bí òréré, ló dífá fún bí ẹgbẹ́ agbábọ́ọ́lù El-Kanemi Warriors ṣe pàdánù fún ìgbà àkọ́kọ́ ní sáà yìí.

El-Kanemi Warriors tó mú ìfigagbága mẹ́wàá tó ti gbá sẹ́yìn, jẹ, rin àrìnfẹsẹ̀sí lọ sí ìlú Ìbàdàn, nígbà tí wọ́n lọ rèé ṣí ogun bá Shooting Stars Sports Club, 3SC, nínú ìfigagbága ọ̀sẹ̀ kọkànlá líìgí orílèdè Nàìjíríà.

Ẹgbẹ́ agbábọ́ọ́lù ọ̀hún ni kò rí òògùn rẹ̀ ṣe ní pápáṣerédárayá Lékan Salami, Shooting Stars, tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ tún mọ̀ sí Olúyọ̀lé Soccer Warlords, bá ẹgbẹ́ agbábọ́ọ́lù náà wìí bí ìkókó, pẹ̀lú àmì ayò mẹ́ta, láìle ta pútú.

Nígbà tí ẹgbẹ́ agbábọ́ọ́lù méjèèjì ń fi ìjà pẹ́ẹ́ta, Samuel Àyànríndè àti Aliyu Abubakar, ló kọ́kọ́ fi ń kan ṣe El-Kanemi Warriors, ní abala àkọ́kọ́, kí Adams Mustapha, tí akọ́nimọ̀ọ́gbá 3SC, Gbénga Ògúnbọ̀tẹ̀, gbé wọlé, tó fi ọba lé e ní abala kejì.

Ìpàdánù yìí, mú El-Kanemi Warriors, bá ara rẹ̀ ní ipò keje, nígbà tí 3SC sún sí ipò kẹsàn-án, ní orí i ìgbéléwọ̀n líìgí.

Ẹ má gbàgbé pé El-Kanemi Warriors, tí Aliyu Zubairu, jẹ́ akọ́nimọ̀ọ́gbá fún, ló ṣẹ̀ṣẹ̀ gba ìgbéga wá sí inú àkàbà àkọ́kọ́ líìgí orílèdè Nàìjíríà ní sáà yìí, tí àwọn ẹgbẹ́ agbábọ́ọ́lù bíi Enyimba ti ìlú Aba, Rivers United, àti Enugu Rangers, kò sì rí ẹ̀yìn rẹ̀ mú balẹ̀.

Lẹ́yìn ìfigagbága ọ̀sẹ̀ kọkànlá, ẹgbẹ́ agbábọ́ọ́lù Remo Stars, tó ta ọ̀mì ayò òdo sí òdo, ní ilé Enyimba, sún sí ipò àkọ́kọ́, nígbà tí Rivers United, tó pàdánù fún ìgbà àkọ́kọ́ ní ọ̀sẹ̀ kẹwàá líìgí, gba àlejò tí apá rẹ kò ká ní ọ̀sẹ̀ kọkànlá, Bayelsa United, ló fi àmì ayò kan dondo, kàn-án ní àbùkù.

Ẹgbẹ́ agbábọ́ọ́lù Ìkòròdú City tó já ìbálé Rivers United ní ọ̀sẹ̀ tó kọjá, tún rí àmì mẹ́ta mú bọ̀ ní ilé Katsina United, tó gbáà ní àlejò, ó fi ìyà jẹ́ pẹ̀lú àmì ayò méjì sí ẹyọ̀kan.

Nígbà tí Emmanuel Amuneke kó Heartland lẹ́yìn lọ gba iṣẹ́ lọ́wọ́ Kennedy Boboye, ti inú ẹgbẹ́ agbábọ́ọ́lù Sunshine Stars, àmì ayò kan sí òdò ni wọ́n fi bá wọn wí.

Plateau ta ọ̀mì pẹ̀lúu Enugu Rangers, Nasarawa United, ṣubú yakata níwájú Kwara United, tó fi àmì ayò kan rée ní ẹ̀fásẹ̀, Niger Tornadoes, sán pa Akwa United, ní èèkan péré.

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *