SpyPen (Gègé Alamí)

News as it breaks.

Ìkòròdú Já Ìbálé Rivers United, 3SC Kan Àgbákò Ìyà Ní Ilé Niger Tornadoes

20241103 191634 1 1392x1112 1

Enimere Àkànbí
Ẹgbẹ́ agbábọ́ọ́lù Ìkòròdú, ti ṣe ohun tí àwọn alátakò kankan kò rí ṣe ní sáà 2024/2025 líìgí orílèdè Nàìjíríà, pẹ̀lú bí wọ́n ṣe ba málù tí ẹgbẹ́ agbábọ́ọ́lù Rivers United, so mọ́ ara, jẹ́.

Nínú ìfigagbága ọ̀sẹ̀ kẹwàá líìgí orílèdè Nàìjíríà ni ẹgbẹ́ agbábọ́ọ́lù méjèèjì ti kọjú ara wọn, tí Ìkòròdú FC sì fi ojú Rivers United tí George Finidi, ń kó sódì gbó ilẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Èkó, pẹ̀lú àmì ayò méjì sí òdo.

Bó ti lẹ̀ jẹ́ pé, ọ̀mì ayò ni abala àkọ́kọ́ ìfigagbága alágbára náà parí sí ní ààrin ẹgbẹ́ agbábọ́ọ́lù méjèèjì, ìṣẹ́jú mẹ́jọ ní ẹ̀yìn tí wọ́n wọlé padà sí orí pápá fún abala kejì, ní Ayọ̀mídé Cole, mi àwọ̀n àkọ́kọ́ fún Ìkòròdú FC.

Ìṣẹ́jú mẹtalèláàdọ́ta ni Rivio Ayemwenre, fi ìkejì lé e fún Ìkòròdú FC, láti ṣe àṣeparí iṣẹ́ náà.

20241103 191705 696x617 1 300x266

Ní báyìí, ẹgbẹ́ agbábọ́ọ́lù El-Kanemi Warriors, tí òun àti Ìkòròdú FC jọ gba ìgbéga wá láti àkàbà kejì, nìkan ni ẹgbẹ́ agbábọ́ọ́lù tí kò tíì bá ìyà pàdé nínú líìgí orílèdè Nàìjíríà, sáà yìí.

Nínú àwọn èsì ìfigagbága ọ̀sẹ̀ kẹwàá yòókù, ẹgbẹ́ agbábọ́ọ́lù El-Kanemi Warriors, fi àgbà han alátakò rẹ̀ Katsina United, pẹ̀lú àmì ayò kan sí òdo,

Ọ̀mì ayò kọ̀ọ̀kan ló wáyé ní ààrin Bayelsa United àti ẹgbẹ́ agbábọ́ọ́lù Enyimba.

Akwa United fi ẹ̀yìn Kwara United janlẹ̀ pẹ̀lú àmì ayò méjì sí ẹyọ̀ kan, bákan náà ni ọ̀rọ̀ rí nígbà tí Kano Pillars bá Plateau United wìí.

Rẹ́mọ Stars rẹ Lobi Stars nilẹ̀ láìka Daniel Amokachi àti ọmọ orílèdè Finland, tó ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣe iṣẹ́ pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀ kún.

Enugu Rangers fi àmì ayò méjì bá Nasarawa United wí, tí òhun náà kò sì leè ta pútú.

Nígbà tí Shooting Stars Sports Club 3SC ilẹ̀ Ìbàdàn bá ìyà pàdé lọ́dọ̀ Niger Tornadoes, àmì ayò méjì sódo ni.

Ẹ̀wẹ̀ ẹgbẹ́ agbábọ́ọ́lù méjì ọ̀tọ̀tọ̀ ló jáde lọ sí òkè ìta, lọ rèé fi nǹkan ṣe àwọn alátakò wọn mọ́ ilé, Emmanuel Amunike, kó Heartland lẹ́yìn lọ gba àmì mẹ́ta lọ́wọ́ ọ Abia Warriors, àmì ayò méjì sí òdo ni.

Sunshine Stars gbé ilé fi ọrùn rọ̀ọ́ nígbà tí Bendel Insurance, ki bẹndẹ ìyà sí ikọ̀ Kennedy Boboye ní inú pẹ̀lú àmì ayò méjì sí ẹyọ̀ kan ní ìlú Àkúrẹ́.

Àwọn ìfigagbága ọ̀sẹ̀ kọkànlá líìgí orílèdè Nàìjíríà yóó ma tẹ̀ síwájú ní ọjọ́ kẹsàn-án àti ìkẹwàá oṣù kọkànlá, ọdún 2024.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *