SpyPen (Gègé Alamí)

News as it breaks.

Ara Rọ Portable, Nígbà Tí Carter Efe Fìyà Jẹẹ́

1777698849671

Enimere Àkànbí
Ọmọ oríléèdè Nàìjíríà, tó gbajúmọ̀ lójú òpó ayélujára, Carter Efe, fìyà jẹ gbajúgbajà olórin tí ẹnu kìísìn lára rẹ̀, Habeeb Òkìkìọlá, tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ mọ̀ sí Portable, nínú eré ìdárayá ẹ̀ṣẹ́ kíkàn tó wáyé láàrin wọn.

Ìjà onípele mẹ́ta ọ̀hún tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn olólùfẹ́ wọn fi ojú ṣọ́nà fún láàrin àwọn ìlúmọ̀ká méjèèjì, ni àkọ́kọ́ irú rẹ̀ tí Efe, yóò ti kópa.

Efe jẹ gàba lórí Portable láti ìbẹ̀rẹ̀ ìjà ọ̀hún títí dé ìparí, kódà àwọn onídàjọ́ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta tó ṣe àkọsílẹ̀ ìfakọyọ ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn, gbé e tán fún Efe.

Bó ti lẹ̀ jẹ́ pé Portable, tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ mọ̀ gẹ́gẹ́ bíi ẹni tó ní okun láti fa ìjàngbọ̀n, gbìyànjú láti ta pútú, agbára rẹ̀ kò ká Efe, tó mú ìdúró rẹ̀ ṣinṣin.

Bí àwọn onídàjọ́ ṣe kéde àkọsílẹ̀ wọn, ni àwọn olólùfẹ́ Efe lójú òpó ayélujára ti bẹ̀rẹ̀ sí ní kọrin ire kìí, fún àwọn ẹ̀bùn tó fi hàn, tí kò sì gbọ̀jẹ̀gẹ́ fún Portable.

Ìjà ọ̀hún ṣe àfihàn ìgbọ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀ eré ìdárayá ẹ̀ṣẹ́ kíkàn láàrin àwọn ìlúmọ̀káá lórílẹ̀èdè Nàìjíríà, níbi tí àwọn tó ń bẹ ní agbo amúlùúdùn ti ń pe ara wọn níjà wọ ìtàgé ẹ̀ṣẹ́ kíkàn láti orí òpó ayélujára, fún ìgbáládùn àwọn olólùfẹ́ wọn.

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *