SpyPen (Gègé Alamí)

News as it breaks.

Olùṣọ́àgùntàn Kan Rawọ Ẹbẹ SÍ Wike Nítorí Ibùdó Ìgbafẹ́ Jabi

jabi lake

Enimere Àkànbí
Olùṣọàgùntàn ìjọ Family Worship Center, tó ń bẹ nílùú Abuja, Sarah Omakwu, ti ra ọwọ́ ẹ̀bẹ̀ sí Alákòóso olú ìlú oríléèdè Nàìjíríà, Abuja, Ọ̀gbẹ́ni Nyesom Wike, láti má ṣe fa ìṣàkóso ibùdó ìgbafẹ́ Jabi Lake fún àwọn aládàáni.

Omakwu, rawọ́ ẹ̀bẹ̀ yìí nínú fónrán tó gbé síta lójú òpó ayélujára Instagram, èyí tó ṣe àfihàn rẹ̀, tó ti kúnlẹ̀ lórí pẹpẹ láti bá Alákòóso ọ̀hún sọ̀rọ̀.

Ó sọ pé “mi ò leè bá alákòóso jà, ṣùgbọ́n mo kúnlẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi ìyá lórí ilẹ̀ yìí, pé kí wọ́n má ṣe gbé ibùdó ìgbafẹ́ ọ̀hún fún ẹnikẹ́ni.

“Ibẹ̀ ni àwọn èèyàn má ń lọ fún ìgbafẹ́, ibi tí àwọn kan ti ma ń tajà, ibi tí àwọn míì ti ń pàdé, tí àwọn míì tí ń ṣe ìgbéyàwó.

Ó jẹ́ ibi tí àwọn èèyàn ti má lọ wo ìran, ibi tí àwọn ọ̀dọ́ ma ń péjọ sí ni, gẹ́gẹ́ bíi ìyá, mo bẹ̀yín, Alákòóso, lórúkọ Ọlọ́run, ẹ má ta ilẹ̀ náà fún ẹnikẹ́ni”

Òjíṣẹ́ Ọlọ́run ọ̀hún tún kọminú lórí àwọn ìdàgbàsókè gbogbo tó wáyé láìpẹ́ yìí nílùú Abuja, ó sì fi ti bí àwọn aráàlú kò ṣe ní àǹfààní láti wọ inú Aso Rock bíi ti ìgbà kan mọ́ àpẹẹrẹ.

Omakwu, sì gba Ọ̀gbẹ́ni Wike, níyànjú láti ṣe Jabi Lake, lọ́jọ̀ fún àwọn olùgbé ìlú Abuja láti má a ṣe afẹ́ lọ síbẹ̀.

Ó sì tún fi àkókò ọ̀hún gbóríyìn fún Alákòóso ọ̀hún fún àwọn àyípadà rere àti ìdàgbàsókè tó ti mú bá ìlú Abuja.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *