SpyPen (Gègé Alamí)

News as it breaks.

Ohun Tó Ní Láti Mọ̀ Nípa Tégbè Tó Fẹ́ Rọ́pò Adélabú Nínú Ìṣàkóso Iná Ọba

tegbe and tinubu 1 1 e1777564157617 1280x720

Enimere Àkànbí
Ààrẹ oríléèdè Nàìjíríà, Bọlá Tinúbú, ti fi orúkọ Ọ̀gbẹ́ni Joseph Tégbè, ráńṣẹ́ sí ilé aṣòfin àgbà, fún ìbuwọ́lù wọn sí ìyànsípò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi alákòóso iná ọba.

Nínú àtẹ̀jáde láti ọwọ́ olùrànlọ́wọ́ Ààrẹ Tinúbú lórí ọ̀rọ̀ ìròyìn, Báyọ̀ Ọnànúgà, ni wọ́n ti jẹ́ kó di mímọ̀ bẹ́ẹ̀, pẹ̀lú àlàyé pé ìgbésẹ̀ yìí ni ìrètí wà pé yóò túbọ̀ ṣe ìrólágbára fún akitiyan láti mú ìgbà ọ̀tun bá ẹ̀ka ìpèsè iná ọba, ṣe ìrànwọ́ fún ẹgbọrọ alátagbà láti dúróre àti láti fa àwọn olùdókòòwò ọlọ́jọ́ pípẹ́ lójú mọ́ra, ní ìbámu pẹ̀lú àfojúsùn Ìrètí Ọ̀tun.

Ìfi orúkọ Ọ̀gbẹ́ni Tégbè sọwọ́ sí ilé aṣòfin àgbà wáyé nítorí pé Ọ̀gbẹ́ni Adébáyọ̀ Adélabú, kọ̀wé fi ipò ọ̀hún sílẹ̀, láti fi èróńgbà hàn fún ipò Gómìnà ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́.

Bẹ́ẹ̀, Ọ̀gbẹ́ni Tégbè, tí òun náà jẹ́ ọmọ bíbí ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ àti ẹni tó ti gbà á lérò rí láti di Gómìnà, jẹ́ akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ nípa owónàá àti àtúntò ọrọ̀ ajé, èyí tó ti fi ń ṣe iṣẹ́ ṣe láti bíi ọgbọ̀n ọdún sẹ́yìn ní àwọn ẹ̀ka ìjọba àti ti aládàáni.

Ó ti fi ìgbà kan rí Alábáṣepọ̀ àgbà àti olórí iléeṣẹ́ tó ń gba KPMG Africa nímọ̀ràn, níbi tí ó ti léwájú onírúurú àgbékalẹ̀ nínú àtúntò ìlànà owónàá, ìṣèjọ̀ba àti ìyípadà ọ̀tun àwọn iléeṣẹ́.

Ṣáájú kí Ààrẹ Tinúbú tó fi orúkọ rẹ̀ ṣọwọ́ sí ilé aṣòfin, ni Ọ̀gbẹ́ni Tégbè jẹ́ Adarí àgbà ìgbìmọ̀ tó ń ṣe alárinà ìbáṣepọ̀ láàrin oríléèdè Nàìjíríà àti China.
Sẹ́gun Adélakùn

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *