SpyPen (Gègé Alamí)

News as it breaks.

Pẹ́pẹ́yẹ Pọn Ọmọ Nígbà Tí Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ Gbàlejó Àwọn Egúngún Káàkiri Àgbáyé

images (11)

Enimere Àkànbí
Gómìnà Ṣèyí Mákindé ti túbọ̀ fìdí akitiyan ìṣàkóso rẹ̀ múlẹ̀ láti ṣàmúlò àṣà àti ìrìn-àjò afẹ́ gẹ́gẹ́ bíi irinṣẹ́ gbòógì fún ìdàgbàsókè ọrọ̀ ajé.

Bákan náà ni Gómìnà Mákindé sọ pé àwọn nǹkan ìmúyagàn àṣà ilẹ̀ Yorùbá kò gbọdọ̀ parun.

Gómìnà Mákindé sọ̀rọ̀ yìí níbi àṣekágbá Àjọ̀dún egúngún àgbáyé, tí iléeṣẹ́ tó ń rí sọ̀rọ̀ àṣà àti ìrìnàjò afẹ́ nípìnlẹ́ Ọ̀yọ́ ṣe nínú pápáṣeré ìdárayá Ọbáfẹ́mi Awólọ́wọ̀, tó ń bẹ ní Òkè-Àdó, nílùú Ìbàdàn.

Gómìnà ọ̀hún tí akọ̀wé ìjọba rẹ̀, Ọ̀jọ̀gbọ́n Musibau Babatunde, ṣojú fún tọ́ka sí bí àwọn aṣojú oríléèdè gbogbo ní àgbáyé tó yẹ́ àjọ̀dún egúngún náà sìí ṣe ń fi ẹ̀rọ ayàwòrán ṣe àkásílẹ̀ gbogbo ètò tí wọ́n ṣe, fi hàn pé Àjọ̀dún ọ̀hún ti ń gbọ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ́ káàkiri àgbáyé.

Mákindé tó gbóríyìn fún Alákòóso àṣà àti ìrìnàjò afẹ́ nípìnlẹ́ Ọ̀yọ́, Ọ̀mọ̀wé Wasiu Olatunbosun, fún bí ó ṣe ń yí ìwòye ọ̀pọ̀lọpọ̀ nípa àṣà padà àti bó ṣe ń sa ipá láti ríi dájú pé àṣà, ìṣe àti àwọn nǹkan tí ilẹ̀ Yorùbá fi ń yangàn kò parun.

Nínú ọ̀rọ̀ olórí igbàkejì aṣojú ilẹ̀ gẹ̀ẹ́sì ní ìlú Èkó, Ọ̀gbẹ́ni Simon Field, ó ṣàlàyé kíkún, ipa pàtàkì tí àwọn àjọ̀dún àṣà ń kó nínú dídì àlàfo tó ń bẹ láàrin ilẹ̀ gẹ̀ẹ́sì àti oríléèdè Nàìjíríà, ó sì fi ìdùnnú hàn sí àwọn ètò tí wọ́n piyamọ àti itú tí àwọn olùkópa pa lórí ìtàgé.

Nínú ọ̀rọ̀ orí adé ọjọ́ ayẹyẹ àti alága Àjọ̀dún egúngún ọdún nìí, Olúbàdàn ilẹ̀ Ìbàdàn, Ọba Rashidi Ládọjà, tí Aṣípa Olúbàdàn, Ọba Hamidu Ajíbádé, ṣojú fún, kan sárá sí ìjọba ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ fún akitiyan láti ṣe àṣà lọ́jọ̀ fún aráyé, àti ìlàkàkà láti sọ ìlú Ìbàdàn di ibùdó ọrọ̀ ajé àṣà àti àgbéjáde àwọn ọgbọ́n àtinúdá.

Ṣáájú nínú ọ̀rọ̀ ìkíni káàbọ̀ Alákòóso àṣà àti ìrìnàjò afẹ́ nípìnlẹ́ Ọ̀yọ́, Ọ̀mọ̀wé Wasiu Ọlátúnbọ̀sún, dúpẹ́ púpọ̀ lọ́wọ́ gbogbo àwọn tó ṣe ìrànwọ́ fún Àjọ̀dún egúngún náà, tó sì jẹ́ kó di mímọ̀ pé àfojúsùn ìjọba fún-un ni láti di àtẹ́wọ́gbà Àjọ tó ń ṣe ìṣàkóso ètò ẹ̀kọ́, ìmọ̀-ẹ̀rọ àti àṣà lágbàyé(UNESCO).

Níbi àjọ̀dún egúngún ọdún ẹgbàá-lé-mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n, tí àwọn eégún káàkiri oríléèdè yìí àti àwọn oríléèdè míì láàgbáyé ti fi ijó, ìlú àti àwọn ìlànà míì gbé àṣà ga, ni wọ́n ti fún Ẹgbẹ́ àwọn òṣìṣẹ́fẹ̀yìntì lórílẹ̀èdè Nàìjíríà ẹ̀ka ti ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, ní àmì ẹ̀yẹ gẹ́gẹ́ bíi Ẹgbẹ́ tó ní àkọsílẹ̀ olùkópa tó pọ̀ jù lọ.
Sẹ́gun Adélakùn

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *