Enimere Àkànbí
Lẹ́yìn tí ilé ẹjọ́ ni kí wọ́n lo fi eegun òtòlò to ìjà aṣáájú tó bẹ̀ sílẹ̀ láàrin àwọn aṣáájú Ẹgbẹ́ òṣèlú African Democratic Congress, ADC, wọ́n ti ṣe àgbéjáde àlàkalẹ̀ bí ètò ìdìbò abẹ́lẹ́ láti yan àwọn olùdíje Ẹgbẹ́ fún ètò ìdìbò gbogbogbò ọdún ẹgbàá-lé-mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n, yóò ṣe wáyé nínú Ẹgbẹ́ òṣèlú ọ̀hún.
Gẹ́gẹ́ bó ṣe jẹ yọ nínú àtẹ̀jáde láti ọwọ́ akọ̀wé ìpolongo Ẹgbẹ́ òṣèlú ADC, Ọ̀gbẹ́ni Bọ́lájí Abdullahi, èyí tó ṣe àfihàn rẹ̀ pé láàrin ọjọ́ karùn-ún sí ọjọ́ kẹwàá oṣù yìí ni àǹfààní yóò ṣí sílẹ̀ fún àwọn ọmọ ẹgbẹ́ láti ra ìwé ìfèròǹgbà hàn, tí wọ́n sì gbọ́dọ̀ ṣe ìgbésẹ̀ tó yẹ àti ìmúpadà wá a rẹ̀ láàrin ọjọ́ kọkànlá sí ọjọ́ kẹtàlá, oṣù yìí.
Àyẹ̀wò fún àwọn tó ń fi èróńgbà hàn yóò wáyé ní ọjọ́ kẹrìnlá àti ọjọ́ kẹẹ̀dógún, tí èsì àyẹ̀wò yóò sì jáde ní ọjọ́ kẹ́tàlélógún oṣù yìí.
Ẹgbẹ́ òṣèlú ADC, jẹ́ kó di mímọ̀ pé àwọn tó ń ṣe ìṣàkóso ètò yóò fi ọjọ́ kejìdínlógún àti ọjọ́ kọ̀kàndínlọ́gbọ̀n, tẹ́tí sí awuyewuye tó bá jẹ yọ, tí ojúlówó orúkọ àwọn tí yóò kópa nínú ètò ìdìbò abẹ́lẹ́ yóò sì jáde ní ogúnjọ́.
Wọ́n fi kún un pé ètò ìdìbò abẹ́lẹ́ náà yóò bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú u àwọn tó fẹ́ ṣe aṣòfin ìpínlẹ̀, ilé aṣòfin àgbà Kínní-kejì, ní àkókò kan náà, lọ́jọ́ kọkànlélógún.
Ọjọ́ kejìlélógún ni wọ́n yóò ṣe ètò ìdìbò abẹ́lẹ́ fún àwọn tó fẹ́ díje du ipò Gómìnà, tí ti ipò Ààrẹ yóò sì wáyé lọ́jọ́ kẹẹ̀dọ́gnọ̀n, oṣù karùn-ún, ọdún ẹgbàá-lé-mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n.
Ìpàdé àwọn ìgbìmọ̀ aláṣẹ Ẹgbẹ́ òṣèlú ADC lápapọ̀ lórílẹ̀èdè yìí, ni yóò sì tẹ́lẹ̀ ní ọjọ́ kẹrìndínlọ́gbọ̀n àti àkànṣe ètò ìdìbò láti fi yan àwọn alákòóso tuntun Ẹgbẹ́ ọ̀hún lápapọ̀ yóò wáyé lọ́jọ́ kẹtàdínlọ́gbọ̀n láti fi kásẹ̀ ètò àti àtúnṣe gbogbo náà nílẹ̀.
Bẹ́ẹ̀ láì pẹ́ yìí , ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn tó dúró gẹ́gẹ́ bíi igi lẹ́yìn ọgbà Ẹgbẹ́ òṣèlú ọ̀hún, bíi ẹni tó ti díje dupò Ààrẹ rí, Peter Obi, Gómìnà nígbà kan rí nípìnlẹ́ Kano, Rabiu Kwankwaso, àti àwọn aṣòfin lórílẹ̀èdè Nàìjíríà fi Ẹgbẹ́ òṣèlú ọ̀hún sílẹ̀ lọ darapọ̀ mọ́ àwọn Ẹgbẹ́ òṣèlú míì.
Ẹ̀wẹ̀, Ààrẹ ilé aṣòfin àgbà, Godswill Akpabio, fi Ẹgbẹ́ òṣèlú ADC ṣe ẹlẹ́yà lákòókò tó ń tukọ̀ ìjókòó ilé aṣòfin ọ̀hún, pẹ̀lú ọ̀rọ̀ àpará pé “Ẹgbẹ́ òṣèlú ADC ti kú”
Akpabio sọ̀rọ̀ yìí gẹ́gẹ́ bíi ìwòye rẹ̀ sí bí àwọn èèyàn ṣe ń fi Ẹgbẹ́ náà sílẹ̀, pàápàá jù lọ àwọn aṣòfin, tí ilé sìí ń fi gbogbo ìgbà kéde nínú ìjókòó wọn.
Ṣẹ́gun Adélakùn











Leave a Reply