SpyPen (Gègé Alamí)

News as it breaks.

Sisí Alágbo Fìdí Fọ́nrán Ìbálòpọ̀ Múlẹ̀, Ó Tọrọ Àforíjìn

1777456256952

Enimere Àkànbí

Gbajúmọ̀ oníṣòwò àgbo nílùú Ìbàdàn, tí àwọn èèyàn mọ̀ bí ẹní mọ owó lójú òpó ayélujára, sí, Ẹniọlá Sisí Alágbo, ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé òótọ́ ni fọ́nrán tó di tọ́rọ́fọ́nkálé lójú òpó ayélujára, èyí tó ṣe àfihàn rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọkùnrin méjì, tí wọ́n ń ní ìbálòpọ̀.

Èyí ló fi òpin sí àríyànjiyàn gbogbo tí àwọn èèyàn ti ń ṣe láti ìgbà tí fọ́nrán ọ̀hún ti jẹyọ, kódà àwọn kan wòye pé àgbélẹ̀rọ Oyè Àtọwọ́dá (AI) ni.

1777453851738967 0

Nínú ohun tí Ẹniọlá Sisí Alágbo, kọ sójú òpó ayélujára Facebook, ló ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé, òótọ́ ni, ṣùgbọ́n kò ṣàlàyé ní kún kún nípa bí ó ṣe jẹ́.

Ṣùgbọ́n ó fi àkókò ọ̀hún tọrọ àforíjìn lọ́dọ̀ Elédùmarè àti àwọn olólùfẹ́ rẹ̀.

Ó ní kí wọ́n dákun fi ojú fòó, kí wọ́n má ṣe fi àṣìṣe náà bi òun, nítorí àwọn àkóbá míì tí ó leè ti ẹ̀yìn rẹ̀ yọ fún òun.

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *