Enimere Àkànbí
Ìdíje bọ́ọ̀lù aláfẹ́sẹ̀gbá ni wọn yóó fi ṣíde ayẹyẹ ogún ọdún tí àgbà-ọ̀jẹ̀ akọ̀ròyìn eréèdárayá, Dayọ̀ Òjó, tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ mọ̀ sí “Okocha” ti ń ṣe iṣẹ́ gẹ́gẹ́ bíi akọ̀ròyìn eréèdárayá.
Gẹ́gẹ́ bó ṣe jẹ yọ nínú àtẹ̀jáde láti ọwọ́ alárinà ìgbìmọ̀ tó ń ṣe kòkárí àjọ̀dún ọ̀hún Adébáyọ̀ Adédigba, pẹ̀lú ìbuwọ́lù Alága ìgbìmọ̀ ọ̀hún, Adédàmọ́lá Adégòkè, àkòrí ìdíje náà ni “Ìdíje bọ́ọ̀lù aláfẹ́sẹ̀gbá fún ìṣàmì ayẹyẹ ogún ọdún àgbà-ọ̀jẹ̀ akọ̀ròyìn eréèdárayá, Dayọ̀ Òjó Okocha.
Ìdíje náà gẹ́gẹ́ bí ìgbìmọ̀ tó ń ṣe àmójútó rẹ̀ èyí tí Ọ̀gbẹ́ni Adéníyì Afẹ́, jẹ́ Alága rẹ̀, ṣe ṣàlàyé nínú àtẹ̀jáde ọ̀hún, ni yóó bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìforúkọsílẹ̀ àwọn ikọ̀ tí yóó kópa, láàrin ọjọ́ Kejìlá sí ọjọ́ Kọkánlélọ́gbọ̀n oṣù Kejìlá, ọdún 2025, tí ìyíkoto bí wọn yóó ṣe kojú ara wọn yóó sì wáyé ní ọjọ́ kẹwàá, oṣù Kínní, ọdún 2026.
Ọjọ́ kẹtàdínlógún, oṣù Kínní, ọdún 2026 ni ìdíje ọ̀hún yóó bẹ̀rẹ̀ ní pẹrẹhu, ní pápáṣeré ìdárayá Durbar, tó ń bẹ ní ìlú Ọ̀yọ́.
Àtẹ̀jáde yìí fi kún pé ìdíje eréèdárayá náà tí yóó wáyé fún oṣù méjì gbáko, ni wọ́n dìídì gbé kalẹ̀ fún àwọn àgbà-ọ̀jẹ̀ Ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù ní ìgboro ìlú Ọ̀yọ́ àti jákèjádò ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ lápapọ̀.
Yàtọ̀ sí ìdíje bọ́ọ̀lù aláfẹ́sẹ̀gbá, àwọn ètò míràn tí wọ́n piyamọ fún ayẹyẹ ọ̀hún ni fífún àwọn tó kópa ribiribi nínú ìrìn àjò ogún ọdún Dayọ̀ Òjó Okocha, láti mú ìdàgbàsókè bá eréèdárayá ní ìlú Ọ̀yọ́, ní àmì-ẹ̀yẹ àti ìwé ẹ̀rí ìmọrírì.
Ìdíje ta ló mọ àwọn ìbéèrè eréèdárayá àti ìtukọ̀ ètò yàjóyàjó eréèdárayá láàrin àwọn gbajúmọ̀ atọ́kùn ètò eréèdárayá ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́.
Àtẹ̀jáde ọ̀hún tún ṣe àpèjúwe ayẹyẹ náà gẹ́gẹ́ bíi ìmọrírì ipa tí “Okocha” ti kó nínú iṣẹ́ ìròyìn eréèdárayá, ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú àwùjọ àti ìgbèlárugẹ eréèdárayá lẹ́sẹ̀kùkú ní tìbútùro ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́.
Níbi àṣekágbá ayẹyẹ yìí tí yóó wáyé ní ọjọ́ kọkànlá, oṣù kẹrin, ọdún 2026, ni wọ́n ti ń retí àwọn àgbà-ọ̀jẹ̀ agbábọ́ọ̀lù, àwọn alátìlẹyìn eréèdárayá àti àwọn tó ní ìfẹ́ eréèdárayá, láti wá yẹ́ akọ́ṣẹ́mọsẹ́ agbóhùnsáfẹ́fẹ́ náà tí ó ti kó ipa tó yááyì lẹ́ka eréèdárayá láti bí i ogún ọdún sẹ́yìn, sìí.
Àwọn ìfitónilétí tó bá tún yẹ, ni àwọn ìgbìmọ̀ náà jẹ́ ẹ̀jẹ́ láti kéde wọn, lọ́gba bí ìgbáradì ṣe ń tẹ́síwájú.









Leave a Reply