Enimere Àkànbí
Ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Tottenham fi ìlú London sílẹ̀ lọ rèé kan Manchester City lábùkù ní ọ̀sẹ̀ kejì tí líìgì ilẹ̀ gẹ̀ẹ́sì fún sáà 2025/2026 bẹ̀rẹ̀.
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ló lérò pé ìdààmú tó bá Pep Guardiola nínú ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Manchester City ní sáà tó kọjá, ti dópin, nígbà tí wọ́n fa Wolverhampton Wanderers, ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ ní ìfigagbága ọ̀sẹ̀ àkọ́kọ́, pẹ̀lú àmì ayò mẹ́rin sí òfo.
Ṣúgbọ̀n nígbà tí Tottenham Hotspur, dé sí pápá ìṣerédárayá Etihad, ni ọ̀rọ̀ fi ojú hàn pé, nǹkan tó ń ṣe ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù ọ̀hún tó jẹ́ ẹ̀rùjẹ̀jẹ̀ tẹ́lẹ̀, kò tíì fi wọ́n sílẹ̀.
Guardiola ná ọ̀pọ̀lọpọ̀ owó láti fi ra àwọn agbábọ́ọ̀lù tuntun, ó sì jọ̀wọ́ àwọn agbábọ́ọ̀lù kan, láti lọ darapọ̀ mọ́ àwọn ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù mìíràn, láti le fi ra ògo ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù ọ̀hún padà.
Síbẹ̀ síbẹ̀ pàbó ló jásí níwájú ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Tottenham Hotspur, tí kó bẹ̀ṣùbẹ̀gbà láti fi Guardiola, wọ́lẹ̀ lójú àwọn olólùfẹ́ ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Manchester City.
Brennan Johnson ló kọ́kọ́ mi àwọ̀n ní ìṣẹ́jú márùndìnlógójì, kí Joao Palhinha, tó fi ọba lé e ní ìṣẹ́jú méjì lẹ́yìn Ìfẹ̀lójú abala àkọ́kọ́.

Gbogbo ìgbìyànjú Manchester City, láti tapúpú, pẹ̀lú ìtọ́ni Guardiola, ló jásí pàbó títí tí Adarí-ayò, Peter Bankes, fi tú ikọ̀ méjèèjì ká.
Ọjọ́kọkànlélọ́gbọ̀n oṣù yìí ni Manchester City, yóó lọ sí òkè-ìta láti kọjú u Brighton, ṣáájú ní Ọgbọ̀njọ́ ni Tottenham yóó gba Bournemouth lálejò.












Leave a Reply