SpyPen (Gègé Alamí)

News as it breaks.

‎Tottenham Tan Hotspot Fún PSG, Alátakò Bá Kó Ìfà UEFA Super Cup Mọ́ Wọn Lọ́wọ́

Paris Saint Germain Celebrates 2508 G 1200

Enimere Àkànbí
‎Ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Paris Saint German (PSG) ti oríléèdè France fi àgbà han alátakò rẹ̀ láti ilẹ̀ gẹ̀ẹ́sì, Tottenham Hotspur, ní àṣekágbá ìdíje UEFA Super Cup.

‎Ìdíje UEFA Super Cup ni àjọ tó ń ṣe kòkárí bọ́ọ̀lú aláfẹsẹ̀gbá ní àárín àwọn oríléèdè aláwọ̀ funfun (UEFA) gbé kalẹ̀ láti mọ akọni láàrin ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù tó gba ife ẹ̀yẹ ìdíje àwọn akọni ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù (Champions league) àti ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù tó gba ife ẹ̀yẹ tí wọ́n gbé kalẹ̀ fáwọn ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù tí kò kójú òṣùwọ̀n láti wà ní àárín àwọn akọni (Europa league).

Images 300x168

‎Ìdíje náà tó wáyé nílùú Udine, lórílẹ̀èdè Italy, ló jẹ́ àkọ́kọ́ irú rẹ̀ láàrin àwọn ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù méjèèjì, nínú ìdíje gbogbo tí àjọ UEFA ń gbé kalẹ̀.

‎Ẹ má gbàgbé pé ife ẹ̀yẹ UEFA Champions league tí ṣáá 2024/2025 tí PSG gbá à lọ́wọ́ Intermilan, tó fi ìyà jẹ ní àṣekágbá pẹ̀lú àmì ayò márùn-ún sí òfo, ni àkọ́kọ́ àṣeyọrí ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù náà nínú ìdíje àjọ UEFA.

‎Nígbà tí Tottenham peregedé fún ìfigagbága yìí lẹ́yìn tó gba ife ẹ̀yẹ Europa League, mọ́ Manchester United lọ́wọ́, pẹ̀lú àmì ayò kan sí òfo.

‎Ẹ̀ẹ̀mejì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni Tottenham tí Thomas Frank, kó sòdí, jẹ PSG, tí akọ́nimọ̀ọ́gbá, Luis Enrique, àti àwọn agbábọ́ọ̀lù rẹ̀, kò sì rí nǹkan ṣe síi, títí tó fi di ìṣẹ́jú márùn-dínláàdọ́rùn-ún.

‎Àwọn agbábọ́ọ̀lù tó di ọwọ́ ẹ̀yìn mú, Micky Van de Ven láti oríléèdè Netherlands àti ọmọ oríléèdè Argentina, Cristian Romero, ló gbá bọ́ọ̀lù sínú àwọ̀n fún Tottenham, ní ìṣẹ́jú kọkàndínlógójì àti ìṣẹ́jú kejìdínlọ́gọ́ta, ìfigagbága ọ̀hún, kó tó di pé nǹkan pakasọ nígbà tó ku díẹ̀ kí ìdíje parí.

‎Ìgbìyànjú PSG já sí èrè láti ọwọ́ ọ Kang-in Lee, tó jẹ́ agbábọ́ọ̀lù ní ààrin gbùngbùn láti oríléèdè South Korea, kí atamátàsé ọmọ oríléèdè Portugal Goncalo Ramos, tó fi ìkejì lé e ní ìṣẹ́jú mẹ́rin-léláàdọ́rùn-ún.

‎Ọ̀mì ayò méjì méjì yìí ni wọ́n gbá parí, tí ó fi di bọ́ọ̀lù golí wò-mí-kíngbáa-sáwọ̀n (Penalty Shootout).

‎Níbẹ̀ ni PSG tó gbá mẹ́rin nínú márùn-ún wọ inú àwọ̀n ti fi ẹ̀yìn Tottenham, tí àwọn pàdánù méjì, janlẹ̀ pẹ̀lú ú àmì ayò mẹ́rin sí mẹ́ta.


Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *