Enimere Àkànbí
Ìgbìmọ̀ àwọn báálẹ̀ ní ilẹ̀ Ìbàdàn, ti fi àmì ẹ̀yẹ aṣíwájú tó tayọ jùlọ, jíǹkí alága àjọ elétò ìdìbò ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ (OYSIEC), Mọ́gàjì Isiaka Ọlágúnjú, fún ipa ribiribi tó ń kó nínú ìdàgbàsókè ilẹ̀ Ìbàdàn àti ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, ní àpapọ̀.
Nígbà tó ń fi àmì ẹ̀yẹ ọ̀hún dá Ààrẹ Ọlágúnjú, tó jẹ́ Mọ́gàjì agbo ilé Ọ̀pẹrẹ, ní Ìsàlẹ̀ Òsì, Ìbàdàn, lọ́lá níbi ètò ráhúnpẹ́ kan tó wáyé ní olú ilé’ṣẹ́ àjọ OYSIEC, tó fìdí kalẹ̀ sí agbègbè Agodi, ní ìlú Ìbàdàn, Ààrẹ ẹgbẹ́ ọ̀hún, Baálẹ̀ Ọládàpọ̀ Wasiu Ààrẹ, sọ pé Mọ́gàjì Ọlágúnjú ti kó ipa tó jọjú nínú ìgbèlárugẹ ìjọba àwarawa àti ìṣèjọba rere ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́.

Ní ìtẹ̀sìwájú àlàyé rẹ̀, Baálẹ̀ Ọládàpọ̀ Ààrẹ, sọ pé ní abẹ́ ìṣàkóso Mọ́gàjì Ọlágúnjú, àjọ OYSIEC, ti ṣe ètò ìdìbò tó kẹ́sẹjárí ní ẹ̀ẹ̀mejì ọ̀tọ̀tọ̀ ní ọdún 2021 àti 2024, láti fi yan àwọn alága ìjọba ìbílẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́.
Ó fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé àwọn tún yan alága àjọ OYSIEC gẹ́gẹ́ bíi aṣojú ẹgbẹ́ náà, nítorí bí kò ṣe rẹ̀wẹ̀sì láti má a kópa sí ìdàgbàsókè àwùjọ.
Nígbà tó ń fèsì, alága àjọ elétò ìdìbò ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ (OYSIEC), Mọ́gàjì Isiaka Ọlágúnjú, dúpẹ́ púpọ̀ lọ́wọ́ ìgbìmọ̀ àwọn báálẹ̀ ní ilẹ̀ Ìbàdàn, fún bí wọ́n ṣe kà á yẹ fún àmì ẹ̀yẹ ọ̀hún.
Àgbàọ̀jẹ̀ agbẹjọ́rọ̀ náà ṣàlàyé pé, ìtẹ́fẹ̀ẹ́ ara òun lọ́rùn lásán ni ipa tí òun ń kó nínú ìdàgbàsókè ilẹ̀ Ìbàdàn, ó sì tún ẹ̀jẹ́ jẹ́ pé òun kò ní fà sẹ́yìn nínú akitiyan àti ìgbìyànjú láti má a mú ìlọsíwájú àti ìdàgbàsókè bá ìlú Ìbàdàn àti ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ní àpapọ̀.
Bákan náà ló ṣe ìlérí pé kàkà kí òun ṣe ohunkóhun tí yóó ta epo sí aṣọ àlà ìlú Ìbàdàn, òun yóó yàn láti má a jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tí yóó ma ṣe ojú ilẹ̀ olókìkí náà dáadáa.

Lára àwọn tó wà ní ibi ètò náà ni alákòóso àjọ OYSIEC, Olóyè Kúnmi Agboọlá, alákòóso ètò ẹ̀náwó àjọ OYSIEC, Arábìnrin Muinat Ọlátúnjí àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀lọ.











Leave a Reply