Enimere Àkànbí
Ìmáàmù àgbà ìjọ ẹ̀sìn Islam ti Ansar-ud-een, ẹ̀ka ti ìlú Ọ̀yọ́, Fadeelatu Sheikh Al-Imam Míkálì Bọ́lájí Adéyẹmọ, ti ṣe àpèjúwe síṣe ìgbélárugẹ ìfẹ́ àti ìṣọ̀kan ní àwùjọ, gẹ́gẹ́ bíi irinṣẹ́ ìdàgbàsókè àti ìlọsíwájú.
Onímọ̀ kíkún nípa ẹ̀sìn Islam ọ̀uń sọ ọ̀rọ̀ yìí nínú ìdánilẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀, níbi ayẹyẹ wíwé láwáàní àti ìfi àmì ẹ̀yẹ dánilọ́lá fún àwọn Mùsùlùmí tó ń kírun ní mọ́ṣáláṣí ńlá agbègbè Mọ́làbí, tó wáyé ní ilé ẹ̀kọ́ alakọbẹ́rẹ́ ti Ansar-Ud-Deen, Akágbọ̀n, ìlú Ọ̀yọ́.
Ní ìtẹ̀sìwájú ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ọ̀hún, Fadeelatu Sheikh Bọ́lájí, sọ pé ẹ̀sìn Islam fi ọwọ́ sí fífi oyè ẹ̀sìn tàbí àmì ẹ̀yẹ jíǹkí èèyàn, níwọ̀n ìba ìgbà tó bá jẹ́ pé àwọn onítọ̀hún gba Ọlọ́run Ọba Allah gbọ́ ní òtítọ́, tí wọ́n sì di òpó ẹ̀sìn Islam mùú.
Ó ṣe àlàyé síwájú pé ó ṣe kókó kí àwọn tí wọ́n ń fi ipò jíǹkí ní onírúurú mọ́ṣáláṣí, mú ìgbáyégbádùn àwọn Ìmáàmù wọn ní ọ̀kúnkúndùn gẹ́gẹ́ bíi àmúṣẹ àwọn àkànṣe iṣẹ́ ìdàgbàsókè.
Fadeelatu Sheikh Bọ́lájí, wá rọ àwọn Mùsùlùmí tó ń kírun ní mọ́ṣáláṣí ńlá agbègbè Mọ́làbí, láti wà ní ìṣọ̀kan, kí wọ́n sì tún má a fi ààyè gba ìpín dọ́gba nínú ìfọnrere ẹ̀sìn Islam.
Aṣíwájú ẹ̀sìn náà, tún rọ àwọn tó gba òye tuntun àti àmì ẹ̀yẹ, láti máa ṣe ìkúnlọ́wọ́ tó ní ìtumọ̀ fún mọ́ṣáláṣí náà nínú àwọn àkànṣe iṣẹ́ tó bá ń gùnlé, pẹ̀lú àfikún pé kí wọ́n máa rántí pé èrè ń bẹ fún gbogbo àwọn tó bá jẹ́ ìpè Allah, àti àwọn tó bá ń lo nínú nǹkan ìní wọn fún-un.

Nígbà tí olùgbàlejò àgbà ń sọ̀rọ̀, Ọ̀mọ̀wé Muftau Ayọ̀ọlá, sọ pé àwọn aláṣẹ mọ́ṣáláṣí ọ̀hún pinnu láti bu ọlá fún àwọn èèyàn náà nítorí ipa àti akitiyan wọn nínú ìdàgbàsókè mọ́ṣáláṣí Mọ́làbí àti àwọn Mùsùlùmí ní àpapọ̀.
Ọ̀mọ̀wé Ayọ̀ọlá, tó fi ẹ̀mí ìmọore hàn sí onírúurú èèyàn àti ẹgbẹ́ tó ṣe àtìlẹyìn fún àṣeyọrí ayẹyẹ ọ̀hún, tún sọ pé ètò náà ti túbọ̀ mú àwọn ará agbègbè ọ̀hún sún mọ́ ara wọn ju ti àtẹ̀yìnwá lọ, bákan náà ló gba ẹní kọ̀ọ̀kan níyànjú láti má ṣe iṣẹ́ tọ ìṣọ̀kan ẹbí wọn gẹ́gẹ́ bí ó ṣe wà nínú al-Quran.
Nínú ọ̀rọ̀ ọ̀tọ̀tọ̀ ti Ààrẹ àwọn Mùsùlùmí ní ìlú Ọ̀yọ́, tó tún jẹ́ baba ètò ọjọ́ náà, Alhaji Tajudeen Kámáaríṣe àti ìyá ètò ọjọ́ náà, Ayaba Sulat Motúnráyọ̀ Adéyẹmi, wọ́n ké sí àwọn tí wọ́n fi oyè dá ní ọlá, láti ríi gẹ́gẹ́ bíi ìpè láti túbọ̀ wá ṣe iṣẹ́ sin Ọba Allah àti àwọn Mùsùlùmí òdodo.

Ṣáájú nínú ọ̀rọ̀ Ìmáàmù àgbà mọ́ṣáláṣí ńlá fún àwọn ará agbègbè Mọ́làbí, Sheikh Al-Imam Soliudeen Ọládókun, sọ pé nítorí pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn tí wọ́n fún ní oyè àgbé ẹ̀sìn ga tẹ́lẹ̀ ní mọ́ṣáláṣí náà, ti re ibi àgbà ń rè, ló bí ayẹyẹ ọ̀hún.
Nínú ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò pẹ̀lú àwọn tí wọ́n fi oyè dálọ́lá, onímọ̀-ẹ̀rọ Alhaji Salawu Adétòkúnbọ̀, tí wọ́n fi jẹ Amir-ul-Mumini, Alhaja, Rashidat Adégòkè tó gba oyè Ìràwọ̀ Àdínnì àti Alhaja Sulat Ọpẹ́lóyẹrú, tí wọ́n fi jẹ Ìyá a Sunnah, fi ìdùnnú hàn sí bí àwọn aláṣẹ mọ́ṣáláṣí ọ̀hún ṣe kà wọ́n yẹ fún oyè náà.
Àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta sì ṣe àpèjúwe ayẹyẹ ọ̀hún gẹ́gẹ́ bíi ara ẹwà ẹ̀sìn Islam tó ń ṣe ìpolongo ìṣọ̀kan ní ààrin àwọn tí wọ́n fún ní oyè àti àwọn Mùsùlùmí tó ń kírun ní mọ́ṣáláṣí ńlá agbègbè Mọ́làbí ní àpapọ̀, pẹ̀lú àfikún pé ìgbésẹ̀ ọ̀hún yóò tún mú àwọn jára mọ́ gbígbé ẹ̀sìn Islam ní arugẹ.

Ní ara àwọn èèyàn pàtàkì tó yẹ́ ayẹyẹ náà sí ni àwọn orí adé, àwọn olórí ẹ̀sìn, tó fi mọ́ aṣòfin tó ń ṣe ojú ẹkùn ìdìbò ààringbùngbùn Ọ̀yọ́, ní ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin orílèdè Nàìjíríà, Senator, ọ̀mọ̀wé Yunus Akíntúndé, ọmọ ilé aṣojúṣòfin, Ọmọba Akeem Adéyẹmí, alága àjọ tó ń yá àwọn àgbẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ní owó, Sheikh. Taofeek Akéwúgbagold, ẹbí àti àwọn ará agbègbè náà.












Leave a Reply